Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  October 2015

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Àwọn ìṣòro wo ni Hẹ́rọ́dù kojú nígbà tó fẹ́ tún tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù kọ́?

Sólómọ́nì ló kọ́kọ́ kọ́ tẹ́ńpìlì sí orí òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Ó ṣe ògiri tó ní òpó sọ́wọ́ iwájú àti ẹ̀yìn òkè náà, kí ibi tó tẹ́jú pẹrẹsẹ lè yí ibi mímọ́ náà ká. Àmọ́ Hẹ́rọ́dù fẹ́ kọ́ tẹ́ńpìlì tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ ju ti Sólómọ́nì lọ. Torí náà, ó dáwọ́ lé àtúnṣe tẹ́ńpìlì náà kó lè mú un gbòòrò sí i.

ọn kọ́lékọ́lé tí Hẹ́rọ́dù lò mú kí ibi tó tẹ́jú pẹrẹsẹ yìí fẹ̀ sí i lọ sí ọwọ́ òsì tẹ́ńpìlì. Ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n fí ẹsẹ̀ bàtà márùnlélọ́gọ́rùn-ún [105] kún un kó lè túbọ̀ fẹ̀ sí i. Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, wọ́n fi òkúta ṣe ògiri tó lágbára láti gbé ilé náà dúró. Nígbà tó yá, wọ́n mọ ògiri yìí kó ga tó ẹsẹ̀ bàtà márùnlélọ́gọ́jọ [165].

Hẹ́rọ́dù sapá kó má báa ṣẹ àwọn Júù, kó má sì ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì àti ẹbọ tí wọ́n ń rú níbẹ̀. Josephus tó jẹ́ òpìtàn Júù sọ pé Hẹ́rọ́dù kọ́ àwọn àlùfáà Júù níṣẹ́ kọ́lékọ́lé àti káfíńtà, kí ẹni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ má báa wọ ibi mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì.

Ṣùgbọ́n Hẹ́rọ́dù kú kí iṣẹ́ náà tó parí. Nígbà tó fi máa di ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ti lo ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta [46] lẹ́nu iṣẹ́ àtúnkọ́ yìí. (Jòhánù 2:20) Ọmọ ọmọ Hẹ́rọ́dù, ìyẹn Ágírípà Kejì, ló parí iṣẹ́ náà ní ìdajì ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.

Kí nìdí táwọn aráàlú Málítà fi ronú pé apààyàn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀sìn àwọn Gírí ìkì ló mú kí àwọn aráàlú Málítà ronú bẹ́ẹ̀. Ìwé Ìṣe ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Málítà lẹ́yìn tí ọkọ ojú omi tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ rì síbẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kó igi tí wọ́n máa fi yáná sínú ààrò, ejò olóró kan dìrọ̀ mọ́ ọn lọ́wọ́. Bí àwọn aráàlú Málítà ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, wọ́n sọ pé: “Dájúdájú, òṣìkàpànìyàn ni ọkùnrin yìí, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé ó gúnlẹ̀ ní àlàáfíà láti inú òkun, ìdájọ́ ẹ̀san kò gbà á láyè láti máa wà láàyè nìṣó.”Ìṣe 28:4.

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìdájọ́ ẹ̀san” ni “di’ke.” Nínú ìtàn àròsọ àwọn Gíríìkì, Dike ni orúkọ abo òrìṣà tí wọ́n gbà pé ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀san ké lórí àwọn aṣebi. Èrò wọn ni pé abo òrìṣà yìí ló ń rí sí ọ̀ràn àwọn èèyàn, tí á sì lọ ròyìn ìwà àìtọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ fún òrìṣà Zeus, kí ẹlẹ́ṣẹ̀ má báa lọ láìjìyà. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn aráàlú Málítà máa ronú pé: ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù kò kú nígbà tí ọkọ wọn rì, síbẹ̀ abo òrìṣà Dike ṣì fẹ́ fìyà jẹ ẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi rán ejò olóró sí i.’ Àmọ́ àwọn èèyàn náà yí èrò wọn pa dà nígbà tí wọ́n rí i pé kò sí ohun tó ṣe Pọ́ọ̀lù.