Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 JỌ́JÍÀ

Wọ́n Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn Atóbilọ́lá

Wọ́n Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn Atóbilọ́lá

Ọ̀dọ́ ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a kà nípa wọn ní àwọn ojú ìwé tó ṣáájú, wọ́n ‘rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ní ọ̀dọ́kùnrin.’ (Oníw. 12:1) Kódà, ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàdínnígba [3,197] tó wà ní Jọ́jíà ló jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀. Kí ló jẹ́ kí púpọ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́ yìí máa ṣe dáadáa nínú òtítọ́?

Ó jọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Òótọ́ kan ni pé, àwọn ìdílé ní Jọ́jíà sábà máa ń gbádùn kí wọ́n jọ máa wà pa pọ̀. Konstantine tó tọ́ ọmọ márùn-ún dàgbà nínú òtítọ́ sọ pé: “Ohun tó fà mí wá sínú òtítọ́ ni bí mo ṣe mọ̀ pé Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà. Nígbà témi náà di bàbá, ohun tí mò ń wá ni bí màá ṣe jẹ́ kí ara máa tu àwọn ọmọ mi tí wọ́n bá ti rí mi.”

 Malkhazi àti ìyàwó ẹ̀ táwọn náà lọ́mọ mẹ́ta sapá gan-an kí wọ́n lè mú kí okùn ìfẹ́ ìdílé wọn yi. Ó sọ pé: “Látìgbàdégbà, àá ní kí àwọn ọmọ wa ronú ohun tí wọ́n fẹ́ràn nípa wa àti nípa ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wọn. Lẹ́yìn náà, àá ní kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n rò tó bá dìgbà ìjọsìn ìdílé wa. Èyí ti wá jẹ́ kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń rí ibi táwọn míì dáa sí, kí wọ́n sì mọyì wọn.”

“Ayé Mi Ti Wá Ládùn, Ó Ti Lóyin!”

Àwọn alàgbà máa ń ti àwọn òbí lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n máa ń fún wọn níṣẹ́ nínú ìjọ ní kété tí wọ́n bá ti rí i pé wọ́n lè ṣe é. Nestori, tó ṣèrìbọmi nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá [11] sọ pé: “Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni àwọn alàgbà ti ń fún mi lóríṣiríṣi iṣẹ́ kéékèèké. Èyí jẹ́ kí n máa rí ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìjọ.”

Ohun pàtàkì míì tún ni ti àwọn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere àti bí àwọn alàgbà ṣe ń ti àwọn ará lẹ́yìn. Koba tó jẹ́ ọ̀kan lára  àwọn ẹ̀gbọ́n Nestori sọ pé, “Ayé mi ò rí bíi tàwọn ọmọ ìyá mi yòókù, nǹkan le gan-an nígbà tí mò ń dàgbà, tí mi ò tíì pé ogún [20] ọdún. Alàgbà kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀ lọ̀rọ̀ mi sábà máa ń yé, kì í sì í rò mí pin, àpẹẹrẹ rere ló jẹ́ fún mi. Ipa pàtàkì ló kó láyé mi tí mo fi lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.”

Lónìí, Nestori àti Koba pẹ̀lú Mari ẹ̀gbọ́n wọn jọ ń sìn ní ìpínlẹ̀ kan tó wà ní àdádó. Koba sọ pé, “Ayé mi ti wá ládùn, ó ti lóyin!”

“Àwọn Ọmọ Mi Ń Bá A Lọ ní Rírìn Nínú Òtítọ́”

Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti àwọn òbí lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n máa ń pe àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n wá lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run ń ṣe. Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé: “A mọyì àwọn ọ̀dọ́ wa, torí ẹ̀ la ṣe tì wọ́n lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń sapá kí ọwọ́ wọn lè tẹ àfojúsùn tẹ̀mí tí wọ́n ní.”

Àwọn ará tó wà ní Jọ́jíà ń bá àwọn òṣìṣẹ́ káyé ṣiṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ nílùú Tbilisi

Àwọn ọ̀dọ́ kì í gbàgbé ohun tí wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọ́n sì jọ ń kẹ́gbẹ́. Mamuka tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ káyé lẹ́nu kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nílùú Tbilisi sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá àwọn tó ń kọ́lé láti orílẹ̀-èdè kan dé orílẹ̀-èdè míì ṣiṣẹ́ ti fún mi láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ tí mo kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará bá a ṣe ń ṣiṣẹ́, mo tún kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó máa jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.”

Ipa rere ni ìdílé tó sún mọ́ra, ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti àwọn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere ní lórí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó wà ní Jọ́jíà. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára àpọ́sítélì Jòhánù ló rí lára àwọn òbí wọn. Jòhánú sọ pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”3 Jòh. 4.

 Bí Wọ́n Ṣe Túbọ̀ Jára Mọ́ Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Èdè

Lọ́dún 2013, Ìgbìmọ̀ Olùdárí ní kí gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹ ìpínlẹ̀ wọn wò bóyá àwọn tó ń sọ èdè míì máa nílò àwọn ìtẹ̀jáde wa ní èdè wọn. Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.

Bó ṣe di pé ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Jọ́jíà wá pinnu láti túmọ̀ àwọn ìwé wa kan sí èdè Svan àti Mingrelian nìyẹn, ìyẹn àwọn èdè Jọ́jíà méjì tó jọra gan-an, àwọn kan tiẹ̀ máa ń kà wọ́n sí èdè àdúgbò.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara kan láti àgbègbè Svaneti kọ̀wé pé: “Àwọn ará Svan kì í fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeré rárá, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún Bíbélì gan-an. Kódà, ó wú àwọn tí kì í kọ́kọ́ fẹ́ gba ìwé wa lórí láti bẹ̀rẹ̀ sí í gba àwọn ìwé tí wọ́n tú sí èdè àbínibí wọn.”

 Orí gbogbo àwọn akéde tó ń sọ èdè Mingrelian ló ń wú nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Giga, aṣáájú-ọ̀nà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Ní báyìí, mo ti lè sọ̀rọ̀ lọ́rọ̀ ara mi nínú ìpàdé. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dígbà tí mo bá kọ́kọ́ fọpọlọ túmọ̀ ohun tí mo fẹ́ sọ kí n tó lè dáhùn nípàdé.”

Zuri tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ tó ń sọ èdè Mingrelian nílùú Tkaia sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti ṣẹlẹ̀ láyé mi, èyí tó dáa àtèyí tí kò dáa, síbẹ̀ kò séyìí tó gbomi lójú mi rí. Àmọ́ nígbà tá a kọ́kọ́ kọ orin Ìjọba Ọlọ́run lédè Mingrelian nípàdé, kò sẹ́ni tómi ò bọ́ lójú ẹ̀, títí kan èmi náà.”

Àwọn Ohun Mánigbàgbé Tó Wáyé Lẹ́nu Àìpẹ́ Yìí

Ohun mánigbàgbé kan wáyé nínú ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà ní Saturday, April 6, 2013. Lọ́jọ́ yẹn, arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ  àsọyé ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n tún ṣe, tí wọ́n sì mú kó fẹ̀ sí i àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan pẹ̀lú ìlé ẹ̀kọ́ Bíbélì tuntun. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà ló fàyè sílẹ̀ nínú ilé wọn kí àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìdínlógójì [338] tó wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélógún [24] lé ríbi dé sí, tọkàntọkàn ni wọ́n sì fi gbà wọ́n.

Lọ́jọ́ kejì, Arákùnrin Splane sọ àkànṣe àsọyé fún ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé igba [15,200] èèyàn, ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán ni wọ́n fi gbọ́ àsọyé náà ní àwọn ìjọ tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Irú èyí ò ṣẹlẹ̀ rí ní Jọ́jíà, pé kí àwọn èrò tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gbọ́ àsọyé látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run. Ó wúni lórí gan-an bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ṣe ń fún ara wọn níṣìírí tí wọ́n sì jọ ń láyọ̀. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé, “Mo ti wá mọ bí ayé tuntun ṣe máa rí.”

Ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Tbilisi, lọ́dún 2013

Ìbùkún ńlá ni Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya tá à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà tó wà ní Jọ́jíà. Látọdún 2013, àwọn tó lé ní igba [200] ló ti kẹ́kọ̀ọ́ yege. Ó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí láti fìtara sìn níbikíbi tí àìní bá wà torí pé wọ́n mọyì ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbà.

“Nínàgà sí Àwọn Ohun tí Ń Bẹ Níwájú”

Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ àwọn tó kọ́kọ́ fìgboyà wàásù Ìjọba Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà, ìròyìn nípa Ìjọba Ọlọ́run ti wá dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè náà báyìí. Jèhófà bù kún ìfẹ́ àtọkànwá tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wọn, títí kan ìgbàgbọ́ wọn, ìgboyà wọn àti bí wọ́n ṣe ń lo ọgbọ́n inú.

Inú àwọn ará tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún [18,000] ní Jọ́jíà ń dùn bí wọ́n ṣe ń ṣe irú iṣẹ́ tí àwọn tó ṣáájú wọn ṣe, tí wọ́n sì ń ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó láti yí ìgbésí ayé ẹni pa dà.Fílí. 3:13; 4:13.

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Jọ́jíà: Wayne Tomchuk, Levani Kopaliani, Joni Shalamberidze, Michael E. Jones