Àwọn kan gbà pé bí ẹni fàkókò ṣòfò ni kéèyàn máa gbàdúrà torí kò sẹ́ni tó ń gbọ́ àdúrà. Àwọn míì máa ń gbàdúrà, àmọ́ ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé Ọlọ́run kò gbọ́ àdúrà wọn. Ọ̀gbẹ́ni kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà sọ èrò rẹ̀ nípa Ọlọ́run, ó ní òun bẹ Ọlọ́run pé: “Tiẹ̀ kàn sọ nǹkan kan fún mi.” Àmọ́, òun kò gbọ́ nǹkan kan rárá.

Síbẹ̀, Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ń gbọ́ àdúrà wa. Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn kan láyé àtijọ́, ó ní: “Láìkùnà, [Ọlọ́run] yóò fi ojú rere hàn sí ọ ní gbígbọ́ ìró igbe ẹkún rẹ; gbàrà tí ó bá gbọ́ ọ, yóò dá ọ lóhùn ní tòótọ́.” (Aísáyà 30:19) Ẹsẹ Bíbélì míì tún sọ pé: “Àdúrà àwọn adúróṣánṣán jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”—Òwe 15:8.

Jésù gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, “a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere.”—Hébérù 5:7

Bíbélì tún sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn. Ẹsẹ Bíbélì kan sọ nípa Jésù pé ó ṣe “ìtọrọ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là . . . a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere.” (Hébérù 5:7) Àpẹẹrẹ àwọn míì tí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn wà nínú Dáníẹ́lì 9:21 àti 2 Kíróníkà 7:1.

Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tàwọn kan fi rò pé Ọlọ́run kì í gbọ́ àdúrà wọn? Ohun kan tó ṣe pàtàkì ni pé, Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nìkan la gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí, ìyẹn Jèhófà. * A kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí ọlọ́run míì tàbí àwọn baba ńlá tó ti kú. Ọlọ́run tún sọ pé a gbọ́dọ̀ gbàdúrà “ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ [òun],” ìyẹn ni pé, ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí ló yẹ ká máa gbà ládùúrà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé òun máa “gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Torí náà, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ mọ Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì mọ ohun tó fẹ́.

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àdúrà kì í kàn ṣe ààtò ìsìn kan lásán, ṣùgbọ́n Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà, ó sì máa ń dáhùn wọn. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Isaac lórílẹ̀-èdè Kenya sọ pé: “Mo gbàdúrà kí n lè lóye ohun tí mò ń kà nínú Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ẹnì kan wá sọ́dọ̀ mi, kó lè ràn mí lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀.” Obìnrin kan tó ń jẹ́ Hilda lórílẹ̀-èdè Philippines fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ṣùgbọ́n, pàbó ni gbogbo akitiyan rẹ̀ já sí. Ọkọ rẹ̀ wá dábàá pé, “O ò ṣe gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́?” Hilda tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọkọ rẹ̀, ó wá sọ pé: “Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ràn mí lọ́wọ́ yà mí lẹ́nu gan-an. Ńṣe ni sìgá bẹ̀rẹ̀ sí í rùn sí mi. Mo sì jáwọ́ ńbẹ̀.”

Tí àdúrà rẹ bá bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu, ṣé o rò pé Ọlọ́run kò ní ràn ẹ́ lọ́wọ́?

^ ìpínrọ̀ 6 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.