Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017

 JỌ́JÍÀ

Àwọn Tó ŃSọÈdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Àwọn Tó ŃSọÈdè Kurdish Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

GULIZAR sọ pé, “Mi ò lè ṣe kí n máà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe jẹ́ kí n mọ òun lédè àbínibí mi.”

Ọdún mẹ́jọ ni Gulizar fi dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé tí wọ́n ń ṣe lédè ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn èdè Kurdish, ló tó ṣèrìbọmi. Ó wà lára ọ̀pọ̀ àwọn ará Kurd tó gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní Jọ́jíà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àmọ́ àwọn wo là ń pè ní Kurd?

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni àwọn tó ń sọ èdè Kurdish ti ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrun. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé  àtọmọdọ́mọ àwọn ará Mídíà ayé àtijọ́ tí Bíbélì sọ ni wọ́n. (2 Ọba 18:11; Ìṣe 2:9) Ọ̀kan lára èdè àwọn ará Ìráànì ni wọ́n ń sọ.

Lónìí, oríṣiriṣi orílẹ̀-èdè ni ọ̀pọ̀ mílíọ́nù àwọn ará Kurd ń gbé, títí kan Àméníà, Ìráànì, Ìráàkì, Síríà àti Tọ́kì. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn ará Kurd ló wà ní Jọ́jíà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fọ́rọ̀ Ọlọ́run.

Ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] akéde ló ń sọ èdè Kurdish ní Jọ́jíà báyìí, ìjọ mẹ́ta ni wọ́n sì ti ń sọ èdè náà. Lọ́dún 2014, inú gbogbo èèyàn ló ń dùn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe àpéjọ àgbègbè léde Kurdish nílùú Tbilisi, àwọn èèyàn sì wá láti orílẹ̀-èdè Àméníà, Jámánì, Tọ́kì àti Ukraine.