Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 1 2017

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ

Báwo Ni Mo Ṣe Máa Gbádùn Ẹ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Máa Gbádùn Ẹ̀?

Ṣé kíka Bíbélì máa ń gbádùn mọ́ni? Àǹfààní wo lo sì máa rí níbẹ̀? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí sinmi lórí ọ̀nà tí ò ń gbà ka Bíbélì. Jẹ́ ká wo ohun tó o lè ṣe láti mú kí Bíbélì máa wù ẹ́ kà, kó o sì gbádùn rẹ̀.

Lo Bíbélì tó dáa, tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì bágbà mu. Tó o bá ka Bíbélì tí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣòro láti lóye tàbí tí kò bágbà mu, oò ní gbádùn ohun tí ò ń kà nínú rẹ̀. Torí náà, Bíbélì tó máa tètè yé ẹ táwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì máa wọ̀ ẹ́ lọ́kàn ni kó o lò. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ Bíbélì tí wọ́n fara balẹ̀ túmọ̀, tí ìtúmọ̀ rẹ̀ sì péye. *

Lo ohun èlò ìgbàlódé. Lóde òní, kì í ṣe orí ìwé nìkan la ti lè rí Bíbélì kà, a tún lè wà á jáde sórí fóònù, tablet tàbí kọ̀ǹpútà, ká sì máa kà á látibẹ̀. Àwọn Bíbélì orí ẹ̀rọ kan tiẹ̀ wà tó tún máa fún ẹ láǹfààní láti wo ẹsẹ Bíbélì kan tàbí kókó ọ̀rọ̀ kan nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì kó o lè fi wọ́n wéra. Tó bá jẹ́ pé èyí tó o lè tẹ́tí sí ló rọ̀ ẹ́ lọ́rùn, Bíbélì tí wọ́n ti kà sílẹ̀ tún wà tó o lè máa gbọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbádùn kí wọ́n máa tẹ́tí sí Bíbélì tí wọ́n ti kà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú mọ́tò, tí wọ́n ń fọṣọ, tàbí tí wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan míì tó gbà wọ́n láyè láti máa fetí sílẹ̀. Oò ṣe gbìyànjú èyí tó máa rọrùn fún ẹ nínú àwọn àbá yìí?

Lo ohun tó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ohun tó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ jàǹfààní nínú kíka Bíbélì. O lè lo àwòrán àwọn ilẹ̀ tí wọ́n  dárúkọ nínú Bíbélì, èyí máa jẹ́ kó o rí àwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kàn, wàá sì lè fọkàn yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ bí èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí tàbí àwọn tó wà ní apá tá a pè ní “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” lórí ìkànnì jw.org, máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí àwọn apá kan nínú Bíbélì túmọ̀ sí.

Lo onírúurú ọ̀nà. Tí kíka Bíbélì láti páálí dé páálí bá jọ pé ó kà ẹ́ láyà, o lè bẹ̀rẹ̀ nípa kíka àwọn apá tó gbádùn mọ́ ẹ jù lọ. Tó o bá fẹ́ mọ ìtàn àwọn èèyàn tó lókìkí nínú Bíbélì, o lè ka àwọn apá Bíbélì tó dá lórí ìtàn àwọn èèyàn. A sọ ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe é nínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìyẹn àpótí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “ Mọ Àwọn Èèyàn Tí Bíbélì Sọ̀rọ̀ Nípa Wọn.” O sì tún lè ka onírúurú ìtàn tó wà nínú Bíbélì tàbí bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Oò ṣe gbìyànjú ọ̀kan lára àwọn àbá náà?

^ ìpínrọ̀ 4 Ọ̀pọ̀ ti rí i pé Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun péye, ó ṣeé gbára lé, ó sì rọrùn láti kà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ Bíbélì yìí, ó sì wà ní èdè tó lé ní àádóje [130]. O lè wa Bíbélì yìí jáde lórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo tàbí kó o wa JW Library jáde láti play store sorí fóònù rẹ. Tó o bá sì fẹ́, ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè mú èyí tá a tẹ̀ jáde wá fún ẹ nílé.