Ṣé a lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run?

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ ká mọ òtítọ́? Ka Jòhánù 17:3

Ọlọ́run bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láyé àtijọ́. Ó lo ẹ̀mí mímọ́ tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ láti fi èrò rẹ̀ sọ́kàn àwọn tó kọ Bíbélì. (2 Pétérù 1:20, 21) A lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run tá a bá ń ka Bíbélì.Ka Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16.

Ọlọ́run lo Bíbélì láti ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ara rẹ̀ fún wa. Ó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi dá àwa èèyàn, ohun tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú àti bó ṣe fẹ́ ká máa gbé ìgbésí ayé wa. (Ìṣe 17:24-27) Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa òun.Ka 1 Tímótì 2:3, 4.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́, ó sì rán Jésù ọmọ rẹ̀ wá sáyé kó lè kọ́ wa ní òtítọ́. Fún ìdí yìí, àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ máa ń wá sọ́dọ̀ Jésù. (Jòhánù 18:37) Irú àwọn tí Ọlọ́run fẹ́ kó máa jọ́sìn òun gan-an nìyẹn.Ka Jòhánù 4:23, 24.

Sátánì Èṣù kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ Ọlọ́run nípa kíkọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí kì í ṣe òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Àwọn tí kò bá nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ máa ń gba àwọn ẹ̀kọ́ èké yìí gbọ́. (Róòmù 1:25) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí sì tí mú kí wọ́n mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.Ka Ìṣe 17:11.