Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 1 2017

Àwọn èèyàn ń jìyà gan-an nínú ayé, àmọ́ ṣé Ọlọ́run ló fà á?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé Ọlọ́run ló ń fa ìjìyà?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!” (Jóòbù 34:10) Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìwà ibi àti ìjìyà tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Sátánì Èṣù tó jẹ́, “olùṣàkóso ayé,” ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá.Jòhánù 14:30.

  • Táwa èèyàn bá tún ṣe ìpinnu tí kò dáa, ó máa ń yọrí sí nǹkan burúkú àti ìyà.Jákọ́bù 1:14, 15.

Ṣé ìyà máa dópin?

Èrò àwọn kan ni pé táwa èèyàn bá ṣera wa lóṣùṣù ọwọ̀, nǹkan á dáa, àwọn míì sì gbà pé kò sí ohun tó lè mú kí ayé yìí dára sí i, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ní yóò máa burú sí i. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọlọ́run máa mú ìyà kúrò. “Ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”Ìṣípayá 21:3, 4.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Ọlọ́run máa lo Jésù láti fòpin sí ìyà tí Èṣù ti fà.1 Jòhánù 3:8.

  • Àwọn èèyàn rere á máa gbé ní àlááfíà lórí ilẹ̀ ayé títí láé.Sáàmù 37:9-11, 29.