Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?

Ṣé ayé yìí máa . . .

  • wà bó ṣe wà?

  • àbí ó máa burú sí i?

  • àbí ó máa dáa?

 OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ọlọ́run . . . yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ YẸN LÈ ṢE FÚN Ẹ́

Wàá ní iṣẹ́ gidi tó máa tẹ́ ọ lọ́rùn.—Aísáyà 65:21-23.

Kò ní sí àìsàn àti ìyà kankan mọ́.—Aísáyà 25:8; 33:24.

Inú rẹ á máa dùn, wàá sì lè wà láàyè títí láé pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ.—Sáàmù 37:11, 29.

 ǸJẸ́ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni Bíbélì pè ní “Olódùmarè” torí pé agbára rẹ̀ kò láàlà. (Ìṣípayá 15:3) Torí náà, ó lágbára láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa bá wa tún ayé ṣe. Bíbélì sọ pé, “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mátíù 19:26.

  • Ọlọ́run fẹ́ mú ìlérí rẹ̀ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ‘ní ìfẹ́’ láti jí àwọn tó ti kú dìde.—Jóòbù 14:14, 15, Bíbélì Mímọ́.

Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, wo àwọn aláìsàn sàn. Kí nìdí tó fi wò wọ́n sàn? Ìdí ni pé ó wù ú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Máàkù 1:40, 41) Bí Jésù ṣe ń fẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ńṣe ló ń gbé gbogbo ìwà baba rẹ̀ yọ.—Jòhánù 14:9.

Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà àti Jésù fẹ́ ká ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀.—Sáàmù 72:12-14; 145:16; 2 Pétérù 3:9.

 RÒ Ó WÒ NÁ

Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ tún ayé yìí ṣe?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé MÁTÍÙ 6:9, 10 àti DÁNÍẸ́LÌ 2:44.