Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 4-A

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Bí ìtàn inú Ìwé Ìhìn Rere Mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Ṣe Ṣẹlẹ̀ Tẹ̀ Léra

Àwọn àtẹ ìsọfúnni tó wà níbí yìí ní àwọn àwòrán ilẹ̀ tá a ti lè rí àwọn ibi tí Jésù lọ àtàwọn ibi tó ti wàásù. Àwọn àmì ẹlẹ́nu ṣóńṣó tó wà nínú àwọn àwòrán ilẹ̀ náà ò tọ́ka sí ibi tí Jésù gba gangan, ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ ń sọ ibi téèyàn lè rìn gbà. Àmì “n.” túmọ̀ sí “nǹkan bíi.”

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀

ÀKÓKÒ

IBI

ÌṢẸ̀LẸ̀

MÁTÍÙ

MÁÀKÙ

LÚÙKÙ

JÒHÁNÙ

3 Ṣ.S.K.

Jerúsálẹ́mù, tẹ́ńpìlì

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìbí Jòhánù Oníbatisí fún Sekaráyà

   

1:5-25

 

n. 2 Ṣ.S.K.

Násáretì; Jùdíà

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìbí Jésù fún Màríà; ó lọ wo mọ̀lẹ́bí rẹ̀, Èlísábẹ́tì

   

1:26-56

 

2 Ṣ.S.K.

Jùdíà Ìgbèríko olókè nílẹ̀

Wọ́n bí Jòhánù Oníbatisí, wọn sì sọ ọ́ lórúkọ; Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀; Jòhánù máa lọ sí aginjù

   

1:57-80

 

2 Ṣ.S.K., n. Oct. 1

Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

Wọ́n bí Jésù; “Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara”

1:1-25

 

2:1-7

1:1-5, 9-14

Nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù; Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

Áńgẹ́lì kéde ìhìn rere fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn; àwọn áńgẹ́lì yin Ọlọ́run; àwọn olùṣọ́ àgùntàn lọ wo ọmọ jòjòló náà

   

2:8-20

 

Bẹ́tílẹ́hẹ́mù; Jerúsálẹ́mù

Jésù dádọ̀dọ́ (ní ọjọ́ kẹjọ); àwọn òbí rẹ̀ gbé e lọ sí tẹ́ńpìlì (lẹ́yìn ogójì ọjọ́)

   

2:21-38

 

1 Ṣ.S.K. tàbí 1 S.K.

Jerúsálẹ́mù; Bẹ́tílẹ́hẹ́mù; Íjíbítì; Násárétì

Àwọn awòràwọ̀ ṣèbẹ̀wò; ìdílé sá lọ sí Íjíbítì; Hẹ́rọ́dù pa àwọn ọmọdékùnrin; ìdílé pa dà láti Íjíbítì wọ́n fìdí kalẹ̀ sí Násárétì

2:1-23

 

2:39, 40

 

12 S.K., Ìrékọjá

Jerúsálẹ́mù

Jésù ọmọ ọdún méjìlá wà ní tẹ́ńpìlì ó ń bi àwọn olùkọ́ ní ìbéèrè

   

2:41-50

 
 

Násárétì

Ó pa dà sí Násárétì; ó ń fi ara rẹ̀ sábẹ́ àwọn òbí rẹ̀; ó kọ́ iṣẹ́ káfíńtà; Màríà ní ọmọkùnrin mẹ́rin míì, ó tún ní àwọn ọmọbìnrin (Mt 13:55, 56; Mk 6:3)

   

2:51, 52

 

29, ìgbà ìwọ́wé

Aginjù, Odò Jọ́dánì

Jòhánù Oníbatisí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ 3:1-12

3:1-12

1:1-8

3:1-18

1:6-8, 15-28