Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ LÈ JÍǸDE?

Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Ṣé àwọn òkú lè jíǹde?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”Jòhánù 5:28, 29.

Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé Sàréè máa ṣófo lábẹ́ Ìjọba òun lọ́jọ́ iwájú. Fernando tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Ẹnu yà mí nígbà àkọ́kọ́ tí mo ka Jòhánù 5:28, 29, ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kí n ní ìrètí, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”

Láyé ìgbàanì, ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù ní ìrètí pé Ọlọ́run máa jí òun dìde tí òun bá kú. Jóòbù béèrè pé: ‘Bí ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?’ Òun fúnra rẹ̀ wá fi ìdánilójú dáhùn pé: “Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo [nínú Sàréè] ni èmi yóò fi dúró, títí ìtura mi yóò fi dé. Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.”Jóòbù 14:14, 15.

Àjíǹde Lásárù jẹ́ ká ní ìrètí pé àwọn òkú máa jíǹde

Ọ̀rọ̀ àjíǹde kì í ṣe nǹkan tuntun sí Màtá arábìnrin Lásárù. Nígbà tí Lásárù kú, Jésù sọ fún un pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Màtá dáhùn pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Jésù wá sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 11:23-25) Lẹ́yìn náà, Jésù jí Lásárù dìde. Ìtàn yìí jẹ́ ká mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Fojú inú wo bó ṣe máa rí nígbà tí Jésù bá jí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kú dìde!

Ṣé àwọn kan máa jíǹde sí ọ̀run?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àjíǹde Jésù yàtọ̀ sí tàwọn mẹ́jọ yòókù tó wà nínú Bíbélì. Àwọn mẹ́jọ yìí jíǹde pa dà sáyé. Àmọ́ ní ti àjíǹde Jésù, Bíbélì sọ pé: “Jésù Kristi . . . wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, nítorí tí ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ọ̀run.” (1 Pétérù 3:21, 22) Ṣé Jésù nìkan ló máa jíǹde sí ọ̀run? Ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.”Jòhánù 14:3.

Kristi lọ sí ọ̀run láti lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún díẹ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó ń bọ̀. Iye àwọn tó máa jíǹde sí ọ̀run jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. (Ìṣípayá 14:1, 3) Ṣùgbọ́n, kí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù yìí fẹ́ máa ṣe lọ́run?

 Iṣẹ́ ńlá ni wọ́n fẹ́ lọ ṣe! Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ àti mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní; ikú kejì kò ní àṣẹ kankan lórí àwọn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:6) Àwọn tó máa jíǹde sí ọ̀run máa jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi, wọ́n sì máa ṣàkóso ayé.

Àwọn wo ló máa jíǹde lẹ́yìn náà?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Bíbélì pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìrètí tí àwọn ọkùnrin yìí pẹ̀lú ní, pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”Ìṣe 24:15.

Bíbélì jẹ́ kó dáwa lójú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ti kú máa jíǹde

Àwọn wo ló máa wà lára “àwọn olódodo” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Dáníẹ́lì ọkùnrin olóòótọ́ kú, áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún un pé: “Ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 12:13) Ibo ni Dáníẹ́lì máa jíǹde sí? Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Dáníẹ́lì àtàwọn olóòótọ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì máa gbébẹ̀ títí láé.

Àwọn wo ló máa wà lára “àwọn aláìṣòdodo” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn? Àwọn ni ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọn ò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà láàyè. Lẹ́yìn tí wọ́n bá jíǹde, wọ́n á láǹfààní láti mọ Jèhófà * àti Jésù, kí wọ́n sì fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run làwọn máa sẹ. (Jòhánù 17:3) Àwọn tó bá yàn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà títí lọ kánrin lórí ilẹ̀ ayé, bí Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣe wà títí láé.

Àwọn tó bá yàn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà títí lọ kánrin lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n máa láyọ̀, ìlera wọn sì máa dáa

Báwo ni nǹkan ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.”Aísáyà 65:21.

Fojú inú wo bó ṣe máa dùn tó kó o máa gbé ní irú ipò yìí pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n ti jíǹde! Àmọ́, ìbéèrè kan ni pé, Kí ló máa mú kó dá ọ lójú pé àjíǹde máa wáyé lóòótọ́?

^ ìpínrọ̀ 15 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.