Bí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ṣe ń fojú ba ilé ẹjọ́, tí wọ́n sì ń kojú ìṣòro lóríṣiríṣi, wọ́n ń fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo wa, pé ká má ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa yẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé ‘Jèhófà yóò ṣìkẹ́ ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.’Sm. 4:3.

AJẸNTÍNÀ | Ẹ̀tọ́ Láti Kọ́ Àwọn Ọmọ ní Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn

Ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti tọ́ Ruth dàgbà, àmọ́ bó ṣe ń dàgbà, ó di aláìṣiṣẹ́mọ́. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ọkùnrin kan, ó lóyún fún un, kò sì pẹ́ tó fi bí ọmọbìnrin kan. Lọ́jọ́ kan, nílùú La Plata, Ruth rí i táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàtẹ ìwé sórí tábìlì, ó wá rántí ìsìn àárọ̀ rẹ̀. Èyí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, ó sì ń fi Bíbélì kọ́ ọmọ rẹ̀ kékeré. Àmọ́ bàbá ọmọ náà ò fọwọ́ sí ohun tí Rúùtù ń ṣe yìí, ló bá gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Ó ní òun ò fẹ́ kí Rúùtù máa kọ́ ọmọ àwọn ní Bíbélì, òun ò sì fẹ́ kó máa mú un lọ sípàdé mọ́.

Agbẹjọ́rò Ruth sọ pé àwọn òbí méjèèjì ló lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ́ ọmọ wọn ní ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti pé ilé ẹjọ́ ò lè fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n, àfi tí ẹ̀rí bá wà pé ohun tí wọ́n ń kọ́ ọmọ náà ti ń ní ipa burúkú lórí ẹ̀. Ilé ẹjọ́ wá sọ pé kí àwọn òbí méjèèjì má fi ẹ̀tọ́ tí ọmọ wọn ní dù ú, torí ó lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wù ú, bẹ́ẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́rin péré ni nígbà yẹn! Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wá jẹ́ kó ṣe kedere pé ọmọ náà ṣì kéré gan-an, kò tíì dàgbà tó láti pinnu ẹ̀sìn tó máa ṣe, síbẹ̀ àwọn òbí méjèèjì ló lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ́ ọmọ wọn ní ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.

Ọmọ Ruth kékeré yìí máa ń ka Bíbélì lálaalẹ́, ó sì ti ń bá mọ́mì ẹ̀ lọ sípàdé báyìí. Ara ẹ̀ ti wà lọ́nà láti lọ wo Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Buenos Aires.

AZERBAIJAN | Ẹ̀tọ́ Láti Ṣe Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé nínú ìjọ àwọn Kristẹni tòótọ́, “bí ẹ̀yà ara kan bá . . . ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.” (1 Kọ́r.  12:26) Bó ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ò dùn rárá sí ìyà tí àwọn aláṣẹ fi jẹ Arábìnrin Irina Zakharchenko àti Arábìnrin Valida Jabrayilova lórílẹ̀-èdè Azerbaijan. Ní February 2015, àwọn aláṣẹ fẹ̀sùn kan àwọn arábìnrin méjì yìí pé wọ́n ń ṣe ìsìn tí kò bófin mu. Adájọ́ wá fi wọ́n sí àtìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn, àmọ́ torí pé wọ́n ṣáà ń sún ẹjọ́ wọn síwájú, àwọn arábìnrin yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún kan látìmọ́lé, wọ́n fìyà jẹ wọ́n, wọ́n sì fi àwọn nǹkan kan dù wọ́n.

Azerbaijan: Valida Jabrayilova àti Irina Zakharchenko

Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, wọ́n gbọ́ ẹjọ́ wọn ní January 2016. Adájọ́ sọ pé àwọn arábìnrin náà jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, ó sì bu owó ìtanràn lé wọn. Àmọ́ torí pé wọ́n ti wà látìmọ́lé tẹ́lẹ̀, ó fagi lé owó ìtanràn náà, ó sì ní kí wọ́n máa lọ sílé. Àwọn obìnrin yìí wá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n yìí, àmọ́ Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn nílùú Baku fagi lé ẹjọ́ wọn, ni wọ́n bá kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ. Wọ́n tún kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lórí bí àwọn aláṣẹ ṣe fi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́ dù wọ́n àti bí wọ́n ṣe fìyà jẹ wọ́n.

Ní báyìí, ara àwọn arábìnrin yìí ti ń yá lẹ́yìn ìyà tí wọ́n fara gbá. Wọ́n sọ pé àwọn mọrírì àdúrà táwọn ará ń gbà láìdabọ̀ nítorí wọn àti bí wọ́n ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ wọ́n lógún. Arábìnrin Jabrayilova kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ó ní: “Mo mọ̀ ọ́n lára pé ẹ̀ ń gbàdúrà torí wa, ó jẹ́ ká lè fara da ìyà tó jẹ wá. Mi ò lè  gbàgbé ìfẹ́ tẹ́ ẹ fi hàn sí wa láé àti bẹ́ ẹ ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ wa jẹ yín lọ́kàn, mi ò sì lè gbàgbé ìfẹ́ tí Jèhófà àtàwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé fi hàn.”

ERITREA | Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Títí di July 2016, márùndínlọ́gọ́ta [55] ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea ti fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àwọn arákùnrin mẹ́ta kan, ìyẹn Paulos Eyassu, Isaac Mogos àti Negede Teklemariam, ti wà lẹ́wọ̀n láti September 1994, ìjọba sì ti fi àwọn arákùnrin mẹ́sàn-án míì sẹ́wọ̀n fún ọdún mẹ́wàá, ó kéré tán.

Àmọ́ ohun kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí ṣẹlẹ̀ ní January 2016. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú níbi Ìrántí Ikú Kristi nílùú Asmara ní April 2014 fojú ba ilé ẹjọ́. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àwọn aláṣẹ máa fi “ẹ̀sùn” kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n á sì jẹ́ kí wọ́n sọ tẹnu wọn. Kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó fojú ba ilé ẹjọ́ ni wọ́n dá lẹ́bi pé wọ́n ń ṣe ìpàdé “tí kò bófin mu”, wọ́n bu owó ìtanràn lé wọn, wọ́n sì dá wọn sílẹ̀. Àmọ́, Saron Gebru, tó wà lára àwọn arábìnrin tí wọ́n fẹ̀sùn kàn kọ̀ láti san owó ìtanràn náà. Ni wọ́n bá rán an lọ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà. Wọ́n gba Arábìnrin Gebru láyè láti gbàlejò lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n tó wà, ìròyìn tá a sì gbọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀ ni pé wọ́n ṣe òun dáadáa. Òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] tó wà lẹ́wọ̀n mọyì báwọn ará ò ṣe dákẹ́ àdúrà lórí wọn, bí gbogbo wa ṣe ń “fi àwọn tí ń bẹ nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n sọ́kàn bí ẹni pé a dè [wá] pẹ̀lú wọn.”Héb. 13:3.

JÁMÁNÌ | Òmìnira Ẹ̀sìn—Wọ́n Lẹ́tọ̀ọ́ sí I Lábẹ́ Òfin

Ní December 21, 2015, ìjọba ìpínlẹ̀ Bremen, ní àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Jámánì, jẹ́ kí ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lábẹ́ òfin ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ló fòpin sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti ń fà nílé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Jámánì fún ọdún mẹ́rin. Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga nílùú Berlin ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ yìí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógún [16] tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì ló fún  àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin tó wà fáwọn aráàlú. Àmọ́ àwọn aláṣẹ ní ìpínlẹ̀ Bremen ò gbà láti fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ yìí, olórí ohun tó sì fà á ni ẹ̀sùn èké táwọn alátakò ń tàn kálẹ̀.

Lọ́dún 2015, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba Orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé àwọn aláṣẹ ìpínlẹ̀ Bremen ti fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin dù wọ́n lórí ohun tí wọ́n ṣe yìí. Ilé ẹjọ́ fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn wọn ní Bremen torí pé òfin fọwọ́ sí i pé wọ́n lómìnira ẹ̀sìn. Wọ́n ní káwọn ìjọ tó wà níbẹ̀ má san owó orí, wọ́n sì tún sọ pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí àwọn àǹfààní míì táwọn ẹ̀sìn tó lórúkọ ń gbádùn lórílẹ̀-èdè Jámánì.

KYRGYZSTAN | Ẹ̀tọ́ Láti Ṣe Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Ní March 2013, àwọn aláṣẹ ìlú Osh, lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan fẹ̀sùn èké kan Oksana Koriakina àti ìyá rẹ̀, Nadezhda Sergienko. Wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń lu àwọn aládùúgbò wọn ní jìbìtì bí wọ́n ṣe ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì, adájọ́ wá ní wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ní October 2014, ilé ẹjọ́ rí i pé ṣe ni àwọn aláṣẹ lọ́ irọ́ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, wọ́n tún rí i pé wọn ò tẹ̀ lé ìlànà tó yẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí àti pé àwọn arábìnrin náà ò jẹ̀bi.. Nígbà tó di October 2015, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá wọn láre.

Àmọ́ agbẹjọ́rò ìjọba nílùú Osh tún kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kyrgyzstan. Ilé ẹjọ́ náà fagi lé ẹjọ́ tí wọ́n dá tẹ́lẹ̀ pé àwọn arábìnrin náà ò jẹ̀bi, wọ́n sì ní kí àwọn arábìnrin náà tún fojú ba ilé ẹjọ́. Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn ní April 2016, àwọn agbẹjọ́rò àwọn arábìnrin náà sọ pé kí ilé ẹjọ́ dá wọn sílẹ̀ torí pé lábẹ́ òfin, àkókò tó yẹ kí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ yìí ti kọjá. Kò sóhun tí adájọ́ náà lè ṣe ju pé kó fagi lé ẹjọ́ náà, bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe kúrò nílé ẹjọ́ nìyẹn.

Jálẹ̀ gbogbo ohun tójú àwọn arábìnrin yìí rí, wọn ò bọkàn jẹ́. Arábìnrin Sergienko sọ pé, “Ó sábà máa ń dun àwa èèyàn táwọn míì bá hùwà àìdáa sí wa, àmọ́ mo rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi, kò sì fọ̀rọ̀ wa ṣeré, torí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ò fi  wá sílẹ̀.” Àwọn arábìnrin náà fojú ara wọn rí i pé Jèhófà ò gbàgbé ìlérí tó ṣe nínú ìwé Aísáyà 41:10 pé: “Má fòyà . . . Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”

KYRGYZSTAN | Òmìnira Ẹ̀sìn—Wọ́n Lẹ́tọ̀ọ́ sí I Lábẹ́ Òfin

Ní August 9, 2015, ọlọ́pàá mẹ́wàá ya wọ ibì kan táwọn ará ti ń ṣèpàdé nílùú Osh, lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan. Wọ́n ní kí àwọn ará dá ìpàdé “tí kò bófin mu” tí wọ́n ń ṣe dúró lójú ẹsẹ̀, wọ́n tiẹ̀ tún halẹ̀ pé àwọn máa yìnbọn pa àwọn tó lé ní ogójì [40] tó wà níbẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá náà mú àwọn arákùnrin mẹ́wàá lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n lu mẹ́sàn-án nínú wọn nílùkulù, lẹ́yìn náà, wọ́n dá wọn sílẹ̀. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, àwọn ọlọ́pàá mú Nurlan Usupbaev, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tí wọ́n lù nílùkulù yẹn, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu torí pé òun ló ń darí ìpàdé lọ́jọ́ náà.

Nígbà tí ọ̀rọ̀ Arákùnrin Usupbaev dé Ilé Ẹjọ́ Ìlú Osh, adájọ́ ò rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, ló bá fagi lé ẹjọ́ náà. Ni àwọn tó fẹ̀sùn kàn án bá kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ìpínlẹ̀ tó wà nílùú Osh, àmọ́ ilé ẹjọ́ náà fagi lé ẹjọ́ tí wọ́n pè. Wọ́n fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Arákùnrin Usupbaev ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu, torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan.

Àwọn onítibí ò fi mọ síbẹ̀ o, wọ́n tún kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kyrgyzstan. Àmọ́ ṣe lara tu Arákùnrin Usupbaev nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fagi lé ẹjọ́ náà ní March 2016, wọ́n ní ẹjọ́ tó tọ́ ni ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ àti ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá, wọ́n tún fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìpàdé ẹ̀sìn wọn lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan. Ẹjọ́ míì ṣì wà nílé ẹjọ́, èyí tí àwọn èèyàn táwọn ọlọ́pàá ìlú Osh fìyà jẹ gbé wá.

RỌ́ṢÍÀ | Òmìnira Ẹ̀sìn

Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò yéé gbógun ti ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè náà  ń sọ pé àwọn ò fara mọ́ ọn. Méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] ni iye ìtẹ̀jáde wa tá a kà gbẹ̀yìn tí àwọn aláṣẹ ti fòfin dè pé wọ́n jẹ́ ti “agbawèrèmẹ́sìn,” wọ́n sì ti fòfin de ìkànnì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jw.org. Lọ́dún 2015, àwọn agbófinró tó ń rí sí ẹrù tó ń wọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wọ orílẹ̀-èdè náà, ilé ẹjọ́ kan nílùú Vyborg sì ń wò ó bóyá kí wọ́n fòfin de Bíbélì tuntun yìí pé ìwé àwọn “agbawèrèmẹ́sìn” ni. Ní March 2016, Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn pa, èyí tó wà ní àgbègbè Solnechnoye, lẹ́yìn ìlú St. Petersburg, wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé “iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn” ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ní káwọn èèyàn máa wọ́de, kí wọ́n sì máa ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ohun rere díẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ní October 2015, àwọn aláṣẹ kọ̀wé sí ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n fagi lé orúkọ ẹ̀sìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Tyumen, tó wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún kan [2,100] kìlómítà sí ìlà oòrùn ìlú Moscow. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí wà pé àwọn ọlọ́pàá lọ́ ẹ̀sùn irọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́sẹ̀, Ilé Ẹjọ́ Ìpínlẹ̀ nílùú Tyumen dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi. Àmọ́ ní April 15, 2016, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fagi lé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ yẹn dá, wọ́n sọ pé “kò sídìí láti fagi lé orúkọ ẹ̀sìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Tyumen.” Nígbà tí adájọ́ àgbà ka ìdájọ́ náà, ṣe ni àwọn ọgọ́ta [60] arákùnrin àti arábìnrin tó kún yàrá ìgbẹ́jọ́ náà dìde dúró, tí wọ́n sì ń pàtẹ́wọ́.

Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti pinnu pé àwọn á máa sìn ín láìka “ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí [wọn]” sí.Aísá. 54:17.

 RÙWÁŃDÀ | Ẹ̀tọ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Níléèwé Láìsí Ẹ̀tanú Ẹ̀sìn

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn aláṣẹ ti lé àwọn ọmọ iléèwé tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà kúrò níléèwé torí pé wọn kì í dá sí àwọn ayẹyẹ ìsìn tàbí àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń ṣe níléèwé wọn. Ìjọba fẹ́ wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ yìí, torí náà, ní December 14, 2015, wọ́n pàṣẹ pé kí ẹ̀tanú ẹ̀sìn dópin níléèwé. Wọ́n ní káwọn aláṣẹ iléèwé má fi ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀sìn táwọn ọmọ iléèwé ní dù wọ́n.

Ní June 9, 2016, àpilẹ̀kọ kan jáde ní abala Ìròyìn lórí ìkànnì jw.org, àkòrí ẹ̀ ni “Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà Gbé Ìgbésẹ̀ Láti Fòpin sí Ẹ̀tanú Ẹ̀sìn Níléèwé.” Ìkànnì kan tó ń gbé ìròyìn jáde táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní Rùwáńdà wá gbé àpilẹ̀kọ náà jáde lórí ìkànnì wọn. Kò pẹ́ tí iye àwọn tó lọ kàròyìn lórí ìkànnì náà fi ròkè, wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000], ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó sì ka àpilẹ̀kọ yìí ló kọ ọ̀rọ̀ tó dáa síbẹ̀ nípa ohun tí ìjọba ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà mọrírì àṣẹ tí ìjọba pa tó jẹ́ kó dá wọn lójú pé àwọn ọmọ wọn lè lọ kẹ́kọ̀ọ́ níléèwé láìsí ẹ̀tanú ẹ̀sìn.

Rùwáńdà: Wọ́n pa dà sí iléèwé

SOUTH KOREA | Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn—Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Ó ti lé ní ọgọ́ta [60] ọdún táwọn ọkùnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún [19] sí márùndínlógójì [35] tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè South Korea ti ń kojú ìṣòro lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ológun. Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ò gbà pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò wọṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe é, wọn ò sì ṣètò àfidípò fún iṣẹ́ ológun. Kódà, láwọn ìgbà míì, ìran àwọn èèyàn kan, látorí bàbá àgbà dórí ọmọ ọmọ, ló ti di dandan pé kí wọ́n lọ sẹ́wọ̀n tí wọ́n bá ti ní kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológun.

Ẹ̀ẹ̀mejì ni Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti sọ pé Òfin Iṣẹ́ Ológun bófin mu, àmọ́ àwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké àtàwọn ọkùnrin tí ìjọba ti fi òfin yìí jẹ níyà ti tún gbé ọ̀rọ̀ náà wá síwájú Ilé Ẹjọ́ Ìjọba. Nígbà tó yá, ìyẹn ní July 9, 2015, Ilé Ẹjọ́ náà gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò  jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun. Arákùnrin Min-hwan Kim, tó ti lo ọdún kan ààbọ̀ lẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó wọṣẹ́ ológun sọ pé: “Mo ti jìyà lẹ́wọ̀n, wọ́n sì ti dá mi sílẹ̀. Àmọ́ mo nírètí pé wọn ò ní fìyà jẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn míì tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Tí ìjọba bá lè jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ àṣesìnlú, wọ́n á lè ṣe ìlú láǹfààní.” Láìpẹ́, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba máa sọ ohun tí wọ́n pinnu lórí ọ̀rọ̀ yìí.

TURKMENISTAN | Bahram Hemdemov

Ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta [53] ni Arákùnrin Hemdemov, ó níyàwó, ó sì ní ọmọkùnrin mẹ́rin. Ó ń fìtara jọ́sìn Ọlọ́run, ẹni iyì sì ni láwùjọ. Ní May 2015, ilé ẹjọ́ kan rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára, torí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé wọ́n ń ṣe ìpàdé ẹ̀sìn “tí kò bófin mu” nínú ilé rẹ̀. Ó wà látìmọ́lé ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìlú Seydi tí wọ́n ti ń ṣẹ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n níṣẹ̀ẹ́. Ibi burúkú gbáà làwọn èèyàn mọ ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí sí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n da ìbéèrè bo Hemdemov níbẹ̀, táwọn aláṣẹ sì lù ú nílùkulù. Àmọ́, kò fi Jèhófà Ọlọ́run sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀. Gulzira, tó jẹ́ ìyàwó Arákùnrin Hemdemov, máa ń lọ wò ó lóòrèkóòrè kó lè fún un níṣìírí.

Bá a ṣe ń rí i táwọn èèyàn Jèhófà ń fi hàn pé adúróṣinṣin làwọn lójú àdánwò, à ń fi àdúrà tì wọ́n lẹ́yìn. Àpẹẹrẹ wọn tún ń mú káwa náà túbọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, bó ṣe dá wa lójú pé ìlérí tó ṣe nínú Sáàmù 37:28 máa ṣẹ, ó ní: “Òun kì yóò . . . fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.”