Obìnrin kan tó ń jẹ́ Alona sọ pé: “Nígbà tí bọ́ǹbù fẹ́ dún, wọ́n tẹ aago ìkìlọ̀, bí mo ṣe gbóhùn aago yìí, àyà mi já pà, ni mo bá sá lọ sí ilé kan tí wọ́n kọ́ fún ààbò nígbà tí wọ́n bá ju bọ́ǹbù. Síbẹ̀ náà, ọkàn mi ò balẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà tún wá burú sí i nígbà tí mo wà níta, tí mi ò sì ríbi sá sí. Lọ́jọ́ kan tí mò ń rìn lọ ládùúgbò, mo kan bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, débi pé mi ò lè mí mọ́. Ó pẹ́ díẹ̀ kí ara mi tó wálẹ̀. Ni aago ìkìlọ̀ náà bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í dún.”

Alona

Kì í ṣe ogun nìkan ló máa ń fa ewu. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá gbọ́ pé o ní àrùn tó lè gba ẹ̀mí ẹni tàbí pé ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ ní irú àìsàn bẹ́ẹ̀, ó lè kó ẹ lọ́kàn sókè. Ìbẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú sì máa ń fa àníyàn fún àwọn míì. Wọ́n lè máa ronú pé ṣé inú ayé tó kún fún ogun, ìwà ọ̀daràn, ìbàyíkájẹ́, ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà àti àjàkálẹ̀ àrùn làwọn ọmọ wa àtàwọn ọmọ ọmọ wa máa dàgbà sí? Báwo la ṣe lè kápá irú àníyàn bẹ́ẹ̀?

Torí a mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ aburú máa ń ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká jẹ́ “afọgbọ́nhùwà tí ó ti rí ìyọnu àjálù [tí ó sì] fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 27:12) Bí a ṣe ń sapá kí ìlera wa lè dára, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ọpọlọ wa jí pépé kí ìrònú wa sì já gaara. Àwọn eré ìnàjú oníwà ipá àti ìròyìn tá à ń gbọ́ máa ń gbé àwòrán tó ń bani lẹ́rù síni lọ́kàn, èyí sì máa ń dá kún àníyàn tí à ń ṣe nípa ara wa àti àwọn ọmọ wa. Àmọ́, a ò wá ní torí pé a ò fẹ́ rí àwọn nǹkan yìí ká wá jókòó pa sílé. Ọlọ́run kò  dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé ohun tó ń báni lọ́kàn jẹ́ nìkan la ó máa rò ṣáá. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, . . . tí ó jẹ́ òdodo, . . . tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, . . . tí ó dára ní fífẹ́, ló yẹ ká fi kún ọkàn wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ “Ọlọ́run àlàáfíà” yóò fi ìbàlẹ̀ ọkàn jíǹkí wa.—Fílípì 4:8, 9.

ÌDÍ TÍ ÀDÚRÀ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tá a bá ní ìgbàgbọ́ tó dúró digbí, ó máa jẹ́ ká lè borí àníyàn. Bíbélì gbà wá níyànjú pé “kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.” (1 Pétérù 4:7) A lè bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n àti ìgboyà tó máa jẹ́ ká lè borí ìṣòro wa, ó sì dá wa lójú pé “ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè.”—1 Jòhánù 5:15.

Alona àti Avi, ọkọ rẹ̀

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì ni “olùṣàkóso ayé yìí” kì í ṣe Ọlọ́run, àti pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19) Abájọ tí Jésù fi kọ́ wa láti máa gbàdúrà pé: “Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 6:13) Alona sọ pé: “Nígbàkigbà tí aago ìkìlọ̀ bá dún, ńṣe ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n má ṣe kó ọkàn sókè jù. Bákan náà, ọkọ mi máa ń pè mí lórí fóònù, á sì gbàdúrà pẹ̀lú mi. Àdúrà máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” Ńṣe ló bá ohun tí Bíbélì sọ mu gẹ́lẹ́ pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́.”—Sáàmù 145:18.

ÌRÈTÍ WÀ PÉ NǸKAN ṢÌ Ń BỌ̀ WÁ DÁA

Nígbà tí Jésù ń wàásù lórí òkè, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mátíù 6:10) Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun tó ń fa àníyàn kúrò títí láé. Ọlọ́run máa lo Jésù “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” láti mú “kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 9:6; Sáàmù 46:9) Ọlọ́run “yóò ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn . . . Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. . . . Kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:3, 4) Àwọn ìdílé aláyọ̀ “yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” (Aísáyà 65:21) “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

Lóde òní, kò sí bá a ṣe lè ṣọ́ra ṣe tó, a ò lè dáwọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aburú dúró, èèyàn sì lè rin àrìnfẹsẹ̀sí tàbí kó ṣe kòńgẹ́ aburú nígbà míì. (Oníwàásù 9:11) Ogun, ìwà jàgídíjàgan àti àrùn ṣì ń pa àwọn èèyàn, bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ǹjẹ́ ìrètí wà fún irú àwọn tó ti bá àjálù bẹ́ẹ̀ lọ?

Àìmọye mílíọ̀nù èèyàn máa tún pa dà jíǹde. Ní báyìí, ńṣe ni wọ́n ń sùn. Jèhófà kò sì ní gbàgbé wọn. Lọ́jọ́ kan “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde, ó jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Ìrètí yìí ni àwa ní gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in.” (Hébérù 6:19) Ọlọ́run sì ti “pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí [Jésù] dìde kúrò nínú òkú.”—Ìṣe 17:31.

Àmọ́ ní àkókò yìí, àwọn tó ń sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ pàápàá máa ń ṣe àníyàn. Paul, Janet, àti Alona tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí kò kọ́kàn sókè mọ́, torí pé wọ́n ṣe ohun tó fọgbọ́n hàn, wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà, wọ́n sì gbọ́kàn lé àwọn ìlérí Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la. Àdúrà wa ni pé, “kí Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí fi ìdùnnú àti àlàáfíà gbogbo kún inú yín nípa gbígbàgbọ́ yín,” gẹ́gẹ́ bó ti ṣe fún àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí.—Róòmù 15:13.