Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW Ń ‘Fún Wa Lókun, Ó sì Ń Mára Tù Wá!’

Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW Ń ‘Fún Wa Lókun, Ó sì Ń Mára Tù Wá!’

ÀTÌGBÀ tí ètò tẹlifíṣọ̀n orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tá a mọ̀ sí Tẹlifíṣọ̀n JW ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2014 ló ti túbọ̀ ń fún àìmọye àwọn tó ń wò ó kárí ayé níṣìírí, ó sì ń tù wọ́n lára nípa tẹ̀mí. Ètò náà ti wà ní ohun tó lé ní àádọ́rùn-ún [90] èdè báyìí. Bí àpẹẹrẹ, a ti ń túmọ̀ ètò náà sí àwọn èdè bí Ewe, Ga àti Twi (bó ṣe wà nínú àwòrán tó wà lókè yìí), kí àwọn akéde tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́fà ààbọ̀ [130,000], tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Benin, Côte d’Ivoire, Gánà àti Tógò lè máa gbádùn rẹ̀. *

Ìyàwó alábòójútó àyíká kan lórílẹ̀-èdè Gánà, tó ń jẹ́ Agatha sọ pé, “Tí mo bá ti ń gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti àwọn tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé  Jèhófà ló ń bá mi sọ̀rọ̀ nínú yàrá mi. Tí kì í bá ṣe ti ètò olóṣooṣù yìí, báwo ni irú èmi ọmọdé lásán-làsàn yìí, tó jẹ́ pé kọ̀rọ̀ kan láyé ni mò ń gbé, ṣe lè ní irú àǹfààní ńlá bí èyí? Ètò náà ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n kárí ayé.”

Àwọn ará ní Sáńbíà fi ìròyìn yìí ránṣẹ́, wọ́n ní: “Ọ̀pọ̀ àwọn akéde nínú ìjọ ló ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí ọgbọ̀n [30] kìlómítà ni Ìjọ Misako wà sí ìlú tó sún mọ́ ọn jù, àgbègbè kan tí wọ́n ti ń dáko ni ìjọ náà wà, ọ̀gbàrá sì máa ń ṣàn gba ọ̀nà tí wọ́n máa ń fẹsẹ̀ rìn kọjá tó bá ti di àkókò òjò.” Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó ń jẹ́ Simon, tó wá sìn ní ìjọ náà torí àìní tó wà níbẹ̀, ṣàlàyé pé: “Oṣooṣù ni ẹnì kan nínú ìjọ náà máa ń fi nǹkan bíi wákàtí méjì rìn, kó tó dójú ọ̀nà gangan, ibẹ̀ lá ti wá wọ ọkọ̀ èrò lọ sí ìlú tí àwọn ará ti lè rí ètò náà wà jáde. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin [70] ọdún àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì kò wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, àmọ́ orí ọkùnrin náà wú nígbà tó gbọ́ pé wọ́n máa wo fídíò ní ìpàdé, ní abúlé tí wọ́n wà yẹn. Bàbá náà sọ pé, ‘Ọ̀nà téèyàn lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run nìyí.’”

Ẹnì kan kọ lẹ́tà ìmọrírì láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó ní: “Ó ti tó ọdún kan báyìí tá a ti ń wo Tẹlifíṣọ̀n JW, inú wa sì ń dùn pé a nírú àǹfààní yìí. Nígbà tá a wo ti oṣù àkọ́kọ́, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la ti rí i pé ìṣọ̀kan ni àwa àti ẹgbẹ́ ará kárí ayé wà! A gbádùn ẹ̀ dọ́ba! A rí i pé ọmọ ìyá ni gbogbo wa! Inú wa sì dùn láti rí àwọn arákùnrin wa ọ̀wọ́n tí wọ́n wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Tinútinú ni wọ́n fi ń pèsè oúnjẹ tó bọ́ sásìkò fún wa, gbogbo wa sì ń rí oúnjẹ náà jẹ lóòrèkóòrè. Ó máa ń ṣe wá bíi pé kí ètò toṣù tó tẹ̀ lé e ti jáde. Kódà, ṣe ni à ń yangàn pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ ṣeun gan-an, ẹ̀yin arákùnrin wa ọ̀wọ́n! A dúpẹ́ lọ́wọ́  Jèhófà àti Kristi fún gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu tí wọ́n ń ṣe. Ètò náà ń fún wa lókun, ó sì ń jẹ́ kára tù wá!”

Àgbàlagbà ni Horst àti Helga ìyàwó rẹ̀, ara wọn ò sì le. Orílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n ń gbé, wọ́n kọ̀wé pé: “Tẹlifíṣọ̀n JW ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó máa ń fún wa lókun, pàápàá tá a bá ń gbọ́ ìrírí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara. Àpẹẹrẹ wọn máa ń fún wa níṣìírí láti máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láìka ti ara wa tí kò le sí. Nígbà tá a rí arákùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì ti rọ, síbẹ̀ tó jẹ́ alàgbà, a rí i pé kálukú wa ló lè fún Jèhófà ní ohun tó ṣeyebíye. Tí a bá ti rí irú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere, ńṣe la máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, tá a sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó jọ̀ọ́, kó máa rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí wọn.”

Kodi láti orílẹ̀-èdè England sọ pé: “Ẹ ṣeun fún gbogbo àkókò tí ẹ̀ ń lò àti bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti máa gbé àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì jw.org jáde pẹ̀lú ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW àtàwọn fídíò Kọ́lá àti Tósìn. Ẹ ṣeun bí ẹ ṣe ń mú kí Bíbélì rọrùn lóye. Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi. Tí mo bá ti dàgbà díẹ̀ sí i, màá yọ̀ǹda ara mi láti máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba! Á sì tún wù mí láti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí báyìí, láìpẹ́ máa dàgbà tẹ́ni tó lè lọ sí Bẹ́tẹ́lì.”

Ọmọ ọdún mẹ́jọ míì tó ń jẹ́ Arabella lórílẹ̀-èdè England kọ̀wé pé: “Ẹ ṣeun àwọn fídíò àtàwọn eré tí ẹ̀ ń gbé jáde. Ó ti jẹ́ kí n mọ Jèhófà sí i. Àwọn eré aláwòrán tó wà lórí ìkànnì jw.org ti ràn mí lọ́wọ́, bí mo ṣe ń gbádùn àwọn eré náà ni mò ń kọ́ nípa Jèhófà. Ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe orin tí gbogbo èèyàn ò ní lè gbàgbé. Àwọn fídíò Kọ́lá àti Tósìn náà ti ràn mí lọ́wọ́. Ẹ ṣeun fún gbogbo iṣẹ́ takuntakun tí ẹ̀ ń ṣe.”

^ ìpínrọ̀ 3 Tó o bá fẹ́ wo Tẹlifíṣọ̀n JW, lọ sórí ìkànnì tv.jw.org/yo.