Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kòlóńbíà

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

A Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Kárí Ayé Láfiyèsí

A Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Kárí Ayé Láfiyèsí

NÍ Wednesday, September 23, 2015, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé nípa àwọn àyípadà tí wọ́n ti ṣe, kí wọ́n lè lo owó ètò Ọlọ́run lọ́nà tó dára jù lọ. Nígbà tó di Saturday, October 3, 2015, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣèfilọ̀ pé: “Fílípì 1:10 sọ fún wa pé kí a ‘máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.’ Torí náà, ká lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí dáadáa, àwa [Ìgbìmọ̀ Olùdarí] fẹ́ fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run jẹni tẹ̀mí láfiyèsí, táá sì jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ máa gbilẹ̀ sí i kárí ayé.”

Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún ṣàlàyé síwájú sí i lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, pé: “Ìgbìmọ̀  Olùdarí fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe túbọ̀ máa tàn kalẹ̀, débi pé a ti wá àwọn ọ̀nà tá a máa gbà dín àwọn nǹkan kan kù ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, ká lè túbọ̀ darí ọrẹ tó ń wọlé sórí iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ètò tó ti wà tipẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn iṣẹ́ míì la ti dín kù, tá a sì yọ àwọn kan kúrò pátápátá. Èyí máa já sí pé iye àwọn tó máa wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì kò ní tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”

Torí náà, láti September 2015, ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún [5,500] ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ló ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní pápá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àyípadà yìí ò rọrùn, à ń rọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń bù kún ètò yìí, àyípadà náà sì ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni túbọ̀ gbòòrò sí i.

Tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà tí wọ́n jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ tí wọ́n ti ní kí wọ́n máa lọ sí pápá rí i pé àǹfààní ló jẹ́ fún àwọn láti fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, àwọn sì fọkàn tán ètò rẹ̀. Wọ́n kọ̀wé pé: “A ò mọ ohun tó wà níwájú. Àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀. A wá gbàdúrà pé, ‘Jèhófà jọ̀ọ́, ohunkóhun tá a bá máa dojú kọ, ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣètò ara wa, káwa méjèèjì lè máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé.’ Lóṣù àkọ́kọ́, a ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan nílé. Síbẹ̀, a rọ́wọ́ Jèhófà láyé wa, ó tọ́jú wa gan-an. Ní báyìí, owó tá a máa fi gbọ́ bùkátà ń wọlé fún wa déédéé. Ọwọ́ wa dí gan-an torí a máa ṣiṣẹ́ ilé, a máa lọ síbi iṣẹ́, a sì máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ ẹ̀kọ́ tá a ti gbà ní Bẹ́tẹ́lì ti jẹ́ ká lè ṣètò àkókò wa dáadáa. Kò sóhun tó ń múnú ẹni dùn tó pé ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, inú wa sì ń dùn pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀ bá a ṣe jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.”

 Lára àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà tí wọ́n rán lọ sí pápá ti kọ́ èdè tuntun, wọ́n sì lọ sáwọn àgbègbè tó jìnnà kí wọ́n lè lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn tó ń gbé ní àdádó. Ìbùkún ni àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí tún jẹ́ fún ìjọ wọn tuntun. Alábòójútó àyíká kan kọ̀wé nípa tọkọtaya kan tí wọ́n yàn sí ìjọ kan ní àyíká tó wà, pé: “Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ náà mọyì ìrànlọ́wọ́ wọn gan-an. Àwọn ará ìjọ náà ti túbọ̀ ń jáde òde ìwàásù, àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ sì ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n á ṣe máa bójú tó oríṣiríṣi iṣẹ́ nínú ìjọ́.” Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti fìgbà kan wà ní Bẹ́tẹ́lì ló ti ṣètò ara wọn kí wọ́n lè máa ti ilé wá sí Bẹ́tẹ́lì láti ṣiṣẹ́ fọ́jọ́ kan lọ́sẹ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Wọ́n ní kí arákùnrin kan tó ti lo ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] ní Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Japan máa lọ sí ìjọ kan tí kò ní ju alàgbà méjì. Torí pé ètò ti wà pé kí ìjọ náà tún àwọn ibì kan kọ́ lára Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń lò, arákùnrin náà pinnu pé òun ò ní lọ ṣiṣẹ́ owó kankan fún ọ̀sẹ̀ méjì. Àmọ́ kí àtúnṣe náà tó bẹ̀rẹ̀, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára wáyé ní àgbègbè Kumamoto, níbi tí ìjọ rẹ̀ wà. Torí pé kò tíì wá iṣẹ́ owó tó máa ṣe, ìyẹn mú kó ṣeé ṣe fún un láti mú ipò iwájú lẹ́nu ṣíṣètò ìrànwọ́ lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé yẹn àti ṣíṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Arákùnrin yìí sọ pé, “Nígbà tí mo ronú sẹ́yìn, mo lè sọ pé ṣe ni Jèhófà fi mí sí ọ̀kan lára ibi tí àìní pọ̀ sí jù lọ.”

Phil àti Sugar tí wọ́n sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílẹ̀ Australasia ṣàlàyé pé: “Nígbà tí ètò Ọlọ́run ní ká pa dà sí ìjọ wa, a pinnu pé ayé se-bí-o-ti-mo làá máa gbé. A  gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kó sì bù kún ìpinnu èyíkéyìí tá a bá ṣe. Gbogbo ohun tá a fẹ́ ò ju pé ká lọ sí ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè míì, ká lè yọ̀ǹda ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run níbẹ̀. Jèhófà bù kún àwọn ìpinnu tá a ṣe, ó sì ṣọ̀nà wa níre ká bàa lè sìn ín tọkàntọkàn!” Àwùjọ kan tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní erékùṣù Samal, nílùú Davao, lórílẹ̀-èdè Philippines ni wọ́n ti ń sìn báyìí, akéde mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] àti aṣáájú-ọ̀nà mẹ́sàn-án ló sì wà níbẹ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́, nǹkan bí ọgọ́fà [120] àwọn tó ti ń wá sípàdé ni Phil àti Sugar ní àdírẹ́sì wọn, tí wọ́n sì fẹ́ ràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lọ. Wọ́n sọ pé, “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó ń gbádùn mọ́ni ló wà nílẹ̀ láti ṣe. Inú wa dùn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Èyí ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí a ní fún un túbọ̀ lágbára!”

Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tí kò tíì lọ́kọ, tí wọ́n fún níṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ti jẹ́ kí n láǹfààní láti fi gbogbo àkókò mi ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, iṣẹ́ tá ò ní pa dà ṣe mọ́, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Inú mi máa ń dùn gan-an pé Jèhófà ń lò mí.” Ní báyìí, àwọn mẹ́fà ló ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn kan lára àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ wá láti orílẹ̀-èdè Ìráàkì, Nàìjíríà, Siri Láńkà, Síríà àti Sáńbíà.

Sáńbíà: Àwọn ará ń fayọ̀ kí àwọn tó ti wà ní Bẹ́tẹ́lì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí ìjọ wọn

Ọ̀pọ̀ nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Sáńbíà ni wọ́n ti ní kí wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fi àkókò tó pọ̀ wàásù. Arákùnrin Andrew tí òun àti ìyàwó ẹ̀ jọ jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ pé, “Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tá a kúrò ní Bẹ́tẹ́lì tá a fi ran àwọn méjì tí kò mọ̀wé kà lọ́wọ́, ní báyìí, wọ́n ti mọ̀ ọ́n kọ, wọ́n ti mọ̀ ọ́n kà. Ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, lára àwọn tá à ń kọ́  lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò ní pẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Tọkọtaya kan tá a wàásù fún wá sí Ìrántí Ikú Kristi, wọn ò sì pa ìpàdé jẹ látìgbà yẹn. Wọ́n ń tẹ̀ síwájú gan-an nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́. A mọ̀ pé gbogbo èyí ò lè ṣeé ṣe ká lá ò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, tá ò rí bó ṣe ń tì wá lẹ́yìn, tá ò sì dúró de ìbùkún rẹ̀.”

Orílẹ̀-èdè Sáńbíà náà ni Edson àti Artness ń gbé, kò tíì ju oṣù mélòó kan lọ tí wọ́n ṣègbéyàwó tí wọ́n fi ní kí wọ́n máa lọ sí pápá. Artness sọ pé: “Ẹ̀kọ́ tá a gbà ní Bẹ́tẹ́lì ti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fọgbọ́n lo ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tá a ní, kínú wa máa dùn, ká má sì ní gbèsè lọ́rùn. A ò kábàámọ̀ pé a lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. A ti kọ́ bá a ṣe lè ṣètò àwọn àfojúsùn wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kọ́wọ́ wa sì tẹ̀ ẹ́ lọ́lá Jèhófà. Ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà ti dọ̀tun, a sì ti pinnu pé àá máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.”