Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ

Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Gbàdúrà?

Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Gbàdúrà?

“Tẹ́tẹ́ títa ti di mọ́líkì sí mi lára. Mo sì máa ń gbàdúrà pé kí n rí owó ńlá jẹ. Àmọ́ mi ò rí i jẹ rí.”—Samuel, * Kenya.

“Nígbà tí mo wà nílé ìwé, ohun tá a kàn máa ń ṣe ni pé ká gba àdúrà àkọ́sórí.”—Teresa, Philippines.

“Mo máa ń gbàdúrà tí mo bá ní ìṣòro. Mo máa ń gbàdúrà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti pé kí n lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tínú ẹ̀ dùn sí.”—Magdalene, Gánà.

Ohun tí Samuel, Teresa àti Magdalene sọ fi hàn pé onírúurú nǹkan làwọn èèyàn máa ń gbàdúrà fún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn kan ń béèrè ṣe pàtàkì ju tàwọn míì lọ. Àdúrà àwọn kan máa ń tọkàn wá, ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán sì ni tàwọn míì. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbàdúrà nípa ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, bíi kí wọ́n yege ìdánwò nílé ìwé, kí ẹgbẹ́ eléré ìdárayá tí wọ́n fẹ́ràn borí ìdíje tàbí fún ààbò Ọlọ́run lórí ìdílé wọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwádìí tiẹ̀ fi hàn pé àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn pàápàá máa ń gbàdúrà.

Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lo máa ń tọrọ nínú àdúrà rẹ? Yálà o máa ń gbàdúrà tàbí o kì í gbàdúrà, o lè máa ronú pé: ‘Ǹjẹ́ àdúrà tiẹ̀ máa ń ṣeni láǹfààní kankan? Ṣé ẹnì kan wà tó ń gbọ́ àdúrà?’ Òǹkọ̀wé kan gbà pé ńṣe ni ẹni tó ń gbàdúrà kàn ń dá ara rẹ̀ nínú dùn. Àwọn oníṣègùn kan tiẹ̀ sọ pé ńṣe ni àdúrà dà bí ìgbà tí èèyàn ń tu ara rẹ̀ nínú lásán. Ṣé ẹni tó ń gbàdúrà kàn ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò, àbí ńṣe ló kàn ń dánú ara rẹ̀ dùn?

Ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn, ó jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ tí àdúrà ń ṣe kọjá pé kó kàn tù wá nínú. Ó fi dá wa lójú pé ẹnì kan wà tó ń gbọ́ àdúrà tá a bá gbà lọ́nà tó yẹ, tí ohun tá a bá béèrè bá tọ̀nà. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.