Àwọn ará Róòmù ń fìyà jẹ àwọn Júù. Bíi ti àwọn baba ńlá wọn, wọ́n gbàdúrà léraléra pé kí Ọlọ́run gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Nígbà tó yá, wọ́n gbọ́ nípa Jésù. Ṣé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí lóòótọ́? Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi “ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tí a yàn tẹ́lẹ̀ láti dá Ísírẹ́lì nídè” lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù tó ń fìyà jẹ wọ́n. (Lúùkù 24:21) Àmọ́ ìṣòro wọn kò yanjú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ run.

Kí ló ṣẹlẹ̀? Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi jà fún àwọn Júù bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀? Kí sì nìdí tí kò fi pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jagun, kí wọ́n lè gba ara wọn sílẹ̀? Ṣé Ọlọ́run ti yí èrò rẹ̀ nípa ogun pa dà ni? Rárá o. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àyípadà ńlá kan ti dé bá àwọn Júù. Wọ́n ti kọ Jésù Ọmọ Ọlọ́run ní Mèsáyà. (Ìṣe 2:36) Torí náà, Ọlọ́run pa orílẹ̀-èdè náà tì.Mátíù 23:37, 38.

Ọlọ́run kò dáàbò bo àwọn Júù àti Ilẹ̀ Ìlérí náà mọ́, kò bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ogun mọ́, kò sì tì wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ jagun. Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn Júù pàdánù àwọn ìbùkún tí wọ́n máa ń rí gbà látàrí bí wọ́n ṣe jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. Ìdí ni pé orílẹ̀-èdè tuntun, tí Bíbélì pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ló ń rí ìbùkún rẹ̀ gbà báyìí. (Gálátíà 6:16; Mátíù 21:43) Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ló wá di Ísírẹ́lì Ọlọ́run tí à ń sọ yìí. Nígbà yẹn lóhùn-ún, Ọlọ́run mí sí Pétérù láti sọ fún wọn pé: “Nísinsìnyí jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.”1 Pétérù 2:9, 10.

Ní báyìí tó jẹ́ pé àwọn Kristẹni ló wá di “ènìyàn Ọlọ́run,” ṣé Ọlọ́run wá bẹ̀rẹ̀ sí í jà fún wọn, kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà táwọn ará Róòmù fi ń jẹ wọ́n? Àbí ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ bá àwọn ọ̀tá náà jagun? Rárá o, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, tó bá kan ogun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí, òun fúnra rẹ̀ ló máa ń pinnu ìgbà tí irú ogun bẹ́ẹ̀ máa wáyé. Ọlọ́run kò jagun fún àwọn Kristẹni nígbà yẹn lóhùn-ún, kò sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ jagun. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe àkókò yẹn ni Ọlọ́run fẹ́ dá wọn nídè lọ́wọ́ àwọn aninilára.

Torí náà, bíi ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ayé ìgbàanì, àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní láti dúró de àkókò tí Ọlọ́run máa pa àwọn ẹni ibi run. Kó tó di ìgbà yẹn, Ọlọ́run kò fún wọn láṣẹ láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jagun. Jésù Kristi mú kí kókó yìí ṣe kedere sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, kò sọ fún wọn pé kí wọ́n jagun, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó sọ fún wọn ni pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí àwọn ọmọ ogun Róòmù máa gbéjà ko ìlú Jerúsálẹ́mù ayé ìgbà yẹn, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ pé kí wọ́n sá kúrò níbẹ̀, wọn ò sì gbọ́dọ̀ bá wọn lọ́wọ́ sí ogun náà. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn.Lúùkù 21:20, 21.

Láfikún sí i, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, . . . nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san,’ ni Jèhófà wí.” (Róòmù 12:19) Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò yìí ni Pọ́ọ̀lù ń fà yọ. Ọ̀rọ̀  náà wà nínú Léfítíkù 19:18 àti Diutarónómì 32:35. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀nà kan tí Ọlọ́run ń gbà gbẹ̀san fún àwọn èèyàn rẹ ni pé ó máa ń tì wọ́n lẹ́yìn láti bá àwọn ọ̀tá wọn jagun. Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé èrò Ọlọ́run nípa ogun kò tíì yí pa dà. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run ṣì rí ogun gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbẹ̀san fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kó sì mú òpin dé bá gbogbo ìnilára àti ìwà burúkú. Àmọ́ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí láyé ìgbàanì, Ọlọ́run nìkan ló ń pinnu ìgbà tí irú ogun bẹ́ẹ̀ máa wáyé àti àwọn tó máa ja ogun náà.

Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò fún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní láṣẹ láti lọ jagun. Òde òní wá ńkọ́? Ǹjẹ́ Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kí àwọn èèyàn kan máa jagun? Àbí àkókò ti tó lójú Ọlọ́run láti dá sí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kó sì jà fún wọn? Kí tiẹ̀ ni èrò Ọlọ́run nípa ogun lóde òní? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.