Joni Shalamberidze àti Tamazi Biblaia ṣáájú ọdún 1995

Láàárín ọdún 1990 sí 1994, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìjọ tó wà ní Jọ́jíà kò ní ju alàgbà kan péré tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan. Àwọn ará ìjọ kì í sábà pàdé pọ̀, àwùjọ kéékèèké ni wọ́n ti máa ń pàdé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ torí pé ńṣe láwọn akéde fọ́n káàkiri sáwọn ìpínlẹ̀ tó tóbi, tó sì ní ọ̀pọ̀ ìlú àti abúlé.

Wọ́n yan Joni Shalamberidze àti Pavle Abdushelishvili tí wọ́n ti sìn láwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní àdádó tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n lọ ṣèrànwọ́ ní Telavi, ìyẹn ìlú kan tó wà ní àgbègbè Kakheti. Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] akéde ló wà nínú ìjọ tó wà níbẹ̀, àmọ́ wọn ò ní ẹyọ alàgbà kan. Àwùjọ mẹ́tàlá [13] tó ń pàdé níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní.

Pavle Abdushelishvili

 Kò pẹ́ tí Joni àti Pavle fi kíyè sí ohun ńlá kan tó lè dènà ìtẹ̀síwájú àwọn ará tó wà níbẹ̀ nípa tẹ̀mí. Joni sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló dáko tó tóbi, tí wọ́n sì ní àwọn ọgbà àjàrà. Àmọ́, torí pé àṣà àwọn tó ń gbé lábúlé ni pé kí wọ́n máa ran ara wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ oko wọn, àwọn ará wa máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.”1 Kọ́r. 15:33.

Joni àti Pavle gba àwọn ará níyànjú pé àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn ni kí wọ́n máa pè tí wọn bá fẹ́ kórè oko. Ìyẹn máa ṣe wọ́n láǹfààní torí àwọn àtàwọn tó níwà rere ni wọ́n á jọ máa kẹ́gbẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ oko wọn. (Oníw. 4:9, 10) Joni sọ pé, “Okùn ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn ará nínú ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í lágbára sí i.” Nígbà tí Joni àti Pavle kúrò ní àgbègbè Kakheti lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, alàgbà márùn-ún àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjìlá [12] ni wọ́n fi sílẹ̀ nínú ìjọ náà.

Àwọn Ìpàdé Mú Káwọn Ará Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Torí pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa títí di àárín ọdún 1990 sí 1994, àwùjọ kéékèèké ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń pàdé, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ nìkan ni wọ́n sì máa ń ṣe. Bo tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpàdé náà máa ń fúnni níṣìírí, síbẹ̀ kì í ṣe èyí tó máa kọ́ àwọn akéde bí wọ́n á ṣe máa wàásù.

Nǹkan yí pa dà nígbà tí ìjọba Kọ́múníìsì fìdí rẹmi. Ni ètò Jèhófà bá ní kí àwọn ìjọ fi ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kún ìpàdé tí wọ́n ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀.

Naili Khutsishvili àti Lali Alekperova ẹ̀gbọ́n rẹ̀, kò jẹ́ gbàgbé àwọn àkókò alárinrin tí wọ́n ní bí wọ́n ṣe ń lọ sípàdé nígbà yẹn. Lali sọ pẹ́: “Àkókò alárinrin gbáà ni. Gbogbo wa là ń yọ̀ pé àwọn arábìnrin á lè máa ṣiṣẹ́ nípàdé báyìí.”

 Naili rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú àṣefihàn kan, ó ní: “Ìwé ìròyìn ni onílé ń kà lọ́wọ́ lórí pèpéle nígbà tó gbọ́ pé ẹni kan ń kan ilẹ̀kùn. Nígbà tó ní kí wọ́n wọlé, àwọn arábìnrin méjì gba ẹnu ọ̀nà wọlé sáàárín ìpàdé, wọ́n sì gun orí pèpéle!” Lali fi kún un pé, “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpàdé yẹn máa ń rí bákan nígbà míì, wọ́n ràn wá lọ́wọ́ ká lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.”

Àwọn Ará Túbọ̀ Nílò Oúnjẹ Tẹ̀mí

Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn arákùnrin kan fi ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ọlọ́wọ́ láti tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde nínú ilé. Torí pé ìwé tí àwọn ará ń béèrè túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn arákùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í lo ilé iṣẹ́ tó ń tẹ ìwé láti máa tẹ àwọn ìwé ìròyìn wa jáde ní iye tó mọn níwọ̀n.

Kí àwọn ará lè ṣètò ìwé tí wọ́n máa mú lọ sí iléeṣẹ́ ìtẹ̀wé, àwọn arákùnrin náà máa ń gé àwọn lẹ́tà látinú ìwé ìròyìn, wọ́n á wá lẹ̀ wọ́n mọ́ iwájú ìwé ti èdè Gẹ̀ẹ́sì

Àwọn ará máa ń fi ọgbọ́n lo ìwọ̀nba ohun tí wọ́n bá ní láti ṣe ẹ̀dà tí wọ́n máa mú lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń tẹ̀wé. Wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Jọ́jíà, wọ́n á tẹ̀ ẹ́ bó ṣe rí nínú ìtẹ̀jáde èdè Gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n á wá gé àwọn àwòrán tó wà lédè gẹ̀ẹ́sì, wọ́n á sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ìwé tí wọ́n tẹ̀. Paríparí ẹ̀, wọ́n á gé ọ̀rọ̀ látinú àwọn ìwé ìròyìn tó lo lẹ́tà tó fani mọ́ra, wọ́n á sì lẹ̀ ẹ́ mọ iwájú ìwé náà. Ó ti dọbẹ̀ nìyẹn, kí wọ́n mú un lọ síbi tí wọ́n á ti tẹ̀ ẹ́ ló kù!

Ara àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ ní Jọ́jíà

Nígbà tí kọ̀ǹpútà dé, àwọn arákùnrin méjì tó jẹ́ ọ̀dọ́, ìyẹn Levani Kopaliani àti Leri Mirzashvili, lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń lò ó dáadáa. Leri sọ pé: “A ò mọ nǹkan kan nípa kọ̀ǹpútà, nǹkan sì máa ń yíwọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, kò sì pẹ́ tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé ìròyìn, tá a sì ń fi kọ̀ǹpútà ṣètò wọn.”

Láìfi ti àwọn ìdènà tó wáyé pè, àwọn ìjọ káàkiri orílẹ̀-èdè Jọ́jíà ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìwé ìròyìn oníkọ́lọ̀ mẹ́rin gbà. Àmọ́ nígbà tó yá, apá ò fẹ́ ká a mọ́ torí iye táwọn èèyàn ń béèrè  ń pọ̀ sí i. Àkókò yìí gan-an ni ètò Ọlọ́run fìfẹ́ ran àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà ní Jọ́jíà lọ́wọ́.

Ìgbà Ọ̀tun Dé

Àpéjọ àgbáyé ọdún 1992 tí wọ́n ṣe nílùú St. Petersburg, ní Rọ́ṣíà, fún àwọn ará tó wá láti Jọ́jíà láǹfààní láti pàdé àwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì láti orílẹ̀-èdè Jámánì. Genadi Gudadze sọ pé, “Wọ́n ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè. Wọ́n sọ fún wa pé láìpẹ́ a máa gba ìbẹ̀wò tó máa ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè tá à ń ṣe.”

Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ń ṣe láti tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde lédè Jọ́jíà. Torí pé èdè náà ní àwọn lẹ́tà tó yàtọ̀ pátápátá, ètò orí kọ̀ǹpútà tí ètò Ọlọ́run ń lò láti fi ṣètò ìwé kí wọ́n tó tẹ̀ ẹ́, ìyẹn Multilanguage Electronic Publishing System (MEPS) kò bá álífábẹ́ẹ̀tì Jọ́jíà ṣiṣẹ́. Nígbà tó yá, ó di pé kí wọ́n ṣe àwọn álífábẹ́ẹ̀tì tó máa bá ètò orí kọ̀ǹpútà yìí ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè máa rí ìwé tẹ̀ jáde.

Ṣáájú àkókò yẹn, ìdílé kan ní Jọ́jíà, ìyẹn ìdílé Datikashvili, kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún díẹ̀ ṣáájú ọdún 1980. Ibẹ̀ ni Marina tó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọmọbìnrin yìí ṣèrànwọ́ gan-an nígbà táwọn ará tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn lẹ́tà Jọ́jíà kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè fi ṣe àwọn álífábẹ́ẹ̀tì tó máa bá MEPS ṣiṣẹ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí wọ́n fi tẹ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú kan àti ìwé pẹlẹbẹ, “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun” jáde lórílẹ̀-èdè Jámánì.

Bí Wọ́n Ṣe Bá Wọn Ṣètò Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Èdè

Lọ́dún 1993, Michael Fleckenstein àti Silvia ìyàwó ẹ̀, dé sí ìlú Tbilisi láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì kí wọ́n lè ṣètò ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Michael sọ pé: “Ìpàdé tá a ṣe nílùú St. Petersburg ò tíì kúrò lọ́kàn mi. Nígbà  tá a dé ìlú Tbilisi ní ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó yà wá lẹ́nu nígbà tí wọ́n fi àwùjọ atúmọ̀ èdè kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́ hàn wá!”

Leri Mirzashvili, Paata Morbedadze àti Levani Kopaliani ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè nílùú Tbilisi lọ́dún 1993

Láàárín oṣù mélòó kan, àwùjọ kan tó ní atúmọ̀ èdè mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ alákòókò kíkún ti ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì tó wà ní ilé kékeré kan. Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ ètò Ọlọ́run tó ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́ yìí, àwọn gan-an ni èjìká tí ò jẹ́ kí aṣọ bọ́ lọ́rùn ẹni. Oúnjẹ tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ sí í dé àwọn ìjọ lóòrèkóòrè.

Bí Oúnjẹ Tẹ̀mí Ṣe Ń Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Ará Lákòókò tí Nǹkan Le

Lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union kógbá wọlé, ogun abẹ́lé àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ìjọba yẹn tẹ́lẹ̀, kò sì yọ Jọ́jíà sílẹ̀. Èyí mú kó léwu láti máa rìnrìn àjò, pàápàá téèyàn bá fẹ́ wọnú ìlú tàbí tó fẹ́ jáde.

Arákùnrin Zaza Jikurashvili àti Aleko Gvritishvili (tí fọ́tò àwọn àti ìyàwó wọn wà níbí) máa ń já ìwé fáwọn ará láwọn ọdún tí nǹkan ò fara rọ

Lọ́jọ́ kan, ní November 1994, Aleko Gvritishvili àti àwọn arákùnrin méjì fẹ́ wọ ìlú kan, ni àwọn ọkùnrin kan tó dira ogun bá dá wọn dúró, wọ́n sì ní kí wọ́n bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ wọn. Aleko sọ pé, “Inú bí wọn gan-an nígbà tí wọ́n rí àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n tò wá sórí ìlà  bíi pé wọ́n máa pa wá. A gbàdúrà gan-an sí Jèhófà. Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí méjì, ọ̀kan nínú wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ gba ìwé yín, kẹ́ ẹ máa lọ, tẹ́ ẹ bá tún pa dà wá, ṣe la máa sọ iná sí ọkọ̀ yín, àá sì yanjú yín.’”

Pẹ̀lú gbogbo wàhálà yìí, àwọn arákùnrin náà ṣì ń kó ìwé lọ sọ́dọ̀ àwọn ará. Arákùnrin Zaza Jikurashvili tó forí ṣe fọrùn ṣe láti kó àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì wọlé sí Jọ́jíà sọ pé: “A mọ̀ pé àwọn ará wa nílò oúnjẹ tẹ̀mí. Àwọn ìyàwó wa àtàtà sì tì wá lẹ́yìn gan-an.”

Aleko sọ pé, “Olórí ìdílé ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn arákùnrin tó lọ ń já ìwé fáwọn ará.” Kí ló jẹ́ kí wọ́n máa bá iṣẹ́ wọn lọ láìfi ewu tó wà níbẹ̀ pè? Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kókó ibẹ̀ ni pé a moore Jèhófà láyé wa, a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. A tún fẹ́ kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn.”

Àbẹ́ ò rí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí àwọn arákùnrin náà ní? Ọ̀rọ̀ ọ̀hún tọ́pẹ́ ó ju ọpẹ́ lọ, kò sígbà táwọn ará ò rí ìwé gbà ní gbogbo ọdún tí nǹkan ò fara rọ yẹn. Nígbà tó yá, àwọn arákùnrin náà rí àwọn ọ̀nà tí kò léwu tí wọ́n lè máa gbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ kó ìwé láti orílẹ̀-èdè Jámánì wá sí Jọ́jíà.

Wọ́n Gba Ìṣírí Tó Bọ́ Sásìkò Kí Wọ́n Lè Lókun Nípa Tẹ̀mí

Nígbà tí wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba rọlẹ̀ lọ́dún 1995, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò bí wọ́n á ṣe ṣe àpéjọ àgbègbè wọn àkọ́kọ́. Ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1996, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] èèyàn láti ibi gbogbo ní Jọ́jíà ló wá sí àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe ní ìlú mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn Gori, Marneul àti Tsnori.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní àpéjọ àgbègbè nítòsí ìlú Gori lọ́dún 1996

Àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè nítòsí ìlú Gori ò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ náà. Nǹkan ti yí pa dà pátápátá sígbà tí kò dá àwọn ará lójú bóyá wọ́n á lè rí èèyàn tó máa kún gbọ̀ngàn ńlá  tí wọ́n gbà nígbà Ìrántí Ikú Kristi! Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] èèyàn tí wọ́n ń retí báyìí pé kó wá, àmọ́ wọn ò rí àyè tó máa lè gba gbogbo wọn. Ni wọ́n bá pinnu pé ìta gbangba làwọn á ti ṣe àpéjọ àgbègbè náà, níbi òkè kan tó rẹwà tí kò jìnnà sí ìlú náà.

Arákùnrin Kako Lomidze tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Àpéjọ Àgbègbè sọ pé: “Lẹ́yìn tí ìpàdé parí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lo ọ̀pọ̀ àkókò pa pọ̀, wọ́n ń kọrin, wọ́n sì ń gbádùn ará wọn. Gbogbo èèyàn ló fojú ara wọn rí i pé ìfẹ́ tó lágbára ló so àwọn èèyàn Ọlọ́run pọ̀ tí wọ́n fi wà níṣọ̀kan.”Jòh. 13:35.

Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́ Mú Kí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Túbọ̀ Gba Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Látọdún 1996, wọ́n ṣètò pé kí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa fi ọ̀sẹ̀ kan gbáko bẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè náà wò. Kí èyí lè ṣeé ṣe, wọ́n yan àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tuntun kún àwọn arákùnrin tí wọ́n ti ń sìn ní apá ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn Jọ́jíà.

Kò sí àní-àní pé “òpò onífẹ̀ẹ́” àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò yẹn àti bí wọ́n ṣe fòótọ́ inú ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè dàgbà nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni ètò Ọlọ́run dáadáa. (1 Tẹs. 1:3) Lọ́dún 1990 sí 1997, ìbísí tó wáyé gadabú. Ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rin [904] akéde ló ròyìn iṣẹ́ ìwàásù lọ́dún 1990, àmọ́ ọdún méje péré lẹ́yìn ìgbà yẹn, ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ó lé méjìlélọ́gọ́rin [11,082] ló ti ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run!

Ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ti wá délé dóko, ó sì ti tàn káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ Jèhófà ṣì ní ọ̀pọ̀ ìbùkún pa mọ́ fún àwọn èèyàn rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà.