Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  May 2015

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Nje Opin Ti Sun Mole?

Nje Opin Ti Sun Mole?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa fàyè gba àwọn èèyàn láti máa jẹ gàba lórí ara wọn, kí wọ́n sì máa ba ayé yìí jẹ́ nìṣó? Rárá o, Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa dá sí ọ̀rọ̀ aráyé láìpẹ́, òun á sì fòpin sí ìṣẹ́ àti ìnira. A dúpẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká mọ ìgbà tí òun máa gbé ìgbésẹ̀ náà. Àmọ́ báwo ló ṣe jẹ́ ká mọ òtítọ́ pàtàkì yìí?

Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé o fẹ́ rìnrìn àjò lọ síbì kan tóò dé rí, ó dájú pé wàá béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹni tó mọ̀nà. Bó o ṣe ń lọ lọ́nà, tó o sì ń rí àwọn àmì tẹ́ni náà júwe fún ẹ ni ọkàn rẹ á túbọ̀ balẹ̀ pé oò ṣìnà, á sì tún dá ẹ lójú pé o ti sún mọ́ ibi tí ò ń lọ. Bákan náà, Ọlọ́run fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé ṣe bá àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn mu gẹ́lẹ́. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó ń wáyé yìí sì jẹ́ àmì tó dájú pé àkókò tí à ń gbé yìí ló kángun sí ìgbà tí òpin máa dé.

Bíbélì fi hàn pé bí ayé yìí ṣe ń bá a lọ, a máa dé sáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan tó máa sàmì sí àkókò òpin gan-an. Lákòókò yẹn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá ò rírú rẹ̀ rí nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn àti ipò tí kò bára dé máa wáyé. Díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ pé ó máa wáyé rèé.

1. ÌDÀRÚDÀPỌ̀ MÁA GBAYÉ KAN Ìwé Mátíù orí kẹrìnlélógún [24] sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan á wáyé tó máa fi hàn pé a ti wà ní ọjọ́ ìkẹyìn. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà para pọ̀ jẹ́ àmì kan, wọ́n sì sàmì sí “ìparí ètò àwọn nǹkan,” tó máa jẹ́ ká mọ ìgbà tí ‘òpin yóò dé.’ (Ẹsẹ 3 àti 14) Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn ogun tó mi ayé tìtì, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ láti ibì kan sí ibòmíì, ìwà àìlófin tó gbòde kan àti àìsí ìfẹ́. Kódà, ó tún sọ pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì á máa fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tú àwọn ọmọ ìjọ jẹ bí iṣu. (Ẹsẹ 6-26) Lóòótọ́, dé ìwọ̀n àyè kan, irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ń wáyé láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn. Àmọ́, bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà á máa wáyé lákòókò kan náà tí aráyé wà nínú hílàhílo tó bùáyà. Ohun mẹ́ta tá a máa sọ tẹ̀ lé èyí tún jẹ́ ìkìlọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé.

2. ÌWÀ ÀWỌN ÈÈYÀN MÁA BURÚ SÍ I Bíbélì sọ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn àkókò tó sàmì sí òpin, àwọn èèyàn á máa hùwà tó burú jáì. Ó ní: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-4) Bí àwa náà bá wò ó, ìwà àìnáání ara ẹni lẹ́nì-kìíní-kejì ti wà ọjọ́ pẹ́, àmọ́ ìwà tí àwọn èèyàn á máa hù sí ara wọn ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí máa lékenkà débí tí a fi lè pe sáà yìí ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Àbí ìwọ náà ò rí i pé ìwà àwọn èèyàn túbọ̀ ń burú sí i ni?

3. ÀWỌN ÈÈYÀN Á MÁA BA ILẸ̀ AYÉ JẸ́ Bíbélì sọ pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Kí la rí tá a fi sọ pé àwọn èèyàn ń run ilẹ̀ ayé tàbí bà á jẹ́? Bíbélì sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nípa ìgbà ayé Nóà, ó ní: “Ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá. Nítorí náà, Ọlọ́run rí ilẹ̀ ayé, sì wò ó! ó bàjẹ́.” Ọlọ́run wá sọ nígbà yẹn pé: “Èmi yóò run wọ́n,” ìyẹn àwọn èèyàn burúkú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11-13) Ǹjẹ́ ìwọ náà ò kíyè sí pé ìwà ipá kún inú ayé lónìí? Ní ti gidi, a wà ní sáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn aráyé. Àwọn tó ń ba ayé jẹ́ ti gbèrú nínú ìwà burúkú wọn débi pé wọ́n lágbára tó lè pa gbogbo èèyàn run láìkù kan. Àwọn ohun ìjà tí wọ́n lè fi ṣọṣẹ́ burúkú yìí sì wà níkàáwọ́ wọn. Ọ̀nà míì tún wà tí àwọn èèyàn gbà ń ba ayé yìí jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tó ń gbé ìwàláàyè ró bí afẹ́fẹ́ tá à ń mí, ewéko àtàwọn ẹranko, òkun àtàwọn ohun abẹ̀mí inú rẹ̀ làwọn ọmọ aráyé ti bà jẹ́.

 Ẹ gbọ́ ná, ‘ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ǹjẹ́ ọmọ aráyé tiẹ̀ lálàá pé àwọn máa ṣe ohun ìjà tó lágbára láti pa gbogbo ohun alààyè inú ayé yìí run bí?’ Àmọ́, ẹ wo bí wọ́n ṣe ń kó àwọn ohun ìjà olóró jọ, tí wọ́n sì fi ń run àyíká. Àti pé bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe ń tẹ̀ síwájú yìí, bóyá lagbára ẹ̀dá èèyàn á lè ká àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń gbé jáde. Bákan náà, wọn ò mọ bí ọṣẹ́ tó máa ṣe á ṣe rinlẹ̀ tó. Bó ti wù kó rí, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé yìí lọ́jọ́ iwájú kọjá òye wa, kò sì sí níkàáwọ́ ẹ̀dá èèyàn. Ọlọ́run ti sọ pé kí ọmọ aráyé tó ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe, òun máa dá sí ọ̀rọ̀ náà, òun á sì run àwọn tó ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Asọ̀rọ̀mátàsé sì ni Ẹlẹ́dàá wa!

4. IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ MÁA KÁRÍ AYÉ Nǹkan míì tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé ni iṣẹ́ kan tí kò láfiwé tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Iṣẹ́ ìwàásù yìí máa yàtọ̀ gédégbé sí ìwàásù táwọn onísìn ń sọ pé àwọn ń ṣe kiri láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run” ló máa jẹ́ lájorí ìwàásù tá à ń sọ náà. Ìsìn wo ni ìwọ mọ̀ tó ń sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn? Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn kan ní àwọn ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ṣé wọ́n kàn ń ṣe é ládùúgbò ni àbí ibi gbogbo ni wọ́n ti mọ̀ wọ́n pé àwọn ni wọ́n ń wàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè”?

À ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè

“Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run” ni ìkànnì www.jw.org ń gbé lárugẹ. Àwọn ìwé ìròyìn tó wà lórí ìkànnì yìí ń ṣàlàyé ìhìn rere Ìjọba náà ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700]. Ǹjẹ́ ohun míì wà táwọn èèyàn ti ṣe láti fi kéde Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé? Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó wà làwọn èèyàn ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí akínkanjú tó ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kódà, láti ọdún 1939 ni ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ wa ti ń ní àkọlé náà tó sọ pé “Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.” Ìwé kan tí wọ́n fi ń ṣàlàyé nípa àwọn ẹ̀sìn sọ pé: “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹ̀sìn tó lè wàásù lọ́nà tó jinlẹ̀ tó sì gbòòrò” tó ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Iṣẹ́ ìwàásù yìí ni wọ́n fi ń kéde pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run á gbé ìgbésẹ̀, “òpin yóò sì dé.”

ÀKÓKÒ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀ NÍNÚ ÌTÀN ARÁYÉ

Ṣé o ti wá rí bí mẹ́rin lára àwọn àmì tí Bíbélì fi kìlọ̀ nípa òpin ṣe ń wáyé lákòókò tá a wà yìí? Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí ìwé ìròyìn yìí ti ń fún wa ní ìsọfúnni tó ṣe ṣàkó nípa ohun tó ń lọ láyé, èyí sì ń jẹ́ ká mọ̀ pé a ti sún mọ́ òpin ayé. Síbẹ̀, ńṣe làwọn kan ń jiyàn pé àwọn ẹ̀rí wọ̀nyẹn ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, pé ńṣe la dọ́gbọ́n hùmọ̀ rẹ̀ fúnra wa. Wọ́n ní torí  pé ètò ìbánisọ̀rọ̀ túbọ̀ ń gbèrú sí i ló ṣe dà bíi pé nǹkan ń burú sí i. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn ń rí nísinsìnyí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé à ń gbé ní ìparí sáà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn ìran èèyàn.

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé bí nǹkan ṣe ń lọ yìí, gudugbẹ̀ ńlá kan ò ní pẹ́ já, tí á sì mú ìyípadà ńláǹlà bá ilẹ̀ ayé yìí. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2014, ìgbìmọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ààbò tó ń tẹ ìwé ìròyìn The Bulletin of the Atomic Scientists, sọ fún ẹ̀ka tó ń dáàbò bo Ìgbìmọ̀ Ààbò fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pé kí wọ́n múra kí àwọn àjálù ńlá tó lè run aráyé má bàa ṣẹlẹ̀. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yẹn sọ pé: “Nígbà tá a gbé àwọn ẹ̀rí tá a ní yẹ̀ wò, ibi tí a parí èrò sí ni pé apá tí ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ìṣe ìgbàlódé lásán máa kó nínú ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí máa fa ewu tó lékenkà fún aráyé.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá gbà lóòótọ́ pé a ti wà ní sáà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn ìran aráyé. Àmọ́ ó dá àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn yìí àtàwọn tó ń kà á lójú pé sáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tá à ń sọ yìí ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àti pé òpin ti sún mọ́lé gan-an. Ṣùgbọ́n, dípò kó o máa bẹ̀rù torí pé oò mọ̀la, máa yọ̀ nítorí pé ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú máa já sí ayọ̀ nígbẹ̀yìn. Ki nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé ìwọ náà lè la òpin tó ń bọ̀ já!