Ìpàdé Kristẹni táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ń lọ wà lára ohun pàtàkì tó mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Kódà, ó máa ń yá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lára, bíi tàwọn tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, láti gbà káwọn ará máa wá ṣèpàdé nílé wọn. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi máa ń kí gbogbo àwọn tó wá káàbọ̀, èyí sì tún mú kí ìfẹ́ wọn túbọ̀ lágbára.

Táwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi, ìṣètò máa ń wà láti dọ́gbọ́n ṣe àwọn ìpàdé kan lákànṣe. Ní August 1973, àwọn ará ṣe irú ìpàdé yìí ní ẹ̀yìn ìlú Sokhumi, létí Òkun Dúdú. Àmọ́ àwọn márùndínlógójì [35] tó yẹ kó ṣèrìbọmi ò ráyè ṣe é, torí pé kí ìpàdé yẹn tó parí, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ibẹ̀, wọ́n sì mú  àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan, títí kan Vladimir Gladyuk.

Gbàrà tí wọ́n dá arákùnrin Vladimir àtàwọn ará tó kù sílẹ̀, ṣe ni wọ́n lọ kàn sí gbogbo àwọn tó yẹ kó ṣèrìbọmi. Ẹ̀yìn ọjọ́ méjì tó yẹ kí wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe é ni wọ́n tó rí i ṣe. Vladimir sọ pé: “A rí i pé Jèhófà wà lẹ́yìn wa. Lẹ́yìn ìrìbọmi náà, gbogbo wa gbàdúrà pa pọ̀, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.”

Àtakò Mú Kí Iṣẹ́ Ìwàásù Tàn Dé Ibòmíì

Ọjọ́ méjì lẹ́yìn ìrìbọmi náà, wọ́n tún mú Vladimir Gladyuk. Nígbà tó yá, wọ́n rán òun, Itta Sudarenko àti Natela Chargeishvili lọ sẹ́wọ̀n ọdún díẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yìí dun àwọn ará, wọ́n pinnu pé àwọn á máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ, àmọ́ àwọn á túbọ̀ máa ṣọ́ra ṣe.

Káwọn aláṣẹ má bàa dájú sọ àwọn akéde yìí, wọ́n máa ń kúrò nílùú wọn, wọ́n á sì rìnrìn àjò lọ sí àwọn ìlú míì àtàwọn abúlé láti lọ wàásù. Bí àtakò táwọn aláṣẹ ń ṣe ṣe mú kí iṣẹ́ ìwàásù tàn dé ibòmíì nìyẹn.

Nígbà ìjọba Kọ́múníìsì, àwọn ará tó ń gbé ìlú ńlá máa ń wàásù láwọn ojú ọ̀nà tó pa rọ́rọ́ àti ibi táwọn èèyàn ń gbé ọkọ̀ sí. Wọ́n sábà máa ń rí àwọn tó wá kí àwọn èèyàn wọn láti ìlú míì tàbí abúlé tàbí àwọn tó wá rajà. Táwọn ará bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n á béèrè àdírẹ́sì ẹni náà, wọ́n á sì ṣètò bí wọ́n á ṣe tún pa dà ríra.

Arábìnrin Babutsa Jejelava wà lára àwọn tó rìnrìn àjò káàkiri ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Jọ́jíà. Ó sọ pé: “Kò sẹ́ni tó fura sí mi bí mo ṣe ń rìnrìn àjò lemọ́lemọ́ torí mo ní mọ̀lẹ́bí káàkiri. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì, àwọn tó lé  ní ogún [20] ni mo ti ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílùú Zugdidi, àwọn márùn-ún míì sì wà nílùú Chkhorotsku. Gbogbo wọn pátá ló ṣèrìbọmi.”

Wọ́n Nílò Ìtẹ̀jáde Lédè Jọ́jíà Gan-an

Kò pẹ́ tó fi ṣe kedere pé àwọn ará nílò ìtẹ̀jáde gan-an lédè Jọ́jíà. Táwọn akéde bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí tí wọ́n lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n máa ń rí i pé àwọn nílò Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì ní èdè tó yé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn jù. *

Babutsa rántí bó ṣe máa ń nira tó láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìsí ìtẹ̀jáde kankan lédè Jọ́jíà. Ó sọ pé, “Èdè Rọ́ṣíà nìkan ni Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tí mo ní, torí náà, mo sábà máa ń túmọ̀ ìwé tí mo fẹ́ fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ sí èdè Jọ́jíà.” Dikiṣọ́nnárì nìkan ni arábìnrin Babutsa ní tó fi ń túmọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ inú àwọn ìwé ìròyìn wa sí èdè Jọ́jíà. Ó tiẹ̀ tún sapá láti túmọ̀ ìwé Ìhìn Rere Mátíù látòkèdélẹ̀!

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó nígboyà fi àwọn ẹ̀rọ kéékèèké ṣe ẹ̀dà ìwé nínú ilé wọn

Àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ mọyì àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n túmọ̀ sí èdè àbínibí wọn yìí débi pé wọ́n ṣe tán láti fọwọ́ da àwọn ìwé náà kọ káwọn náà lè máa rí i lò. Torí pé ẹ̀dà Bíbélì ṣòro rí lédè Jọ́jíà, lára àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ dà á kọ, wọ́n wá di “adàwékọ” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

“Àtàárọ̀ Ṣúlẹ̀ Ni Mo Fi Ń Da Ìwé Kọ”

Kí gbogbo àwọn ará àtàwọn tó ti ń wá sípàdé lè ka àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Jọ́jíà, ohun tí wọ́n ṣe ni pé, tẹ́ni kan bá ti kà á tán, á fún ẹlòmíì. Ìwé kan kì í  lò ju ọjọ́ mélòó kan tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n tú sí èdè Jọ́jíà òde òní wá tẹ àwọn ará lọ́wọ́, ìdílé kan sọ pé àwọn máa fọwọ́ kọ ọ́ sínú ìwé míì.

Ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] péré ni Raul Karchava nígbà tí bàbá rẹ̀ ní kó fọwọ́ da Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì kọ. Ó ní: “Bàbá mi ra ọ̀pọ̀ ìwé tuntun, oríṣiríṣi báírò àti pẹ́ńsù, wọ́n ń wò ó pé ìyẹn máa jẹ́ kó wù mí kọ. Ó kọ́kọ́ ṣe mí bíi pé mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ ńlá náà, àmọ́ mo gbà pé màá ṣe é. Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo fi ń da ìwé kọ, àfi tí mo bá kàn dúró díẹ̀, kí n lè na ọwọ́ mi.”

Ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Jọ́jíà

Ọ̀pọ̀ ló ń fẹ́ kí Ìwé Mímọ́ yìí tètè dọ́wọ́ àwọn náà, àmọ́ inú àwọn mọ̀lẹ́bí Raul dùn gidigidi nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn ará fẹ́ kí ìwé náà ṣì lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan sí i  lọ́wọ́ ìdílé wọn kí ọmọ wọn Raul lè parí akọ iṣẹ́ tó ń ṣe. Oṣù méjì péré ni Raul fi da gbogbo ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì kọ!

Pẹ̀lú bí àwọn ará yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti da ìwé kọ, ebi tẹ̀mí ṣì ń pa àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ torí pé wọ́n ń pọ̀ sí i. Kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, ṣe làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nígboyà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé nínú ilé wọn, tí wọ́n sì ń pín in kiri, láìfi ewu tó wà níbẹ̀ pè.

Iṣẹ́ ìwàásù ti ń gbilẹ̀ gan-an ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Jọ́jíà. Ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà wá ńkọ́? Ṣé ẹnì kankan wà nílùú Tbilisi, olú-ìlú Jọ́jíà, tó lè ran àwọn tó ń wá òtítọ́ lójú méjèèjì lọ́wọ́, bíi Vaso Kveniashvili tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀?

 Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Dé Olú-Ìlú Jọ́jíà

Láàárín ọdún 1970 sí 1979, àwọn aláṣẹ ìjọba Soviet Union gbìyànjú láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lé wọn kúrò ní ilé wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Oleksii àti Lydia Kurdas nìyẹn tí wọ́n fi kó lọ sílùú Tbilisi. Orílẹ̀-èdè Ukraine ni tọkọtaya yìí ti wá. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n sì ti lò lẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ Soviet Union torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Larisa Kessaeva (Gudadze) rèé láàárín ọdún 1970 sí 1979

Oleksii àti Lydia wàásù fún Zaur àti Eteri Kessaev, tọkọtaya tí kì í fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré. Larisa ọmọ wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] nígbà yẹn sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Oleksii àti Lydia kọ́kọ́ wàásù fún wọn, ó ní: “A fẹ́ jẹ́ kó yé wọn pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nìkan ni wọ́n ti ń ṣe ìsìn tòótọ́. Nígbà tá a fa ọ̀rọ̀ náà débì kan, a ò rí nǹkan kan sọ mọ́, àmọ́ àwọn ṣì ń fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ wọn.”

Larisa ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Tá a bá lọ ṣọ́ọ̀ṣì, mo máa ń ka Òfin Mẹ́wàá tí wọ́n kọ sára ògiri láàárín ère méjì tó wà níbẹ̀. Àmọ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn tí Oleksii ka ìwé Ẹ́kísódù 20:4, 5 fún wa, ó yà mí lẹ́nu gan-an. Mi ò rí oorun sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ṣe ni mò ń rò ó ṣáá pé: ‘Àbí òótọ́ ni pé à ń ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run bá a ṣe ń jọ́sìn ère ni?’”

Kí ọ̀rọ̀ yìí lè tán lọ́kàn Larisa, ṣe ló sáré lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ìlú wọn láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì. Nígbà tó débẹ̀, ó tún òfin náà kà, tó sọ pé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ . . . Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn.” Ìgbà yẹn ni òfin Ọlọ́run yìí kọ́kọ́ yé Larisa láyé ẹ̀. Nígbà tó yá, Larisa àtàwọn òbí ẹ̀ ṣèrìbọmi, wọ́n sì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Tbilisi.

 Ó Rí Ohun Tó Ń Fẹ́

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún [20] ọdún lẹ́yìn tí Vaso Kveniashvili ti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kó tó wá rí ẹnì kan tó ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Tbilisi. Bí Vaso ṣe pa dà rí àwọn Ẹlẹ́rìí yìí múnú ẹ̀ dùn gan-an, torí ọjọ́ pẹ́ tó ti ń wá wọn.

Vaso Kveniashvili di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlélógún [24] tó ti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú yẹn ò kọ́kọ́ fẹ́ kí Vaso bá wọn dá sí àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe, torí pé ọ̀daràn ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí tẹ́lẹ̀. Ẹ̀rù tiẹ̀ ń ba àwọn kan pé kó má lọ jẹ́ àwọn aláṣẹ ìjọba Soviet Union ló dọ́gbọ́n rán an sáàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, odindi ọdún mẹ́rin ni wọn ò fi gbà kí Vaso wá sípàdé.

Nígbà tí wọ́n wá rí i pé Vaso kì í ṣe èèyàn bẹ́ẹ̀, pé ọwọ́ ẹ̀ mọ́, wọ́n gbà kó máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ náà, ó sì ṣèrìbọmi. Bí Vaso ṣe láǹfààní láti sún mọ́ “Ọlọ́run ìdájọ́ [òdodo]” tó ti ń wá látìgbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́ nìyẹn o!  (Aísá. 30:18) Bó ṣe wá Jèhófà tọkàntọkàn yẹn náà ló ṣe sìn ín títí ó fi kú lọ́dún 2014.

Ìgbà tó fi máa di ọdún 1990, iṣẹ́ ìwàásù ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ gan-an ní ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn Jọ́jíà. Àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] ń kọ́ àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé méjìlélógójì [942] èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ yìí ló máa jẹ́ ìpìlẹ̀ àwọn ohun àgbàyanu tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 12 Nígbà ìjọba Kọ́múníìsì, ó ṣòro láti rí Bíbélì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti túmọ̀ àwọn apá kan sí èdè Jọ́jíà tipẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún.—Wo àpótí “Bíbélì Lédè Jọ́jíà.”