Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  September 2015

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?

Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ibi gbogbo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà kárí ayé, a ò sì dara pọ̀ mọ́ àwùjọ ẹ̀sìn èyíkéyìí. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni orílé-iṣẹ́ wa wà, síbẹ̀ èyí tó pọ̀ jù lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè míì. Kódà, a ti lẹ́ ní mílíọ̀nù mẹ́jọ báyìí, a sì ń wàásù ní àwọn ilẹ̀ tó lé ní 230 kárí ayé. À ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”Mátíù 24:14.

Ibi yòówù ká máa gbé, tọkàntọkàn la fi ń pa òfin ìlú mọ́. Síbẹ̀, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Ìdí ni pé à ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jésù fún gbogbo Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ “apá kan ayé.” Torí náà, a kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú tàbí ọ̀ràn ogun. (Jòhánù 15:19; 17:16) Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́lé, wọ́n fìyà jẹ àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì pa àwọn míì. Ìdí sì ni pé wọn ò dá sí ọ̀ràn ogun. Ẹnì kan tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù nílẹ̀ Jámánì nígbà kan sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níkàn ló lè fọwọ́ sọ̀yà pé àwọn ò dá sí ọ̀ràn ogun nígbà ìjọba Násì.”

“[Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ní ìwà ọmọlúwàbí. Wọn kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan, torí náà irú wọn là ń fẹ́ kó di ipò pàtàkì mu láwùjọ. Àmọ́, wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. . . . Wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ, àmọ́ wọ́n gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro àwa èèyàn.”—Ìwé ìròyìn Nová Svoboda, lórílẹ̀-èdè Czech Republic.

Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé à ń dá tara wa ṣe o. Jésù gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé.” (Jòhánù 17:15) Torí náà, wàá rí i pé a máa ń lọ sí ibiṣẹ́, a máa ń lọ sí ọjà, a sì máa ń lọ sí ilé ìwé pẹ̀lú àwọn èèyàn tó wà níbi tá a bá ń gbé.