BÍ AYÉ Sátánì ṣe ń ko àjálù kan lórí òmíràn ni àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn Jèhófà ń “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń fi hàn pé a ‘gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, à ń ṣe rere, a sì ń fi ìṣòtítọ́ báni lò.’ (Sm. 37:3) Àwọn ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

A Gbé Oríléeṣẹ́ àti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Lọ Síbòmíì

Ọjọ́ kìíní oṣù February ọdún 2016 ni iṣẹ́ parí ní ọ́fíìsì ìlú Wallkill ní New York tí a mú gbòòrò sí i. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn àtàwọn ẹ̀ka míì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti kó lọ síbẹ̀. Bí iṣẹ́ ṣe ń parí lọ lórí oríléeṣẹ́ wa tuntun tó wà nílùú Warwick, bẹ́ẹ̀ ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ṣe ń fara rọ́ iṣẹ́ kíkó kúrò nílùú New York lọ sí ìgbèríko.

 Àǹfààní máa ṣí sílẹ̀ láti ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa ní Warwick bẹ̀rẹ̀ láti Monday, April 3, 2017. Àtẹ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà tí àwọn tó bá wá máa rí láìsí pé ẹnì kan ń ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn, lẹ́yìn náà, ẹnì kan á mú wọn rìn yí ká ọgbà.

  1. “Bíbélì àti Orúkọ Àtọ̀runwá Náà,” àwọn Bíbélì tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ló wà níbi àtẹ yìí, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì.

  2. “Àwọn Èèyàn Kan fún Orúkọ Jèhófà,” àtẹ yìí ní àwòrán ìtàn àwọn ohun tẹ̀mí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jogún, ó sì fi bí Jèhófà ṣe ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé hàn, tó ń kọ́ wọn, tó sì ń ṣètò wọn kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

  3. “Ìgbàgbọ́ ní Oríléeṣẹ́,” àtẹ yìí ń ṣàlàyé iṣẹ́ àwọn ìgbìmọ̀ kéékèèké tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò, ìyẹn ohun tí wọ́n ṣe kí àwọn èèyàn Jèhófà lè máa pàdé pọ̀, kí wọ́n lè máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n lè máa róúnjẹ tẹ̀mí jẹ, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn.

Láti ọjọ́ Monday sí Friday, ní aago mẹ́jọ àárọ̀ sí mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ni àyè máa ṣí sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti rìn yí ká àtẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí fúnra wọn. Àwọn tó wá ṣèbẹ̀wò tún máa gbádùn ogún [20] ìṣẹ́jú míì tí ẹnì kan máa mú wọn rìn kiri, tí á sì fi àwọn ibì kan hàn wọ́n ní àwọn ọ́fíìsì àtàwọn ibòmíì táwọn ará ti ń ṣiṣẹ́, títí kan àyíká Bẹ́tẹ́lì. Ètò tí a ṣe pé kí ẹnì kan máa mú àwọn èèyàn rìn yí ká yìí máa wà láti Monday sí Friday, ní aago mẹ́jọ àárọ̀ sí mọ́kànlá àárọ̀ àti aago kan ọ̀sán sí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.

Kó o tó ṣètò láti wá, jọ̀ọ́ lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wo abẹ́ NÍPA WA > Ọ́FÍÌSÌ ÀTI RÍRÍN YÍ KÁ ỌGBÀ > Amẹ́ríkà.