Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017

 JỌ́JÍÀ

Ìfẹ́ Máa Ń Borí Ìdènà

Ìfẹ́ Máa Ń Borí Ìdènà

ṢÁÁJÚ kí wọ́n tó bí Sanel ni àwọn dókítà ti sọ fáwọn òbí ẹ̀ pé tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n bí i láàyè, ó máa ní àwọn àìlera tó lágbára. Ọjọ́ tí wọ́n ti bí i ló ti nílò iṣẹ́ abẹ. Abkhazia ni àwọn òbí ẹ̀ ń gbé, ìyẹn àgbègbè kan tó gbòmìnira kúrò lábẹ́ orílẹ̀-èdè Jọ́jíà. Àwọn òbí Sanel ò rí dókítà tó máa ṣiṣẹ́ abẹ fún un láìlo ẹ̀jẹ̀.

Àwọn òbí Sanel kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn * tó wà nílùú wọn. Ara tù wọ́n gan-an nígbà táwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ yìí bá wọn rí dókítà kan tó máa ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ nílùú Tbilisi, olú-ìlú Jọ́jíà. Àmọ́ ara ìyá Sanel ò tíì fi bẹ́ẹ̀ le lẹ́yìn tó bímọ, torí náà kò lè rìnrìn àjò. Ni wọ́n bá pinnu pé ìyá ìyá Sanel àti ìyá bàbá ẹ̀, ló máa gbé ọmọ jòjòló náà lọ sílé ìwòsàn tó wà nílùú Tbilisi. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ìyá méjèèjì yìí.

Iṣẹ́ abẹ náà gbẹgẹ́, àmọ́ ó yọrí sí rere. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn ìyá àgbà méjèèjì kọ̀wé pé: “Ó lé lógún [20] ọjọ́ tá a fi wà nílé ìwòsàn náà. Ní gbogbo àsìkò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ní Jọ́jíà ló wá kí wa, tí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló bá wa kẹ́dùn. A ti kà nípa bí ẹgbẹ́ ará wa ṣe ń fìfẹ́ hàn, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, àwa fúnra wa ti mọ bó ṣe máa ń rí lára.”

^ ìpínrọ̀ 4 Ní Jọ́jíà, àwọn alàgbà tó ń sìn nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ti fẹnu kò pẹ̀lú àwọn dókítà tó lé ní igba ó lé àádọ́ta [250] tí wọ́n gbà láti ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.