Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àfikún Ìsọfúnni Láti Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

A4

Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù

Báwo ni àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan ṣe tú orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú èdè Hébérù? Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu bí wọ́n ṣe lo orúkọ náà, “Jèhófà”? Kí ni orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sì?

A6-A

Àtẹ: Àwọn Wòlíì àti Àwọn Ọba ní Ilẹ̀ Júdà àti Ísírẹ́lì (Apá 1)

Wo àtẹ àwọn ọjọ́ àti ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn Bíbélì láti ọdún 997 Ṣ.S.K. títí dé ọdún 800 Ṣ.S.K.

A6-B

Àtẹ: Àwọn Wòlíì àti Àwọn Ọba ní Ilẹ̀ Júdà àti Ísírẹ́lì (Apá 2)

Wo àtẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn Bíbélì láti ọdún 800 Ṣ.S.K. Títí dé ọdún 607 Ṣ.S.K.

A7-A

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀

Wo àtẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn Bíbélì láti ọdún 3 Ṣ.S.K. títí dé ìgbà ìwọ́wé ọdún 29 S.K.

A7-B

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Ìgbà Tí Jésù Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀

Wo àkókò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ àti àwòrán ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìwọ́wé ní ọdún 29 S.K. títí dé ìgbà Ìrékọjá ní ọdún 30 S.K.

A7-C

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Títayọ Tí Jésù Ṣe ní Gálílì (Apá 1)

Wo àkókò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ àti àwòrán ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 30 S.K. títí dé ìgbà Ìrékọjá ọdún 31 S.K.

A7-D

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Títayọ Tí Jésù Ṣe ní Gálílì (Apá 2)

Wo àkókò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ àti àwòrán ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 31 S.K. títí dé ìparí àjọyọ̀ Ìrékọjá ní ọdún 32 S.K.

A7-E

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Títayọ tí Jésù Ṣe ní Gálílì (Apá 3) àti ní Jùdíà

Wo àkókò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 32 S.K. láàárín Àjọyọ̀ Ìrékọjá àti Ìyàsímímọ́.

A7-F

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Pa Dà Lọ Ṣe ní Ìlà Oòrùn Jọ́dánì

Wo àkókò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ àti àwòrán ilẹ̀ láti ọdún 32 S.K. lẹ́yìn Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́.

A7-G

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù (Apá 1)

Wo àkókò àti àwòrán ilẹ̀ tó wà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, bẹ̀rẹ̀ láti Nísàn 8 títí dé Nísàn 14, ọdún 33 S.K.

A7-H

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù (Apá 2)

Wo àkókò àti àwòrán ilẹ̀ tó wà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, bẹ̀rẹ̀ láti Nísàn 8 títí dé Ííyà 25, ọdún 33 S.K.

B1

Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Ohun tó wà nínú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ láti inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó fi parí sí Ìṣípayá kò ta ko ara wọn, ó sì rọrùn láti lóye. Kí ló wà nínú Bíbélì?

B2

Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ìrìn Àjò Àwọn Baba Ńlá

Àwòrán àwọn ilẹ̀ tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì.

B3

Wọ́n Jáde Kúrò ní Íjíbítì

Mọ àwọn ọ̀nà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí.

B4

Wọ́n Gba Ilẹ̀ Ìlérí

Wo àwòrán ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọ́n ọmọ ogun Ísírẹ́lì bá jà.

B5

Àgọ́ Ìjọsìn àti Àlùfáà Àgbà

Wo bí àgọ́ ìjọsìn àti bí aṣọ àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì ṣe máa ń rí.

B6

Ibi Tí Wọ́n Tẹ̀dó Sí ní Ilẹ̀ Ìlérí

Wo àwòrán ilẹ̀ tó ń fi ìlú tí wọ́n pín fún èyà kọ̀ọ̀kàn ní Ísírẹ́lì hàn àti àwọn agbègbè tí àwọn onídàájọ́ ń ṣàkoso lè lórí, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà Ótíníẹ́lì títí dé orí Sámúsìnì.

B7

Ìjọba Dáfídì àti ti Sólómọ́nì

Wo àwòrán ilẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tí agbára rẹ̀ fi kàmàmà.

B8

Tẹ́ńpìlì Tí Sólómọ́nì Kọ́

Wo àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́rìnlá tó wà nínú Tẹ́ńpìlì náà.

B9

Àwọn Agbára Ayé tí Dáníẹ́lì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Wọn

Wo ère arabaríbí tí Dáníẹ́lì lá àlá nípa rẹ̀ ní Dáníẹ́lì orí 2 àti bí àlá náà ṣe ṣẹ.

B10

Ilẹ̀ Ísírẹ́lì Nígbà Tí Jésù Wà Láyé

Wo agbègbè àwọn ará Róòmù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti àyíká rẹ̀.

B11

Tẹ́ńpìlì ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní

Wo àwọn apá pàtàkì nínú tẹ́ńpìlì náà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nígbà ayé Jésù.

B12-A

Ọ̀sẹ̀ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Kó Tó Kú (Apá 1)

Wo àwòrán ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù àti àwọn agbègbè tó yí i ká, kó o sì tún wo àtẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní Nísàn 8 títí di Nísàn 11, ọdún 33 S.K.

B12-B

Ọ̀sẹ̀ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Kó Tó Kú (Apá 2)

Wo àtẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ láti Nísàn 12 sí Nísàn 16, ọdún 33 S.K.

B13

Bí Ẹ̀sìn Kristẹni Ṣe Gbilẹ̀

Wo àwòrán ilẹ̀ láti rí bí Pọ́ọ̀lù ṣe rírìn àjò rẹ̀ nígbà tó ń wàásù ìhìn rere, wàá sì rí àwọn ilú tí ìwé Ìṣípayá mẹ́nu kàn.

B14-A

Òwò Ṣíṣe àti Ọrọ̀ Ajé

Wo àwòrán táá jẹ́ kó o rí bí òṣùwọ̀n nǹkan olómi àti nǹkan gbígbẹ, ìdíwọ̀n nǹkan gbọọrọ tí Bíbélì mẹ́nu kan ṣe rí.

B14-B

Owó àti Ìdíwọ̀n

Wo àwòrán táá jẹ́ kó o rí bí àwọn ẹyọ owó àti ìdíwọ́n tí Bíbélì mẹ́nu kàn ṣe rí.

B15

Kàlẹ́ńdà Àwọn Hébérù

Fi kàlẹ́ńdà òṣùpá inú Bíbélì wé kàlẹ́ńdà òde òní, kó o sì mọ ìgbà tí àwọn ìgbòkègbodò ọdọọdún kan máa ń wáyé.