Wọ́n bẹ́ jáde gìjà, wọ́n ń ṣe kútúpà-kútúpà! Téèyàn bá ń ka ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ẹṣin ńláǹlà náa àtàwọn tó gùn wọ́n, ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn ń wò wọ́n lójúkojú! Ẹṣin funfun ló kọ́kọ́ jáde, ọba ògo tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́ ló gùn-ún. Ẹṣin aláwọ̀ iná ló tẹ̀ lé e, ẹni tó gùn-ún sì mú àlàáfíà kúrò nínú ayé. Ẹṣin dúdú ló jáde tẹ̀ lé e, ẹni tó gùn-ún mú òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì dání, ẹnì kan sì ń kéde pé àìtó oúnjẹ máa wà. Ẹṣin ràndánràndán tó dà bí èyí tó ní àrùn ni ẹsin kẹrin, Ikú fúnra rẹ̀ ló gùn-ún, èyí sì jẹ́ àmì àìsàn àtàwọn nǹkan míì tó ń ṣekú pani. Sàárè, ìyẹn isà òkú sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí, ó sì ń ṣekú pa omilẹgbẹ èèyàn!Ìṣípayá 6:1-8.

“Ẹ̀rù bà mí gan-an nígbà tí mo kọ́kọ́ kà nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin náà. Mo ronú pé Ọjọ́ Ìdájọ́ ti dé tán, mi ò sì tíì ṣe tán, torí náà mo gbà lọ́kàn mi pé mi ò ní là á já.”Crystal.

“Bí mo ṣe kà nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ yẹn wú mi lórí gan-an. Nígbà tí mo sì ti lóye ohun tí ìran náà jẹ́, ó wá nítumọ̀ sí mi.”Ed.

Ṣé bọ́rọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin inú ìwé Ìfihàn yẹn ṣe rí lára Crystal ló ṣe rí lára tìẹ náà? Àbí bó ṣe rí lára Ed ló ṣe rí lára rẹ̀? Èyí tó wù kó jẹ́, ọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin yìí ló gba àfiyèsí jù lọ nínú àwọn ìran inú ìwé Ìfihàn tàbí Ìṣípayá, ìyẹn ìwé tó kẹyìn nínú Bíbélì. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé tó o bá lóye ìran yìí dáadáa, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an? Lọ́nà wo? Ọlọ́run ṣèlérí pé wàá láyọ̀ gidi tó o bá ń ka ìwé tó ní àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tó o sì ń fi ohun tó wà nínú rẹ̀ ṣèwà hù.Ìṣípayá 1:1-3.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan tí wọ́n bá ka ìran àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin inú Bíbélì yìí, àmọ́ kì í ṣe torí kó lè bani lẹ́rù ló ṣe wà níbẹ̀. Kódà, ìran yìí ti mú kí ìgbàgbọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn túbọ̀ lágbára, ó sì mú kí wọ́n máa retí ọjọ́ iwájú tó dáa. Ọ̀rọ̀ tiẹ̀ náà lè rí bẹ́ẹ̀! Jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó kàn.