Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017

Àwọn ará wà nípàdé tí wọ́n ṣe nílùú Tbilisi lọ́dún 1992

 JỌ́JÍÀ | 1991-1997

“Ọlọ́run Ń Mú Kí Ó Máa Dàgbà.”—1 Kọ́r. 3:6.

“Ọlọ́run Ń Mú Kí Ó Máa Dàgbà.”—1 Kọ́r. 3:6.

Genadi Gudadze ṣe alábòójútó àyíká láàárín ọdún 1990 sí 1994

 ỌDÚN 1991 ni orílẹ̀-èdè Jọ́jíà gbòmìnira, ọdún yẹn sì ni ìjọba Soviet Union kógbá wọlé. Àmọ́ ìyípadà tó bá ìjọba àti ogun abẹ́lé tó ń ṣẹlẹ̀ mú kí ayé nira gan-an fáwọn èèyàn. Genadi Gudadze tó jẹ́ alábòójútó àyíká láwọn ọdún yẹn sọ pé ṣe làwọn èèyàn máa ń tò sórí ìlà látàárọ̀ ṣúlẹ̀ kí wọ́n lè rí búrẹ́dì gbà.

Lákòókò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run látinú Bíbélì fáwọn tó wà lórí ìlà. Genadi sọ pé, “Láwọn ọdún tí nǹkan le yẹn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé pélébé tí wọ́n kọ àdírẹ́sì sí là ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

 Lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí, àwọn arákùnrin tó tóótun máa ń ka orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn tó ní kí wọ́n wá bẹ àwọn wò. Àwọn akéde á wá ṣètò bí wọ́n á ṣe lọ bá wọn.

Láàárín ọdún 1990 sí 1999, wọ́n ń wàású fáwọn tó tò sórí ìlà tí wọ́n fẹ́ gba búrẹ́dì

Arákùnrin Levani Sabashvili tó jẹ́ alàgbà ní ìlú Tbilisi sọ pé òun rántí tọkọtaya kan tó ní kí wọ́n wá bẹ àwọn wò. Ó ní, “Àwọn akéde pín gbogbo àdírẹ́sì náà láàárín ara wọn, àmọ́ kò sẹ́ni tó fẹ́ lọ sọ́dọ̀ tọkọtaya yìí. Torí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnnà gan-an, púpọ̀ nínú wa ló sì ti ní ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, tọkọtaya yìí tún fìwé ránṣẹ́ pé kí wọ́n wá bẹ àwọn wò. Nígbà tó yá, wọ́n fìwé kẹta ránṣẹ́, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n kọ ìwé míì kún un tí wọ́n fi bẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n má jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 20:26, 27) Levani sọ pé: “Àsìkò Ọdún Tuntun ló bọ́ sí, a kì í sì í fẹ́ bẹ àwọn èèyàn wò lákòókò yẹn. Àmọ́ a rí i pé a ò lè sún ìbẹ̀wò náà síwájú mọ́.”

Ó ya Roini àti ìyàwó rẹ̀ Nana Grigalashvili tí wọ́n ti ń wá gbogbo ọ̀nà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí Levani àti arákùnrin míì lẹ́nu ọ̀nà wọn láàárọ̀ ọjọ́ kan tí òtútù mú gan-an. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, Roini àti Nana ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.

Ìsapá tí Àwọn Ará Ṣe Láti Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tó Fẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

Ìdùnnú tó ṣubú layọ̀ fáwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ mú kí wọ́n lo àkókò wọn, okun wọn àti àwọn ohun ìní wọn tinútinú láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run fáwọn míì. Pẹ̀lú gbogbo bùkátà ìdílé tó já lé Badri àti Marina Kopaliani léjìká, wọ́n wà lára àwọn tó rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ sí àwọn abúlé tó wà ní àdádó kí wọ́n lè ran àwọn tó lọ́kàn ìfẹ́ lọ́wọ́.

 Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, Badri àti Marina pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, Gocha àti Levani, tí kò tíì pé ogún [20] ọdún máa ń ṣètò láti rìnrìn àjò lọ sí àgbègbè Dusheti, ìyẹn àgbègbè olókè tó rẹwà ní àríwá Tbilisi. Ìgbà míì wà tí wọ́n máa ń rin nǹkan bí àádọ́jọ [150] kìlómítà gba ọ̀nà tó rí kọ́lọkọ̀lọ láti dé àwọn abúlé tó jìnnà.

Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan pe Badri àti ìyàwó rẹ̀ wá síbi iṣẹ́ rẹ̀. Badri sọ pé: “Nígbà tá a dé yàrá ńlá tó mú wa lọ, nǹkan bí àádọ́ta [50] èèyàn la bá níbẹ̀ tí wọ́n ń dúró dè wá! Ṣe lẹnu kọ́kọ́ yà mí, mi ò mọ ohun tí ǹ bá ṣe, àmọ́ lẹ́yìn tí mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn jíròrò àwọn ẹsẹ tó wá nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún [24], èyí tó dá lórí àmì ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹnì kan tọ́rọ̀ náà yà lẹ́nu sọ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn àlùfáà wa ò fi máa sọ àwọn nǹkan yìí fún wa?’”

Ìrántí Ikú Kristi Tó Gba Àfiyèsí Àwọn Èèyàn

Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ara Jọ́jíà tó lọ́kàn ìfẹ́ túbọ̀ láǹfààní láti gbọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún  1990, Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe nílé Arábìnrin la Badridze nílùú Tbilisi mú kí àwọn ará àdúgbò náà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ gan-an.

Arábìnrin la Badridze gba igba [200] èèyàn sí ilé rẹ̀ kí wọ́n lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi

Arábìnrin Badridze yọ̀ǹda ilé rẹ̀ kí wọ́n lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi níbẹ̀. Òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ jọ kẹ́rù kúrò nínú pálọ̀ kí àyè lè wà. Àmọ́ báwo ló ṣe máa rí àga tó pọ̀ tó fún àwọn tó ń bọ̀? Ní Jọ́jíà, àṣà wọn ni kí ìdílé lọ rẹ́ǹtì tábìlì àti ìjókòó tí wọ́n bá fẹ́ gbàlejò tó pọ̀. Àmọ́ ìjókòó nìkan ni Arábìnrin Badridze rẹ́ǹtì, ìyẹn mú káwọn oníṣọ́ọ̀bù náà máa bi í pé: “Ṣé ẹ ò ní gba tábìlì ni? Báwo lẹ ṣe máa jẹun?”

Arábìnrin Badridze rí àyè fún gbogbo àwọn tó wá sílé rẹ̀ tó wà ní àjà kẹtàlá ilé tó ń gbé, láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ó wúni lórí pé igba [200] èèyàn ló wá! Abájọ tí ọ̀pọ̀ ará àdúgbò fi bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ìbéèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!

Ìrántí Ikú Kristi tí Kò Ṣeé Gbàgbé

Lọ́dún 1992, gbọ̀ngàn ńlá láwọn ará gbà kí wọ́n lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi láwọn ibì kan lórílẹ̀-èdè náà. Davit Samkharadze tó ń gbé nílùú Gori rántí bí alábòójútó arìnrìn-àjò kan ṣe bi wọ́n nípa ètò tí wọ́n ṣe fún Ìrántí Ikú Kristi.

 Nígbà tí alábòójútó arìnrìn-àjò náà gbọ́ pé ilé àdáni ni wọ́n fẹ́ lò, ó bi wọ́n pé: “Ṣé kò sí gbọ̀ngàn ńlá nílùú yìí ni? Kí ló dé tí ẹ ò lọ gba ibẹ̀?” Àmọ́, torí pé àwọn akéde náà ò ju ọgọ́rùn-ún [100] lọ, tó sì jẹ́ pé gbọ̀ngàn náà lè gbà ju ẹgbẹ̀rún [1,000] èèyàn lọ, wọn ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n lọ gba ibẹ̀.

Alábòójútó arìnrìn-àjò náà wá mú àbá kan wá, ó ní: “Tí akéde kọ̀ọ̀kan bá lè pe èèyàn mẹ́wàá wá, gbogbo ìjókòó ló máa kun.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àbá náà lè kọ́kọ́ dà bíi pé kò gbéṣẹ́, àwọn akéde náà sapá láti tẹ̀ lé e. Ó yà wọn lẹ́nu gan-an, inú wọn sì dùn dọ́ba nígbà tí wọ́n rí àwọn tó wá, ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́rìndínlógójì [1,036] èèyàn ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi! *

Àwọn Aṣáájú-ọ̀nà Onítara Dé Àwọn Ìpínlẹ̀ Tuntun

Lọ́dún 1992, àwọn àgbègbè kan ṣì wà ní Jọ́jíà tí àwọn èèyàn Jèhófà ò tíì wàásù dé. Báwo làwọn ara ṣe máa dé àwọn ìpínlẹ̀ tuntun yìí nígbà tó jẹ́ pé ọrọ̀ ajé ò lọ déédéé lórílẹ̀-èdè náà?

Tamazi Biblaia tó ń gbé ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́jíà lákòókò náà sọ pé: “Alábòójútó arìnrìn-àjò kan pe àwa mélòó kan jọ, ó sì bá wa jíròrò ohun tá a lè ṣe. A ò ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe ń ṣètò àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere náà láìjáfara.” (2 Tím. 4:2) Torí náà, wọ́n yan àwọn aṣáájú-ọ̀nà mẹ́rìndínlógún [16], wọ́n sì pín wọn káàkiri orílẹ̀-èdè náà.—Wo máàpù tó wà lójú ìwé tó tẹ̀ lé e.

Àwọn ibi tí wọ́n yan àwọn aṣáájú-ọ̀nà sí pé kí wọ́n ti fi oṣù márùn-ún wàásù

Ní oṣù May 1992, a ṣe ìpàdé wákàtí mẹ́ta nílùú Tbilisi láti fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà níṣìírí, ìyẹn àwọn tí wọ́n yàn  pé kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ yẹn fóṣù márùn-ún. Lóṣooṣù, àwọn alàgbà máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé wọn ró, kí wọ́n sì fún wọn láwọn ohun míì tí wọ́n bá nílò.

Wọ́n yan àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pé kí wọ́n lọ sí ìlú kan tó ń jẹ́ Ozurgeti, orúkọ wọn ni Manea Aduashvili àti Nazy Zhvania. Manea tó jẹ́ ẹni ọgọ́ta [60] ọdún nígbà yẹn sọ pé, “A mọ̀ pé ẹnì kan tó máa ń fẹ́ gbọ́rọ̀ wa ń gbé ní tòsí ìlú Ozurgeti. Torí náà, gbàrà tí a dé ìlú yẹn la ṣètò láti wá a lọ. Nígbà tí a dé ilé obìnrin náà, ó ti ń dúró dè wá, òun àti ọgbọ̀n [30] èèyàn tó pè wá sílé ẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ yẹn.”

Láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, ìsapá wa ń sèso rere. Lẹ́yìn oṣù márùn-ún péré, àwọn méjìlá [12] ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi!

Ẹ̀mí Ìfara-ẹni-rúbọ Wọn Mérè Wá

Wọ́n rán àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ sílùú Tsageri, orúkọ wọn ni Pavle Abdushelishvili àti  Paata Morbedadze. Àgbègbè kan tí àṣà ìbílẹ̀ ti gbilẹ̀ ni ìlú yẹn wà, tí wọ́n sì ti máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn.

Àyíká ìlú Tsageri

Nígbà tí àkókò òtútù fi máa bẹ̀rẹ̀, oṣù márùn-ún tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà máa lò ti fẹ́ parí, wọ́n sì pe Paata pé kó wá ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè níbòmíì. Ó wá di pé kí Pavle pinnu ohun tó máa ṣe. Ó ní: “Mo mọ̀ pé kò ní rọrùn láti lo àkókò òtútù nílùú Tsageri. Àmọ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣì nílò ìrànwọ́, torí náà mo pinnu pé màá dúró.”

Pavle sọ pé, “Mo dúró sọ́dọ̀ ìdílé kan nílùú yẹn, mo sì máa ń pẹ́ gan-an lóde ìwàásù. Tó bá wá di ìrọ̀lẹ́, màá dara pọ̀ mọ́ ìdílé náà níbi tí wọ́n ti ń yáná lẹ́gbẹ̀ẹ́ àdògán nínú pálọ̀ wọn tó wà nísàlẹ̀. Tó bá tó àkókò tó yẹ kí n gòkè lọ sí yàrá mi, màá dé fìlà òtútù mi, màá wá fi bùláńkẹ́ẹ̀tì tó nípọn bora tí mo bá ti fẹ́ sùn.”

Nígbà táwọn alàgbà bẹ Pavle wò nígbà ìrúwé, ẹni mọ́kànlá [11] ló ti tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Kò sì pẹ́ tí gbogbo wọn fi ṣèrìbọmi.

^ ìpínrọ̀ 20 Lọ́dún 1992, iye akéde onítara tó wà ní Jọ́jíà jẹ́ 1,869, iye àwọn tó sì wá síbi Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ 10,332.