Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?

Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?

Ṣé o rò pé . . .

  • ìfẹ́ ni?

  • àbí owó?

  • àbí nǹkan míì?

 OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:28, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ YẸN LÈ ṢE FÚN Ẹ

Wàá rí ìfẹ́ tòótọ́.—Éfésù 5:28, 29.

Wàá gbádùn ojúlówó ìtẹríba.—Éfésù 5:33.

Wàá ní ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀.—Máàkù 10:6-9.

 ǸJẸ́ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run ló dá ìdílé sílẹ̀. Bíbélì sọ pé “olúkúlùkù ìdílé . . . gba orúkọ rẹ̀” látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. (Éfésù 3:14, 15) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa?

    Rò ó wò ná: Tó o bá ń jẹ oúnjẹ àjẹpọ́nulá, tó o sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n fi sè é, ọwọ́ ta ló yẹ kó o ti béèrè? Ṣebí ọwọ́ ẹni tó sè é ni?

    Bákan náà, tá a bá fẹ́ mọ àwọn ohun tó máa mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé, ọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ ká yíjú sí, torí pé òun ni ó dá ìdílé sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24.

  • Ọlọ́run bìkítà nípa wa. Àwọn ìdílé tó bá jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tí Jèhófà ń fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. ‘Nítorí Jèhófà bìkítà fún wa.’ (1 Pétérù 5:6, 7) Ohun tó dára ni Jèhófà ń fẹ́ fún ọ, àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sì máa ń wúlò nígbà gbogbo!—Òwe 3:5, 6; Aísáyà 48:17, 18.

 RÒ Ó WÒ NÁ

Báwo lo lè ṣe lè jẹ́ ọkọ rere tàbí aya rere tàbí òbí rere?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé ÉFÉSÙ 5:1, 2 àti KÓLÓSÈ 3:18-21.