Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  September 2015

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Rí Ohun Tó Sàn Ju Òkìkí

Mo Rí Ohun Tó Sàn Ju Òkìkí

Lálẹ́ ọjọ́ kan lọ́dún 1984, ìgbésí ayé mi yí pa dà bìrí, wọ́n fi mí jẹ ọmọge tó rẹwà jù lọ nílùú Hong Kong. Èmi tí mo jẹ́ ọmọdé kan lásán tẹ́lẹ̀ wá di ìlúmọ̀ọ́ká. Gàdàgbà-gadagba ni wọ́n gbé fọ́tò mi síwájú ọkàn-ò-jọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin, mò ń jó, wọ́n tún máa ń pè mí wá sọ̀rọ̀ láwọn ibi pàtàkì, mo sì ń ṣe atọ́kùn ètò lórí tẹlifíṣọ̀n. Mo tún máa ń wọ aṣọ aláràbarà, mó sì máa ń bá àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn jáde, irú bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Hong Kong.

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, mó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe fíìmù, lọ́pọ̀ ìgbà èmi ni mo máa ń kó ipa tó pọ̀ jù nínú àwọn fíìmù náà. Ọ̀pọ̀ àwọn oníròyìn ló máa ń fẹ́ kọ ọ̀rọ̀ nípa mi, àwọn ayàwòrán máa ń fẹ́ ya fọ́tò mi, àwọn èèyàn sì máa ń fẹ́ kí n kó ipa pàtàkì nínú àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe, bí ìṣílé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákàn náà, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbé mi jáde lọ jẹun. Gbogbo èèyàn ló ń gba tèmi.

Èmi rèé nínú fíìmù kan

Bí àkókò ṣe ń lọ, mo wá rí i pé gbogbo afẹfẹyẹ̀yẹ̀ yìí ò rí bí mo ṣe rò. Àwọn fíìmù oníjàgídíjàgan ni mo máa ń ṣe, èyí sì léwu gan-an. Nínú àwọn fíìmù tí à ń ṣe ní Hong Kong, mo sábà máa ń ṣe eré géle, bíi kí n fi alùpùpù dá bírà lórí mọ́tò. Ọ̀pọ̀ fíìmù tí mo ṣe ló ní ìṣekúṣe, ìwà ipá àti ìbẹ́mìílò nínú.

Lọ́dún 1995, mo fẹ́ ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń gbé fíìmù jáde. Lóòótọ́, ó jọ pé mo ní gbogbo nǹkan tó yẹ kó fún mi láyọ̀, bí òkìkí, ọ̀rọ̀ àti ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ mi, síbẹ̀ mi ò láyọ̀. Torí náà, mo pinnu láti fi iṣẹ́ fíìmù sílẹ̀.

MO RÁNTÍ ÌGBÀ TÍ MO WÀ NÍ KÉKERÉ

Mo máa ń rántí irú ìgbàgbọ́ tí mo ní nígbà tí mo wà ní kékeré. Nígbà yẹn, gbogbo ọjọ́ Sátidé ni èmi àti ẹ̀gbọ́n mi máa ń lọ kí ìdílé kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Joe McGrath lorúkọ bàbá wọn, ó sì máa ń kọ́ èmi àtẹ̀gbọ́n mi pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́ta lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìdílé wọn láyọ̀, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú torí pé ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni bàbá wọn fi mú ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀. Mo máa ń gbádùn bá a ṣe máa ń lọ sí ìpàdé Kristẹni papọ̀. Nígbà míì, a máa ń lọ sí àwọn àpéjọ ńlá. Àwọn àkókò yẹn lárinrin púpọ̀, ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àmọ́ ilé tiwa kò tòrò, ńṣe ni inú mi máa ń bà jẹ́ ní gbogbo ìgbà. Ìwà bàbá mi máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn  bá màmá mi, èyí sì máa ń mú kí màmá mi sorí kọ́. Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá, màmá mi fi ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀. Èmi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ségesège. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], mo ṣe ìrìbọmi. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ìwà tí kò yẹ Kristẹni, débi pé èmi náà fi ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀.

MO PINNU LÁTI PA DÀ SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ

Kété lẹ́yìn tí mo ṣe ìgbéyàwó, àwọn alàgbà méjì látinú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ mi. Wọ́n ṣàlàyé bí mo ṣe lè pà dà sọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ṣètò pé kí míṣọ́nárì kan tó ń jẹ́ Cindy ràn mí lọ́wọ́. Ní àkókò yìí, ìgbàgbọ́ mi ti domi pátápátá. Mo wá sọ fún Cindy pé kó fi hàn mí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́. Ó sì fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Bíbélì tó ti ní ìmúṣẹ hàn mí. Bí èmi àti Cindy ṣe di ọ̀rẹ́ nìyẹn, ó wá ní òun máa kọ́ mi láwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, mo sì gbà. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tó wá yé mi pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà, ó sì fẹ́ kí n láyọ̀.

Nígbà tó yá, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo sì gbádùn kí n máa wà pẹ̀lú wọn ju kí n máa wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń ṣe fíìmù. Àmọ́ torí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi ní kékeré, ó máa ń ṣe mí bíi pé kò sẹ́ni tí mo lè fọkàn tán, èyí sì máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́. Ṣùgbọ́n, ẹnì kan nínú ìjọ fi Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè kápá èrò yìí. Mo sì tún kọ́ bí mo ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́.

OHUN TÓ DÁRA JU ÒKÌKÍ LỌ

Lọ́dún 1997, èmi àti ọkọ mi kó lọ sí Hollywood, ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù kí àwọn èèyàn lè jàǹfààní nínú ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. Bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí n ní ìtẹ́lọ́rùn tí mi ò ní nígbà tí mò ń ṣe fíìmù tí òkìkí mi sì ń kàn kiri. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2002, mo pàdé Cheri, tá a jọ mọra ní Hong Kong. Òun náà ti kó wá sí Hollywood. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ọ̀rọ̀ èmi àti Cheri fi jọra. Òun ló joyè ọmọge tó rẹwà jù ní Hong Kong ní ọdún tó ṣáájú tèmi. Kódà, òun ló gbé adé òye lémi lórí. Òun náà ti ń ṣe fíìmù, ó tún ń gbé fíìmù jáde, ó sì máa ń bá àwọn olùdarí fíìmù tó jẹ́ gbajúmọ̀ ṣiṣẹ́.

Àánú Cheri ṣe mí nígbà tí mo gbọ́ pé àrùn ọkàn pa àfẹ́sọ́nà rẹ̀. Àmọ́ kò rí ìtùnú nínú ẹ̀sìn Búdà tó ń ṣe. Lóòótọ́, òkìkí rẹ̀ kàn bíi tèmi, àmọ́ kò láyọ̀ kò sì fọkàn tán ẹnikẹ́ni. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì fún un, àmọ́ torí pé ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà, ó ṣòro fún un láti fara mọ́ ohun tí mò ń kọ́ ọ.

Ọ̀rẹ́ mi Cheri nínú fíìmù kan

Lọ́jọ́ kan lọ́dún 2003, Cheri pè mí lórí fóònù níbi tó ti ń ṣe fíìmù kan ní ìpínlẹ̀ Vancouver, lórílẹ̀-èdè Canada. Ó sọ fún mi pé bí òun ṣe ń wakọ̀ lọ ní ìgbèríko kan, tí òun sì ń gbádùn àwọn nǹkan tí òun ń wò, ṣàdédé lóun bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sókè pé: “Sọ fún mi, Ṣé ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́? Kí lorúkọ rẹ?” Àkókò yẹn ló wakọ̀ gba iwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ilé ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì rí orúkọ náà Jèhófà. Ìyẹn mú kó gbà pé Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà òun, torí náà ó wù ú láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kíákíá. Mo sì ṣètò bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa kàn sí i. Kò pẹ́  kò jìnnà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé tí wọ́n ti ń sọ èdè Chinese ní ìpínlẹ̀ Vancouver.

Cheri sọ pé: “Àwọn èèyàn yìí gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀. Ó sì rọrùn fún mi láti bá wọn sọ̀rọ̀.” Inú mi dùn nígbà tí Cheri sọ ọ̀rọ̀ yìí fún mi, torí pé kò ní ọ̀rẹ́ kankan láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe fíìmù. Cheri kò ṣíwọ́ lílọ sí ìpàdé. Àmọ́ lọ́dún 2005, ó fọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti ṣe fíìmù méjì tó gọntíọ lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, ìyẹn sì mú kó pa dà sí Hong Kong. Ó dùn mọ́ mi pé Cheri ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà lọ́dún 2006, ó sì ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Hong Kong. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ sin Jèhófà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, àmọ́ iṣẹ́ fíìmù tó ń ṣe kò jẹ́ kó rọrùn fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn rárá.

AYỌ̀ TÓ WÀ NÍNÚ RÍRAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́

Lọ́dún 2009, nǹkan yí pa dà fún Cheri. Ó pinnu láti fi iṣẹ́ fíìmù sílẹ̀ kó lè túbọ̀ ráyè ṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Ó yan àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ Kristẹni, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi àkókò tó pọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun. Ó tún ń gbádùn ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó dára jù.Mátíù 24:14.

Lẹ́yìn náà, Cheri kọ́ èdè Nepalese kó lè ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń sọ èdè náà ní Hong Kong. Àwọn èèyàn sábà máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn Nepalese tó ń gbé ní Hong Kong, torí pé wọn ò gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Chinese dáadáa àti pé àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀. Cheri sọ fún mi pé òun gbádùn bóun ṣe ń ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé, ó pàdé obìnrin Nepalese kan. Nǹkan díẹ̀ ni obìnrin náà mọ̀ nípa Jésù, àmọ́ kò mọ nǹkan kan nípa Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Cheri wá fi ibi tí Jésù ti gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ han obìnrin náà nínú Bíbélì. Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun lè gbàdúrà sí Ọlọ́run tòótọ́ tó ń jẹ́ Jèhófà, tọkàntọkàn ló fi gba ìhìn rere náà. Kò pẹ́ tí ọkọ obìnrin náà àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.Sáàmù 83:18; Lúùkù 22:41, 42.

Cheri rèé báyìí

Nígbà tí mo rí i pé Cheri ń gbádùn bó ṣe ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù, mo bi ara mi pé, ‘Kí ló dé tí èmi náà ò lè ṣe bí i tiẹ̀?’ Ní àkókò tí mò ń sọ yìí, mo ti pa dà sí Hong Kong. Mo ṣe àwọn àyípadà kan kí n lè túbọ̀ ráyè wàásù fún àwọn èèyàn. Mo ti wá rí i pé tí mo bá ń tẹ́tí sí àwọn èèyàn, tí mo sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa ń múnú mi dùn.

Mo ti wá rí i pé ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń fún mi láyọ̀ jù lọ

Bí àpẹẹrẹ, mo kọ́ obìnrin Vietnamese kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tẹ́lẹ̀, inú rẹ̀ sábà máa ń bà jẹ́ ó sì máa ń sunkún lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́ ní báyìí inú rẹ̀ ti ń dùn, ó sì máa ń gbádùn kó máa wà pẹ̀lú àwọn ará ìjọ.

Èmi àti Cheri ti rí ohun tó dára ju òkìkí lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ fíìmù sọ wá di ìlúmọ̀ọ́ká tí àwọn èèyàn sì máa ń yẹ́ wa sí, àmọ́ kíkọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà Ọlọ́run ló ń fún wa láyọ̀, torí pé iṣẹ́ náà ń fi ògo fún un. A ti wá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”Ìṣe 20:35.