Àwọn ìgbésẹ̀ wo lo lè gbé táá jẹ́ kó o gbádùn Bíbélì kíkà, kó o sì jàǹfààní nínú rẹ̀? Wo àwọn àbá márùn-ún yìí tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́.

Jẹ́ kí ibi tó o wà tù ẹ́ lára. Wá ibi tó pa rọ́rọ́, kó o sì dín ohun tó lè pín ọkàn rẹ níyà kù, kó o lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ò ń kà. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí ìmọ́lẹ̀ àti afẹ́fẹ́ tó tura wà níbẹ̀, kí ohun tí ò ń kà lè wọ̀ ẹ́ lọ́kàn.

Ní èrò tó tọ́. Ọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run ni Bíbélì ti wá, torí náà kó o lè jàǹfààní nínú rẹ̀, á dára kó o ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ bí ọmọdé tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tó o bá ti ní èrò òdì nípa Bíbélì tẹ́lẹ̀, o ní láti gbé èrò náà tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kí Ọlọ́run lè kọ́ ẹ.Sáàmù 25:4.

Kọ́kọ́ Gbàdúrà. Èrò Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, ìdí nìyẹn tá a fi nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ká lè lóye ohun tí à ń kà. Ọlọ́run ti ṣèlérí láti “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí mímọ́ yìí lè mú kó o mọ èrò Ọlọ́run lórí àwọn nǹkan. Tó bá yá, ẹ̀mí mímọ́ á ṣí ọkàn rẹ payá láti mọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”1 Kọ́ríńtì 2:10.

Kà á lọ́nà tó fi máa yé ẹ. Má kàn máa ka Bíbélì lọ gbuurugbu. Máa dánu dúró kó o lè ronú lórí ohun tó o kà. Bí ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ẹ̀kọ́ wo ni mo kọ́ lára ẹni tí mò ń kà nípa rẹ̀ yìí? Báwo ni mo ṣe lè fi ẹ̀kọ́ náà sílò nígbèésí ayé mi?’

Ní àfojúsùn kan. Kí Bíbélì kíkà tó lè ṣe ẹ́ láǹfààní, o yẹ kó o ní ohun kan lọ́kàn tó o fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tó máa wúlò fún ẹ nígbèésí ayé. O lè fi ṣe àfojúsùn rẹ pé: ‘Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run fúnra rẹ̀.’ ‘Mo fẹ́ túbọ̀ ní ìwà tó dáa, táá jẹ́ kí n jẹ́ ọkọ tàbí ìyàwó rere.’ Lẹ́yìn náà, yan ẹsẹ Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí kókó náà. *

Àwọn àbá márùn-ún tá a ti jíròrò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, báwo lo ṣe lè mú kí Bíbélì kíkà náà gbádùn mọ́ ẹ? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣèrànwọ́.

^ ìpínrọ̀ 8 Tí o kò bá mọ ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà lórí kókó kàn, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.