Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?

Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni.

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́.

  • Kò dá mi lójú.

 OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ọlọ́run . . . yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4, Bíbélì Mímọ́.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ YẸN LÈ ṢE FÚN Ẹ

Á jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro wa.—Jákọ́bù 1:13.

Ọkàn rẹ á balẹ̀ pé Ọlọ́run mọ bí ìyà ṣe ń rí lára wa.—Sekaráyà 2:8.

Wàá ní ìrètí pé gbogbo ìyà máa dópin.—Sáàmù 37:9-11.

 ǸJẸ́ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa jìyà tàbí kí wọ́n rẹ́ wa jẹ. Ronú nípa bó ṣe rí lára Jèhófà Ọlọ́run nígbà táwọn kan fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Bíbélì sọ pé inú Jèhófà kò dùn rárá nítorí àwọn ‘tó ń ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára.’—Àwọn Onídàájọ́ 2:18, Bíbélì Mímọ́.

    Ọlọ́run kórìíra àwọn tó ń ṣe ìkà sí ọmọnìkejì wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà kórìíra “ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀.”—Òwe 6:16, 17.

  • Ọlọ́run ń bójú tó ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Yàtọ̀ sí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ ‘ìpọ́njú tí òun ní àti ìbànújẹ́ tó wà lọ́kàn òun,’ Jèhófà pẹ̀lú mọ ohun tó ń bá kálukú wa fínra.—2 Kíróníkà 6:29, 30.

    Jèhófà máa tipasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Mátíù 6:9, 10) Àmọ́ ní báyìí ná, Jèhófà ń tu gbogbo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá a nínú.—Ìṣe 17:27; 2 Kọ́ríǹtì 1:3, 4.

 RÒ Ó WÒ NÁ

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé RÓÒMÙ 5:12 àti 2 PÉTÉRÙ 3:9.