Kí nìdí tá a fi wà láyé?

Ṣé o máa ń rò pé ẹ̀mí àwa èèyàn kò gùn tó?

Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé, kí nìdí tá a fi wà láyé? Ṣé kò ju pé ká kàn máa ṣeré, ká ṣiṣẹ́, ká gbéyàwó, ká ní ìdílé, ká sì darúgbó? (Jóòbù 14:1, 2) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n náà máa ń ní irú èrò yìí.Ka Oníwàásù 2:11.

Kí la wá ṣe láyé gan-an? Ká tó lè mọ ohun tá a wá ṣe láyé, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn kan kíyè sí ọ̀nà àgbàyanu tí ọpọlọ wa àti gbogbo ara wa ń gbà ṣiṣẹ́, wọ́n gbà pé ọlọ́gbọ́n kan gbọ́dọ̀ wà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá. (Ka Sáàmù 139:14.) Ó sì máa nídìí tó fi dá wa! Tá a bá mọ ìdí tá a fi wà láyé, èyí máa jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá èèyàn?

Ọlọ́run súre fún ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fún wọn ní iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni láti ṣe. Ó fẹ́ kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè, kí wọ́n sì máa gbébẹ̀ títí láé.Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 31.

Àmọ́, wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, èyí sì ṣèdíwọ́ fún ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé. Síbẹ̀, Ọlọ́run kò pa wá tì, kò sì yí ohun tó fẹ́ ṣe pa dà. Bíbélì sì tún fi dá wa lójú pé Ọlọ́run ti ṣe ohun tó máa jẹ́ kó lè gba àwọn olódodo là, kí ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé sì ní ìmúṣe! Nítorí náà, Ọlọ́run fẹ́ kó o gbádùn ìgbésí ayé rẹ, bó ṣe fẹ́ kó rí nígbà tó dá wa sáyé! (Ka Sáàmù 37:29.) Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ bó o ṣe lè gbádùn àwọn ìbùkún yìí.