Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ No. 3 2017 | Bí Ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Yìí Ṣe Kàn Ọ́

KÍ LÈRÒ RẸ?

Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin yìí ló gba àfiyèsí jù lọ nínú àwọn ìran inú ìwé Ìfihàn tàbí Ìṣípayá, ìyẹn ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì. Ìran náà máa ń ba àwọn kan lẹ́rù. Ó sì máa ń múnú àwọn míì dùn. Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ báyìí:

“Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́.”Ìṣípayá 1:3.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin yìí ṣe lè já sí ìròyìn ayọ̀ fún wa.

 

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Bí Ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Inú Bíbélì Ṣe Kàn Ọ́

Àwọn ẹṣin mẹ́rin—ìkan jẹ́ funfun, ìkan pupa, ìkan dúdú, òmíràn sì jẹ́ ràndánrandán. Bí wọ́n ṣe ń bẹ́ gìjàgìjà jẹ́ ọ̀kan lára ìran tó gbàfiyèsí jù lọ nínú ìwé Ìṣípayá, tàbí Ìfihàn.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?

Wo bó o ṣe lè mọ ìtúmọ̀ ìran yìí.

Ẹ̀rí Mí ì Tún Rèé

O lè má mọ ẹni tó ń jẹ́ Táténáì, àmọ́ ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí fi hàn pé ó wà lóòótọ́.

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Mo Fẹ́ràn Baseball Gan-an!

Eré ìdíje ló gba Samuel Hamilton lọ́kàn jù, àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

“O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí”

Nílùú Íjíbítì, àwọn ìjòye Fáráò rí bí Sárà ṣe lẹ́wà tó. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà máa yà ẹ́ lẹ́nu.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé Ọlọ́run máa ń ṣe dáadáa sí àwọn kan ju àwọn mí ì lọ? Ṣé ègún wà lórí àwọn kan tàwọn mí ì sì ń dáa?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Làwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá Túmọ̀ Sí?

Ìwé yìí fúnra rẹ̀ sọ pé aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ka ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, tó lóye rẹ̀, tó sì ń pa á mọ́.