Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  November 2015

Kí Ni Bíbélì Sọ

Kí Ni Bíbélì Sọ

Ṣé àwọn òkú máa jíǹde?

Ó dájú pé ẹlẹ́dàá lágbára láti dá ẹ̀mí àwọn tó ti kú pa dà

Jèhófà ló fún wa ní ẹ̀mí. (Sáàmù 36:9) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé Ọlọ́run tó fún wa lẹ́mìí ní agbára láti dá ẹ̀mí àwọn tó ti kú pa dà. Bíbélì mú un dá wa lójú pé ohun tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú nìyẹn. (Ka Ìṣe 24:15) Àmọ́, kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa jí àwọn òkú dìde?

Ohun tí Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ látìbẹ̀rẹ̀ ni pé kí àwa èèyàn máa gbélé ayé kánrin kése. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; 2:15-17) Ohun tó ṣì fẹ́ títí di báyìí nìyẹn. Ó máa ń dùn ún bó ṣe ń rí i tí àwa èèyàn ń jìyà, tá a sì ń kú láìtọ́jọ́.Ka Jóòbù 14:1, 14, 15.

Ibo làwọn òkú máa jíǹde sí?

Ṣé ọ̀run ni Ọlọ́run fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbé? Rárá o. Àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run dá láti máa gbé ní ọ̀run. Ayé ló fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Jóòbù 38:4, 7) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn tí Jésù jí dìde. Orí ilẹ̀ ayé níbí ló jí àwọn èèyàn náà dìde sí. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn tó máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú máa jíǹde pa dà sórí ilẹ̀ ayé.Ka Jòhánù 5:28, 29; 11:44.

Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti yan ìwọ̀nba àwọn èèyàn díẹ̀ láti jíǹde sí ọ̀run, àwọn wọ̀nyí máa di ẹni ẹ̀mí bíi táwọn áńgẹ́lì. (Lúùkù 12:32; 1 Kọ́ríńtì 15:49, 50) Àwọn tó máa jíǹde sí ọ̀run máa láǹfààní láti bá Kristi jọba lé ayé lorí.Ka Ìṣípayá 5:9, 10.