Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  December 2015

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé “láti gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run” ni àwọn Júù ti wá sí Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?

Èrò rẹpẹtẹ ní òpópónà kan ní Jerúsálẹ́mù nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni.

Láfikún sí àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìṣe 2:5-11, òǹkọ̀wé Júù tó ń jẹ́ Philo sọ bí èrò ṣe wọ́ wá sí Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni.

Philo kọ̀wé nípa àwọn tó ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù pé: “Èrò rẹpẹtẹ ló wá láti àìmọye ìlú, àwọn kan rìn wá, àwọn míì sì wọkọ̀ ojú omi wá. Orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé ni àwọn èèyàn ti ń wá lọ́dọọdún.” Ó tún fa ọ̀rọ̀ yọ látinú lẹ́tà kan tí ọmọ-ọmọ Hẹ́rọ́dù Ńlá, ìyẹn Àgírípà kìíní fi ránṣẹ́ sí Olú Ọba Róòmù náà Kaligúlà. Nínú lẹ́tà yìí, Àgírípà sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé: “Ìlú Ńlá Mímọ́ náà . . . kì í ṣe olú ìlú Jùdíà nìkan, àmọ́ ó tún jẹ́ olú ìlú fún ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míì. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó ṣí kúrò ní Jùdíà ló ti tẹ àwọn ìlú míì dó.”

Àgírípà wá mẹ́nu kan àwọn agbègbè táwọn Júù tẹ̀ dó sí tó jìnnà sí Jerúsálẹ́mù, irú bí Mesopotámíà, Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà Kékeré, Gíríìsì àtàwọn erékùṣù Mẹditaréníà. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Joachim Jeremias sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Àgírípà kò sọ nínú lẹ́tà rẹ̀ pé àwọn Júù máa ń rìnrìn àjò láti àwọn ìlú yìí wá sí Jerúsálẹ́mù, àmọ́ bọ̀rọ̀ ṣe máa jẹ́ nìyẹn torí pé Òfin Mósè pa á láṣẹ pé káwọn ọkùnrin Júù máa wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún.”Diutarónómì 16:16.

Ibo ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tó ń wá sí Jerúsálẹ́mù máa ń dé sí nígbà àjọyọ̀ àwọn Júù?

Àwókù ilé ìwẹ̀ kan tí wọ́n ti ń ṣe ààtò ìwẹ̀nùmọ́ tí wọ́n ṣàwárí ní Jerúsálẹ́mù

Àjọyọ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún, ìyẹn ni Àjọyọ̀ Ìrékọjá, Pẹ́ńtíkọ́sì àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn máa ń rìnrìn àjò wá sí Jerúsálẹ́mù fún àwọn àjọyọ̀ yìí. Wọ́n máa ń wá láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtàwọn ilẹ̀ míì táwọn Júù ń gbé. (Lúùkù 2:41, 42; Ìṣe 2:1, 5-11) Gbogbo àwọn arìnrìn àjò yìí ní láti wábi sùn sí.

Àwọn kan máa ń sùn ilé ọ̀rẹ́ wọn, àwọn míì sì máa ń sùn àwọn ilé èrò tàbí òtẹ́ẹ̀lì. Àwọn míì tún máa ń pàgọ́ sí ìtòsí odi ìlú. Ìlú kan tó ń jẹ́ Bẹ́tánì ni Jésù dé sí nígbà tó wá sí Jerúsálẹ́mù kẹ́yìn.Mátíù 21:17.

Wọ́n ṣàwárí àwọn ilé kan nítòsí tẹ́ńpìlì tó ní ọ̀pọ̀ ilé ìwẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ inú àwọn ilé yìí làwọn arìnrìn àjò máa ń dé sí, wọ́n á sì tún wẹ̀ níbẹ̀ kí wọ́n tó wọ inú tẹ́ńpìlì. Ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n kọ sínú ọ̀kan lára àwọn ilé náà fi hàn pé Theodotus tó jẹ́ àlùfáà àti aṣáájú sínágọ́gù ló kọ́ sínágọ́gù náà kí wọ́n lè máa ka Tórà níbẹ̀. Ó tún kọ́ àwọn òtẹ́ẹ̀lì, yàrá àti táǹkì omi kí àwọn arìnrìn àjò tí kò rí ilé lè ríbi wọ̀ sí.”