Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  May 2015

Ohun Ti Bibeli So

Ohun Ti Bibeli So

Kí ni Ọjọ́ Ìdájọ́?

Kí nìdí tí ọjọ́ ìdájọ́ fi máa jẹ́ àkókò aláyọ̀?

Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Ọlọ́run lo àwọn onídàájọ́ láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìṣèdájọ́ òdodo. (Àwọn Onídàájọ́ 2:18) Bíbélì sọ pé ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú yóò jẹ́, torí Jèhófà Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé máa gba aráyé là kúrò lọ́wọ́ àìsí ìdájọ́ òdodo.—Ka Sáàmù 96:12, 13; Aísáyà 26:9.

Ọlọ́run ti yan Jésù láti jẹ́ onídàájọ́ òdodo fún àwọn alààyè àti òkú. (Ìṣe 10:42; 17:31) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kú láìmọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, ní Ọjọ́ Ìdájọ́, Jésù máa jí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dìde kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Ka Ìṣe 24:15.

Kí nìdí tí Ọjọ́ Ìdájọ́ fi máa gba ẹgbẹ̀rún ọdún?

Nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún ni Jésù máa jí àwọn òkú dìde. (Ìṣípayá 20:4, 12) Wọ́n máa ní àkókò tó pọ̀ tó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́, kí wọ́n sì ṣègbọràn sí i. Bíbélì fi hàn pé, ohun tí àwọn èèyàn yìí bá ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá jíǹde ni a ó fi ṣèdájọ́ wọn, èyí sì yàtọ̀ sí èrò ọ̀pọ̀ èèyàn.—Ka Róòmù 6:7.

Bíbélì tún sọ nípa ọjọ́ ìdájọ́ kan tó máa wáyé ṣáájú kí ẹgbẹ̀rún ọdún náà tó bẹ̀rẹ̀. Òjijì ni ìṣèlẹ̀ náà yóò sì wàyé. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí, ọjọ́ yẹn ni à ń pè ní òpin. Lọ́jọ́ náà, Ọlọ́run máa mú gbogbo àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn búburú kúrò. (2 Pétérù 3:7) Nígbà náà, a gbọ́dọ̀ sapá kí a ba lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—Ka 2 Pétérù 3:9, 13.