Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

“Ẹ̀yin Ni Aládùúgbò Tó Dáa Jù Lọ”

“Ẹ̀yin Ni Aládùúgbò Tó Dáa Jù Lọ”

NÍ May 7 àti 8, 2016, àwọn èèyàn ń kọ hàà níbi àbáwọlé oríléeṣẹ́ wa tó wà ní 25 Columbia Heights, Brooklyn, nílùú New York, wọn ò mọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé láwọn òpin ọ̀sẹ̀, a kì í fún àwọn èèyàn láyè láti wọbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fún wọn láyè láti wá wo àtẹ, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ṣe la dìídì pe àwọn tó ń gbé lágbègbè Bẹ́tẹ́lì wá, tá a sì ṣí ibẹ̀ sílẹ̀ fún wọn kí wọ́n lè wá wo ìpàtẹ Bíbélì.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ báwọn ará ṣe ké sí àwọn èèyàn lágbègbè náà, ó jẹ́ kí wọ́n lè wàásù fún wọn, inú àwọn ará tó wàásù yìí sì dùn gan-an. Ó wúni lórí gan-an láti gbọ́ àwọn ohun rere tí àwọn tá a ti jọ wà ládùúgbò tipẹ́tipẹ́ sọ.

 Ọkùnrin kan sọ pé, “Oríṣiríṣi ilé ni mo ti gbé káàkiri [àgbègbè Bẹ́tẹ́lì] láti ọdún mélòó kan ṣáájú ọdún 1970, ẹ̀yin sì ni aládùúgbò tí mo ní tó dáa jù lọ. Àárò yín máa sọ wá gan-an, kò wù wá kẹ́ ẹ kúrò níbí.”

Obìnrin kan sọ pé, “Àdúgbò yìí ì bá má dáa tó báyìí ká lẹ́ ò sí níbí. A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá pé ẹ jẹ́ aládùúgbò wa látọdún yìí wá.”

Inú ọ̀pọ̀ nínú àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó máa ń wàásù lágbègbè náà dùn bí àwọn tó wà ládùúgbò náà ṣe ń fìfẹ́ hàn, tí wọ́n sì ń tẹ́tí gbọ́rọ̀ wọn. Ọkùnrin jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kan tó wà nínú ẹgbẹ́ kan tí wọ́n dá sílẹ̀ ní àdúgbò náà sọ bó ṣe mọyì ètò wa tó, ó ní ó dun òun pé òun ò ní sí nílùú lọ́jọ́ tí a máa ṣí ọ́fíìsì wa sílẹ̀ pé káwọn èèyàn wá wo ibẹ̀.

Ohun tí iṣẹ́ tá a ṣe yìí mú jáde wúni lórí gan-an. Lẹ́nu ọjọ́ méjì yẹn, àwọn méjìdínláàádọ́ta [48] tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wá wo ìpàtẹ Bíbélì. Ní àkókò tí a ṣí ilé sílẹ̀ fáwọn èèyàn yìí, àwọn kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì wà níbi àbáwọlé kí wọ́n lè máa kí àwọn ará àdúgbò náà káàbọ̀, kí wọ́n sì bá wọn sọ̀rọ̀.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sally, tó ti ń sún mọ́ ọgbọ̀n [30] ọdún, lo nǹkan bíi wákàtí kan ààbò níbi àtẹ náà. Nígbà tó dé, ó bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó pè é wá síbẹ̀ níbi àbáwọlé náà. Sally ní òun ò mọ̀ pé ìpàtẹ Bíbélì wà. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà sọ fún un pé ó wú àwọn lórí gan-an láti bá ọ̀dọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀, tó sì mọyì Bíbélì bíi tiẹ̀ pàdé. Sally fèsì pé: “Ìwé tó ṣe pàtàkì gan-an ni Bíbélì. Òun nìkan ló lè jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run sọ. Ìwé tá a nílò nígbèésí ayé wa ni.”

Sally sọ pé ìfẹ́ tí òun ní fún Bíbélì ló sún òun láti kọ́ èdè Látìn àti Gíríìkì àti pé òun fẹ́ràn iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè  gan-an. Ó ní ó ṣe pàtàkì kí ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ péye, kó má bàa jẹ́ pé èrò orí àwọn kan ló máa wà nínú ẹ̀. Nígbà táwọn aṣáájú-ọ̀nà náà sọ fún Sally pé ìkànnì wa, ìyẹn jw.org ní ìsọfúnni nípa Bíbélì ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] lọ, ó yà á lẹ́nu gan-an, inú ẹ̀ sì dùn dọ́ba. Nígbà tí àwọn arábìnrin náà ṣàlàyé ohun tí àwọn atúmọ̀ èdè kan ti ṣe sí orúkọ Jèhófà, àyà rẹ̀ là gààrà, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí wọ́n fi yọ orúkọ Jèhófà kúrò nínú Bíbélì?” Bí Sally ṣe fẹ́ máa lọ, ó sọ pé, “Mi ò tíì gbé ládùúgbò míì àfi àdúgbò yìí, ẹ̀yin sì ni aládùúgbò tó dáa jù lọ.”

Lọ́jọ́ Monday tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí a ṣí ọ́fíìsì wa sílẹ̀, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan wá bá John tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì, níbi tó pàtẹ ìwé sí, nítòsí Bẹ́tẹ́lì. Ó sọ fún John bínú rẹ̀ ṣe dùn tó nígbà tó wá wo ọ́fíìsì wa lọ́jọ́ tá a ní kí wọ́n wá wò ó, ó tún sọ pé òun mọyì bá a ṣe máa ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ. Àmọ́, lẹ́yìn tó bá John sọ̀rọ̀ díẹ̀, ó ṣàdédé sọ pé, “Inú ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bí mi!” Ọ̀rọ̀ náà ò yé John, ló bá béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé kí nìdí. Àlùfáà náà sọ pé, “Torí pé ẹ̀ ń kó kúrò níbí ni! Ẹ DÚRÓ SÍBÍ! Ẹ lè ra àwọn ilé ńlá tàbí kẹ́ ẹ kọ́ ohun tẹ́ ẹ bá fẹ́ síbí, ẹ ṣáà máà kúrò níbí. Ẹ̀yin lẹ jẹ́ kí àdúgbò yìí tòrò. Inú ń bí mi gan-an pé ẹ̀ ń kó lọ sí àríwá!”

Gbogbo ẹ̀ gbògbò ẹ̀, bá a ṣe ké sáwọn èèyàn wá wo ọ́fíìsì wa àti bá a ṣe ṣí ibẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè wá wo ìpàtẹ Bíbélì ti jẹ́ káwọn tó wà lágbègbè náà gbọ́ ìwàásù, orúkọ Ọlọ́run sì ṣe kedere sáwọn aládùúgbò wa ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.