Ǹjẹ́ ìṣẹ́ àti òṣì lè dópin láyé?

Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù ló ń kú lọ́dọọdún nítorí pé wọn kì í jẹunre kánú, wọn kò sì rówó tọ́jú ara wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan rí towó ṣe, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ tálákà paraku. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn òtòṣì ti wà.—Ka Jòhánù 12:8.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìṣẹ́ àti òṣì?—Mátíù 6:9, 10.

Kí ìṣẹ́ àti òṣì tó lè dópin, a máa nílò ìjọba kan tó máa lè pín nǹkan lọ́gbọọgba, tí ìka kan kò sì ní gùn ju ọ̀kan lọ. Irú ìjọba yìí tún máa ní láti fòpin sí ogun, torí ogun ló sábà máa ń fa òṣì. Ọlọ́run sì ti ṣèlérí pé òun máa mú ìjọba yìí wá.—Ka Dáníẹ́lì 2:44.

Ta ló lè fòpin sí ìṣẹ́ àti òṣì?

Ọlọ́run tí yan Jésù ọmọ rẹ̀ láti ṣàkóso gbogbo ayé. (Sáàmù 2:4-8) Jésù máa gba àwọn òtòṣì lọ́wọ́ ìnilára àti ìwà ipá.—Ka Sáàmù 72:8, 12-14.

Jésù tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlááfíà,” máa mú kí àlááfíà àti ààbò wà kárí ayé. Nígbà náà, gbogbo èèyàn máa ní ilé tara wọn, wọ́n á máa ṣiṣẹ́ tó gbádùn mọ́ wọn, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ sì máa wà.—Ka Aísáyà 9:6, 7; 65:21-23.