Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?

Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni.

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́.

  • Kò dá mi lójú.

 OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Àjíǹde . . . yóò wà.”—Ìṣe 24:15, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ YẸN LÈ ṢE FÚN Ẹ

Ó máa tù ẹ́ nínú tí èèyàn rẹ bá ṣaláìsí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Kò ní jẹ́ kó o máa bẹ̀rù ikú.—Hébérù 2:15.

Wàá ní ìrètí tó dájú pé o máa pa dà rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú.—Jòhánù 5:28, 29.

 ǸJẸ́ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Mẹ́ta lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo. Bíbélì pe Jèhófà Ọlọ́run ní “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9; Ìṣe 17:24, 25) Ó dájú pé ẹni tó lágbára láti dá ohun gbogbo máa lágbára láti jí òkú dìde.

  • Ọlọ́run ti jí òkú dìde nígbà kan rí. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn mẹ́jọ tí Ọlọ́run jí dìde, ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbà sì wà lára wọn. Kò pẹ́ púpọ̀ tí àwọn kan lára wọn kú tí wọ́n fi jíǹde, àmọ́ ọ̀kan wà lára wọn tó jẹ́ pé ó ti tó odindi ọjọ́ mẹ́rin tó ti wà nínú ibojì!—Jòhánù 11:39-44.

  • Ọlọ́run tún fẹ́ jí àwọn òkú dìde. Jèhófà kórìíra ikú, ó kà á sí ọ̀tá wa. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ó fẹ́ ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa pátápátá, torí náà ó máa jí àwọn òkú dìde. Ó ń wù ú gan-an láti jí gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ dìde, ó sì fẹ́ kí wọ́n tún wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé.—Jóòbù 14:14, 15.

 RÒ Ó WÒ NÁ

Kí nìdí tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé JẸ́NẸ́SÍSÌ 3:17-19 àti RÓÒMÙ 5:12.

(Kọ èdè tó o fẹ́.)