“Ó ti pẹ́ díẹ̀ tí mo ti mọ Mike. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Àmọ́ ẹ̀sìn yẹn máa ń jọ mí lójú. Ta ni Jèhófà? Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi ṣe ọdún? Irú ẹgbẹ́ wo ni Mike lọ ń ṣe yìí?”—Becky, California, U.S.A.

“Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn aládùúgbò mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo bi ara mi pé: ‘Kí ló ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Orúkọ ẹ̀sìn yẹn pàápàá jọ mí lójú!’”—Zenon, Ontario, Canada.

“Ohun tí èmi àti ìyàwó mi rò ni pé ńṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fẹ́ tojú bọ ọ̀rọ̀ wa torí pé a kì í sábà lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. A sì gbà pé tí àwọn ẹ̀sìn tó gbajúmọ̀ ò bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wa, ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lásánlàsàn ló máa wá lè dáhùn rẹ̀?”—Kent, Washington, U.S.A.

“Kí n má parọ́, mi ò mọ nípa wọn, mi ò sì mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́.”—Cecilie, Esbjerg, Denmark.

Ó ṣeé ṣe kó o ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tí wọ́n ti ń wàásù láti ilé-dé-ilé, tàbí kó o ti pàdé wọn níbi tí wọ́n pàtẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí, tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọwọ́ ọ̀kan lára wọn lo ti gba ìwé ìròyìn tó ò ń kà yìí. Àmọ́, o lè máa wò ó pé, ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí pàápàá? O sì lè ní irú èrò tí àwọn tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ní.

Tó o bá ní ìbéèrè tàbí tí ohun kan ń jẹ ẹ́ lọ́kàn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ta ló yẹ kó o bi? Báwo lo ṣe lè mọ ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Ibo ni wọ́n tí ń rí owó tí wọ́n fi ń tẹ ìwé tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn ilé ìpàdé wọn? Kí nìdí tí wọ́n fi ń wá àwọn èèyàn lọ ilé wọn kí wọ́n lè wàásù fún wọn? Kí sì nìdí tí wọ́n fi ń pàtẹ ìwé síbi táwọn èèyàn pọ̀ sí?

Cecilie tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Mo ka ohun tó pọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Oríṣiríṣi nǹkan ni mo ti gbọ́ nípa wọn, tó fi mọ àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn fi ń bà wọ́n jẹ́. Ìyẹn ló jẹ́ kí n máa fi ojú burúkú wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Àmọ́ nígbà tó yá, Cecilie béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìgbà yẹn ló tó mọ òkodoro òtítọ́ nípa wọn.

Ṣé ìwọ náà fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? A rọ̀ ẹ́ pé kó o wádìí ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣe ìwé ìròyìn yìí. Ó ṣe tán ẹnu oníkàn la ti ń gbọ́ pọ̀n-ún. (Òwe 14:15) A retí pé àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa jẹ́ kó o mọ irú ẹni tá a jẹ́ àti ohun tá a gbà gbọ́. Á sì tún jẹ́ kó o mọ ìdí tá a fi ń wàásù.