BÍ Ọ̀RỌ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe tàn kálẹ̀ lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà bá ohun tí Jésù sọ mu gẹ́lẹ́ nínú àpèjúwe ìwúkàrà tó fara pa mọ́ sínú ìyẹ̀fun. (Mát. 13:33) Ó kọ́kọ́ dà bíi pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde lórílẹ̀-èdè náà, bí ìgbà tí ìwúkàrà fara pa mọ́ sínú ìyẹ̀fun, àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀kọ́ òtítọ́ délé dóko, ó sì yí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn pa dà.

Ka àwọn ìtàn amóríyá, tó wọni lọ́kàn nípa bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní Jọ́jíà ṣe fi hàn pé wọ́n ní ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́, pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n lo ìdánúṣe àti pé wọ́n ní ìgboyà ní ‘àsìkò tí ó rọgbọ àti ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.’2 Tím. 4:2.