WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Jèhófà Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ló dára jù lọ. Ohun tó ní lọ́kàn fún ayé yìí àti aráyé máa ṣẹ.

Lẹ́yìn 4026 Ṣ.S.K.

Ohun tí “ejò náà” ń sọ ni pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso kò dára. Jèhófà ṣèlérí pé òun á gbé “ọmọ,” tàbí “irú ọmọ” kan dìde tó máa tẹ ejò náà, ìyẹn Sátánì, rẹ́ níkẹyìn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5, 15) Àmọ́, Jèhófà fàyè gba àwọn èèyàn láti máa ṣàkóso ara wọn bí ejò náà ṣé ń darí wọn.

1943 Ṣ.S.K.

Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé “ọmọ” tí òun ṣèlérí náà yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

Lẹ́yìn 1070 Ṣ.S.K.

Jèhófà mú un dá Dáfídì Ọba àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ lójú pé “ọmọ” tóun ṣèlérí náà yóò wá látinú ìlà ìdílé wọn.—2 Sámúẹ́lì 7:12, 16; 1 Ọba 9:3-5; Aísáyà 9:6, 7.

29 S.K.

Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni “ọmọ” tóun ṣèlérí tó jẹ́ Ajogún ìtẹ́ Dáfídì.—Gálátíà 3:16; Lúùkù 1:31-33; 3:21, 22.

 33 S.K.

Ejò náà, ìyẹn Sátánì dí “ọmọ” ìlérí náà lọ́wọ́ nígbà tó pa Jésù. Jèhófà gbé Jésù dìde sí ìyè ti ọ̀run, ó sì tẹ́wọ́ gba ìtóye ìwàláàyè pípé tí Jésù fi rúbọ, ó tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà kí Ọlọ́run sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìṣe 2:32-36; 1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.

Nǹkan bíi 1914 S.K.

Jésù fi ejò náà, Sátánì sọ̀kò sí ayé, á sì sé e mọ́bẹ̀ fún àkókò kúkúrú.—Ìṣípayá 12:7-9, 12.

Ọjọ́ Iwájú

Ẹgbẹ̀rún ọdún ni Jésù á fi ti Sátánì mọ́ ẹ̀wọ̀n, lẹ́yìn náà yóò pa á run, tó túmọ̀ sí pé á fọ́ ọ lórí. Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún ayé yìí àti aráyé máa ṣẹ, yóò sì mú gbogbo ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀, yóò sì dá ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso láre.—Ìṣípayá 20:1-3, 10; 21:3, 4.