Kí Lèrò Rẹ?

Ṣé Bíbélì ṣì wúlò láyé ọ̀làjú tá a wà yìí? Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ, ó ní: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.”2 Tímótì 3:16, 17.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì àti àwọn ohun tá a lè ṣe láti jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà.