LÁTI nǹkan bí ọdún 1995, ṣe ni inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Jọ́jíà ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí i tí iye àwọn akéde àtàwọn tó ń wá sípàdé ń pọ̀ sí i lọ́nà tó gadabú. Lọ́dún 1998, ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́sàn-án [32,409] èèyàn ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.

Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn akéde, títí kan àwọn tó jẹ́ alàgbà ni kò tíì pẹ́ nínú ètò, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa bójú tó oríṣiríṣi ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe máa rí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà gbà?

Ètò Jèhófà Túbọ̀ Ràn Wọ́n Lọ́wọ́

Ètò Ọlọ́run rán Arno àti Sonja Tüngler lọ sí Jọ́jíà ní March 1998, lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Jámánì. Ọdún yẹn kan náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ṣí ọ́fíìsì kan sí orílẹ̀-èdè Jọ́jíà, kí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sì máa bójú tó o.

Kò pẹ́ tí wọ́n fi ní Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù. Gbàrà tí òfin ti fọwọ́ sí iṣẹ́ wa ni wọ́n ti ń kó ìwé tó dá lórí Bíbélì wọlé sí Jọ́jíà láti ibi tí wọ́n ń pè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Jámánì nígbà yẹn. Bí òfin ṣe fọwọ́ sí àwọn ohun tá à ń ṣe tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ra ilẹ̀ tá a máa kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ẹ̀ka ọ́fíìsì sí.

Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́

Ọ̀pọ̀ akéde ni kò lè wàásù láti ilé dé ilé ní gbogbo ọ̀pọ̀ odún tí ìjọba Soviet Union fi fòfin de iṣẹ́ wa. Arno  Tüngler sọ pé: “Ojú ọ̀nà ni ọ̀pọ̀ akéde ti sábà máa ń wàásù, kì í ṣe gbogbo wọn ló mọ́ lára láti máa wàásù láti ilé dé ilé, kí wọ́n sì máa pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó gbọ́rọ̀ wọn.”

Arno àti Sonja Tüngler

Davit Devidze, tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì tuntun tí wọ́n dá sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà ní May 1999 sọ pé: “Iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ní Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kà àmọ́ tá ò mọ bá a ṣe máa ṣe é. Torí náà, ṣe la fara balẹ̀ wo bí àwọn arákùnrin tó nírìírí tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí rán wá ṣe ń ṣe nǹkan, a sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn.”

Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ará ní Jọ́jíà lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó fakíki. Àmọ́ bíi ti àwọn tó bá lọ sìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i lọ̀rọ̀ rí níbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí, ní ti pé àwọn ará tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nìkan kọ́ ló jàǹfààní níbẹ̀. (Òwe 27:17) Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn tó wá dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ náà kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará ní Jọ́jíà.

Ìwà Àwọn Ará ní Jọ́jíà Fani Mọ́ra

Arno àti Sonja ò jẹ́ gbàgbé báwọn ará ṣe gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀ nígbà tí wọ́n dé sí Jọ́jíà. Àwọn arákùnrin àtàwọn  arábìnrin níbẹ̀ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ara wọn lè mọlé lẹ́nu iṣẹ́ tuntun tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ yìí.

Sonja rántí ìwà ọ̀làwọ́ wọn. Ó ní: “Tọkọtaya kan tó ń gbé nítòsí ò lè ṣe kí wọ́n máà gbé oúnjẹ aládùn wá fún wa. Arábìnrin kan ní ká jọ ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù, ó fi ìjọ wa tuntun hàn wá, ó sì ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa àṣà ìbílẹ̀ Jọ́jíà. Arábìnrin mìíràn tún fara balẹ̀ kọ́ wa ní èdè Jọ́jíà.”

Warren àti Leslie Shewfelt, tí wọ́n rán wá sí Jọ́jíà láti orílẹ̀-èdè Kánádà lọ́dún 1999, sọ pé: “Bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ní Jọ́jíà ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn wú wa lórí gan-an, a sì rí i pé wọ́n yẹ lẹ́ni tí à ń fara wé. Tọmọdé tàgbà wọn ló nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọn ò sì fi bò.”

Àwọn ará ní Jọ́jíà bá àwọn míṣọ́nnárì tó nírìírí ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè náà

Àwọn tí wọ́n rán lọ sí Jọ́jíà láti orílẹ̀-èdè míì kì í jẹ́ kí ìṣòro tí wọ́n ń kojú gbà wọ́n lọ́kàn, ìwà rere àwọn ará ibẹ̀ ni wọ́n máa ń wò. Bákan náà, bí àwọn míṣọ́nnárì  yìí ṣe ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ ṣe nǹkan mú kí àwọn àtàwọn ará Jọ́jíà tètè mọwọ́ ara wọn.

Àwọn Tó Bẹ̀rù Ọlọ́run Gba Òtítọ́

Jálẹ̀ ọdún 1990 sí 1999, ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ́kàn ìfẹ́ ló ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lọ́dún 1998 nìkan, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́rìnlélógún [1,724] èèyàn ló ṣèrìbọmi. Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Jọ́jíà gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó bẹ́ẹ̀?

Tamazi Biblaia, tó fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ṣàlàyé pé: “Àtilẹ̀ làwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tá a bá ti bá wọn sọ ohun tó wà nínú Bíbélì, ojú ẹsẹ̀ ló ti máa ń wù wọ́n.”

Davit Samkharadze, tó jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run, sọ pé: “Tẹ́nì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò rẹ̀ sábà máa ń fẹ́ ṣèdíwọ́. Ibi tí wọ́n bá ti ń gbìyànjú láti dí ẹni náà lọ́wọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú wọn ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!”

Bí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tàn kálẹ̀, ó ń yí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn pa dà. Ní April 1999, àwọn ará ti pọ̀ sí i débi pé ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mọ́kàndínláàádọ́rin [36,669] èèyàn ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.

“Ọ̀pọ̀ Alátakò” Ló Wà

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe nílùú Éfésù ìgbà yẹn, ó ní: “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ alátakò ní ń bẹ.” (1 Kọ́r. 16:9) Ohun tó sọ bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará ní Jọ́jíà mu ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn Ìrántí Ikú Kristi tó jẹ́ mánigbàgbé tí wọ́n ṣe lọ́dún 1999.

 Lóṣù August ọdún yẹn, ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Vasili Mkalavishvili tí wọ́n ti yọ nípò àlùfáà ní ṣọ́ọ̀ṣì kó àwọn agbawèrèmẹ́sìn kan tí wọ́n ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lẹ́yìn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de nílùú Tbilisi, wọ́n sì dáná sun àwọn ìwé wa ní gbangba. Bí inúnibíni ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, ọdún mẹ́rin ni wọ́n sì fi ṣe é.

Látọdún 1999, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn tó ń wọ́de kiri dájú sọ, wọ́n ń dáná sun ìwé wọn, wọ́n sì ń gbógun tì wọ́n

Ní October 17, 1999, àwọn agbawèrèmẹ́sìn kan kó àwọn jàǹdùkú tó tó igba [200] lẹ́yìn, wọ́n sì lọ da ìpàdé tí Ìjọ Gldani nílùú Tbilisi ń ṣe rú. Kóńdó àti àgbélébùú onírin tí wọ́n kó dání ni wọ́n fi ń lu àwọn tó wà nípàdé yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ló ṣèṣe, tí wọ́n sì dèrò ilé ìwòsàn.

Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé wọn ò mú àwọn jàǹdùkú yẹn, wọn ò sì yéé yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan, títí kan Ààrẹ Shevardnadze, bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó ń hùwà yìí, àmọ́ kò sí ẹ̀rí pé wọ́n gbé ìgbésẹ̀. Kódà, ó máa ń pẹ́ lẹ́yìn tí wàhálà bá ti ṣẹlẹ̀ kí àwọn ọlọ́pàá tó dé.

Àkókò kan náà ni Guram Sharadze tó jẹ́ ara ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Jọ́jíà bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́ káàkiri, kò mú un ní kékeré rárá. Ó fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n lè da ìlú rú. Ó ti wá dà bíi pé “àsìkò tí ó rọgbọ” láti wàásù ìhìn rere ti dohun àtijọ́.

Ètò Jèhófà Ṣèrànwọ́ Nígbà Àtakò

Kíákíá ni ètò Jèhófà ran àwọn ará ní Jọ́jíà lọ́wọ́. Wọ́n fìfẹ́ kọ́ wọn lóhun tí wọ́n máa ṣe tí àwọn jàǹdùkú bá ti kó wàhálà wọn dé. Wọ́n sì rán wọn létí ìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń dojú kọ inúnibíni nígbà míì.2 Tím. 3:12.

 Yàtọ̀ síyẹn, ètò Jèhófà gbèjà àwọn ará wa lábẹ́ òfin nílé ẹjọ́. Arákùnrin kan tó ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Jọ́jíà sọ pé: “Láwọn ọdún mẹ́rin yẹn, ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] ìgbà tá a kọ̀wé sí ìjọba lórí ohun tí Vasili Mkalavishvili àtàwọn èèyàn ẹ̀ ń ṣe. A ní káwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ràn wá lọ́wọ́. Oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ìkéde tó ṣàrà ọ̀tọ̀ káàkiri, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ ọ̀rọ̀ náà ń fi lélẹ̀.” *

^ ìpínrọ̀ 30 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bá a ṣe jà fún ẹ̀tọ́ wa lábẹ́ òfin, wo Jí! January 22, 2002 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 18 sí 24.