Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  September 2015

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ àsọtẹ́lẹ̀?

KÍ nìdí tí bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa?Lúùkù 21:10, 11.

Kò sí èèyàn kankan tó lè sọ bí ọlà ṣe máa rí. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ ló wà nínú Bíbélì. Gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ló ṣẹ, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.Ka Jóṣúà 23:14; 2 Pétérù 1:20, 21.

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó ti ṣẹ jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká gba Ọlọ́run gbọ́. (Hébérù 11:1) Ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa máa ṣẹ. Torí náà, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa ń fún wa ní ìrètí tó dájú.Ka Sáàmù 37:29; Róòmù 15:4.

Àǹfààní wo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe wá?

Ọlọ́run fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan kìlọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn Kristẹni ayé ọjọ́un rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ìparun ìlú Jerúsálẹ́mù ti ń ṣẹ, wọ́n sá kúrò ní ìlú náà. Nígbà tó yá, ìlú Jerúsálẹ́mù pa run torí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn aráàlú yẹn kọ Jésù. Àmọ́, àwọn Kristẹni tó fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wá ibòmíì forí pa mọ́ sí kí ìlú náà tó pa run.Ka Lúùkù 21:20-22.

Lóde òní, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44; Lúùkù 21:31) Torí náà, ó yẹ ká tètè ṣe ohun tó máa jẹ́ ká rí ojúure Ọba tí Ọlọ́run yàn, ìyẹn Jésù Kristi.Ka Lúùkù 21:34-36.

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí ìjọba Ọlọ́run fi dára ju gbogbo ìjọba yòókù lọ.

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé

Ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún ṣáájú, Ọlọ́run fi ìgbà tí Mèsáyà máa dé gẹ́lẹ́ hàn. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì yìí!