Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  September 2015

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?

Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) À ń lo Bíbélì láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá, ìlànà inú rẹ̀ sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.

Bíbélì sọ pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run nìkan là ń jọ́sìn. À sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ fáwọn èèyàn torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀.Aísáyà 43:10-12.

Níwọ̀n bá a ti jẹ́ Kristẹni, a gbà gbọ́ pé Jésù “Ọmọ Ọlọ́run” * wá sí ayé, ó sì di Mèsáyà. (Jòhánù 1:34, 41; 4:25, 26) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run jí i dìde, ó sì pa dà sí ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:3, 4) Lẹ́yìn náà, ó di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 11:15) Ìjọba yìí ló sì máa sọ gbogbo ayé di Párádísè. (Dáníẹ́lì 2:44) Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”Sáàmù 37:11, 29.

“Tí wọ́n bá ka Bíbélì, wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló ń bá àwọn sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá ní ìṣòro kan, wọ́n á ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe yanjú ìṣòro náà. . . . Wọ́n gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè.”—Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Benjamin Cherayath, nínú ìwé ìròyìn Münsterländische Volkszeitung lórílẹ̀-èdè, Germany

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ṣàwọn èèyàn láǹfààní láyé àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe lè ṣe wá láǹfààní lóde òní. (Aísáyà 48:17, 18) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọwọ́ pàtàkì la fi mú àwọn ìlànà Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kìlọ̀ pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí àwọn àṣà tó máa sọ ara wa di ẹlẹ́gbin, torí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mu sìgá, a kì í sì lo oògùn olóró. (2 Kọ́ríńtì 7:1) A tún máa ń yẹra fún àwọn àṣà tí Bíbélì kà léèwọ̀, irú bí ìmutípara, ìṣekúṣe àti olè jíja.1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

^ ìpínrọ̀ 5 Bíbélì tún sọ pé Jésù ni “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run,” torí pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ dá.Jòhánù 3:18; Kólósè 1:13-15.