Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  October 2015

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ

Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú—Àdúrà

Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú—Àdúrà

Ká tó dáwọ́ lé ohun kan, a lè ronú pé, ‘Àǹfààní wo ni máa rí níbẹ̀?’ Ṣé ìmọtara ẹni nìkan ni tá a bá ní irú èrò yìí nípa àdúrà? Rárá o. Ìdí ni pé a máa ń fẹ́ mọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá gbàdúrà. Kódà, ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù béèrè pé: “Bí mo bá pè é, òun yóò ha dá mi lóhùn?”—Jóòbù 9:16.

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àdúrà ju ohun téèyàn fi ń dánú ara rẹ̀ dùn tàbí ààtò ẹ̀sìn kan lásán. Ọlọ́run tòótọ́ máa ń gbọ́ àdúrà wa. Tá a bá gbàdúrà lọ́nà tó yẹ, tá a sì ń béèrè ohun tó tọ́, ó dájú pé ó máa gbọ́ tiwa. Kódà, ó rọ̀ wá pé ká sún mọ́ òun. (Jákọ́bù 4:8) Kí wá ni àǹfààní tí àdúrà máa ń ṣe láyé wa? Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ nínú rẹ̀ yẹ̀ wò.

Ìbàlẹ̀ ọkàn.

Nígbà tá a bá kojú onírúurú ìṣòro ní ìgbésí ayé wa, àníyàn sábà máa ń gbà wá lọ́kàn. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa “gbàdúrà láìdabọ̀,” ká sì máa sọ àwọn ohun tá à ń “tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 5:17; Fílípì 4:6) Bíbélì fi dá wa lójú pé tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa].” (Fílípì 4:7) Ọkàn wa máa balẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan tá a bá sọ àwọn ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún Bàbá wa ọ̀run. Kódà, òun fúnra rẹ̀ fẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé Sáàmù 55:22 sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”

“Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”Sáàmù 55:22

 Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ti jàǹfààní àlàáfíà ọkàn tí Bíbélì sọ yìí. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Hee Ran lórílẹ̀-èdè South Korea sọ pé: “Bí mo tiẹ̀ ní ìṣòro ńlá, tí mo bá ṣáà ti gbàdúrà nípa rẹ̀, ńṣe lara máa ń tù mí, mo sì máa ń lókun láti fara dà á.” Obìnrin míì lórílẹ̀-èdè Philippines tó ń jẹ́ Cecilia sọ pé: “Torí pé abiyamọ ni mí, mo máa ń ṣàníyàn gan-an nípa àwọn ọmọ mi àti ìyá mi tí àìsàn kò jẹ́ kó dá mi mọ̀ mọ́. Àmọ́, àdúrà máa ń jẹ́ kí n gbọ́kàn kúrò lórí àwọn ìṣòro náà, torí mo mọ̀ pé Jèhófà máa bá mi tọ́jú wọn.”

Ó ń tù wá nínú, ó sì ń fún wa lókun nígbà ìṣòro.

Ṣé kòókòó-jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé lò ń bá fà á tàbí àwọn ìṣòro tó le koko míì? Àdúrà sí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” lè mú kára tù ẹ́. Bíbélì sọ pé ó máa ń “tù  wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Àpẹẹrẹ kan ni ìgbá tí Jésù ní ẹdùn ọkàn, ńṣe ló “tẹ eékún rẹ̀ ba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà.” Kí ni àbájáde rẹ̀? “Áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:41, 43) Àpẹẹrẹ míì ni ti ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Nehemáyà. Àwọn èèyàn burúkú halẹ̀ mọ́ ọn kó lè dá iṣẹ́ Ọlọ́run tó ń ṣe dúró. Ló bá gbàdúrà pé: “Nísinsìnyí, fún ọwọ́ mi lókun.” Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fi hàn pé Ọlọ́run fún un lókùn, ó sì parí iṣẹ́ náà. (Nehemáyà 6:9-16) Ọkùnrin kan lórílẹ̀-èdè Gánà tó ń jẹ́ Reginald sọ àǹfààní tí àdúrà máa ń ṣe fún un, ó ní: “Tí mo bá gbàdúrà, pàápàá jù lọ nígbà tí ìṣòro kan bá kọjá agbára mi, ó máa ń ṣe mí bíi pé mo ti sọ ìṣòro náà fún ẹni tó lè ràn mí lọ́wọ́, tó sì fi mi lọ́kàn balẹ̀ pé kí n má ṣe bẹ̀rù, kò séwu.” Kò sí àní-àní pé Ọlọ́run máa ń tù wá nínú tá a bá gbàdúrà sí i.

Ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Àwọn ìpinnu kan wà tó lè yí ìgbésí ayé wa àti tàwọn èèyàn wa pa dà. Báwo la ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó dáa? Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n [ní pàtàkì láti kojú ìṣòro], kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Jákọ́bù 1:5) Tá a bá béèrè fún ọgbọ́n, Ọlọ́run lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa ká lè ṣe ìpinnu tó dáa. Kódà, a lè dìídì béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ torí Jésù mú un dá wa lójú pé, “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:13.

Jésù pàápàá rí i pé ó pọn dandan kí òun gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà tó fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù fẹ́ yan àwọn ọkùnrin méjìlá tó máa jẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀, ‘ó fi gbogbo òru gbàdúrà sí Ọlọ́run.’—Lúùkù 6:12, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

Bíi ti Jésù, ọ̀pọ̀ lónìí ti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa, ìgbàgbọ́ wọn sì lágbára sí i nígbà tí wọ́n rí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà wọn. Obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Philippines tó ń jẹ́ Regina sọ onírúurú ìṣòro tó ń dojú kọ, òun ló ń dá gbọ́ bùkátà ìdílé lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú. Iṣẹ́ tún bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kò sì rọrùn fún un láti tọ́ àwọn ọmọ. Ọgbọ́n wo ló dá sí i? Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì dá mi lójú pé ó máa ràn mí lọ́wọ́.” Ọkùnrin kan láti Gánà tó ń jẹ́ Kwabena sọ ìdí tí òun fi gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ní: “Iṣẹ́ ìkọ́lé ni mò ń ṣe, ó sì ń mówó wọlé dáadáa fún mi. Àmọ́, iṣẹ́ náà bọ́ lọ́wọ́ mi lójijì.” Nígbà tó ń ronú lórí ohun tó máa ṣe, ó sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà kí n lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Ó sì dá mi lójú pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi ní ti pé mo rí iṣẹ́ tó fún mi láyè láti jọ́sìn Ọlọ́run, mo sì tún ráyè gbọ́ tara mi.” Tó o bá ń gbàdúrà nípa àwọn ohun tó kan àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, ó dájú pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà rẹ.

A ti mẹ́nu kan díẹ̀ lára nǹkan tí àdúrà lè ṣe fún wa. (Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpótí náà “ Àǹfààní Tí Àdúrà Ń Ṣe.”) Ṣùgbọ́n kó o tó lè rí àwọn àǹfààní wọ̀nyí, o ní láti kọ́kọ́ mọ Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́. Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ẹ́ pé kó o wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, kí wọ́n lè kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. * Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á jẹ́ pé o ti gbé ìgbésẹ̀ kan tó máa jẹ́ kó o sún mọ́ “Olùgbọ́ àdúrà.”—Sáàmù 65:2.

^ ìpínrọ̀ 14 Fún ìsọfúnni síwájú sí i, béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì, www.jw.org/yo.