Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  May 2015

Nje O Mo?

Nje O Mo?

Ǹjẹ́ àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn bá àkọsílẹ̀ Bíbélì mu?

Ságónì kejì ọba ìlú ásíríà tí ìwé aísáyà 20:1 mẹ́nu kàn

Àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé tó ń jẹ́ Biblical Archaeology Review sọ pé, ìwádìí tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣe fi hàn pé, “ó kéré tán àádọ́ta [50]” nínú àwọn èèyàn tí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù mẹ́nu kàn tí gbé ayé rí lóòótọ́. Lára wọn ni mẹ́rìnlá nínú àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Júdà àti Ísírẹ́lì, ó mẹ́nu kan àwọn tó gbajúmọ̀ bíi Dáfídì àti Hesekáyà, àti àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ bíi Ménáhémù àti Pékà. Àkọsílẹ̀ yẹn tún mẹ́nu kan àwọn Fáráò márùn-ún, pẹ̀lú mọ́kàndínlógún [19] nínú àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Ásíríà, Bábílónì, Móábù, Páṣíà, àti Síríà. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọba tó wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì nìkan kọ́ ní àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí. Wọ́n tún rí àwọn míì tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀, irú bí àwọn àlùfáà àgbà, akọ̀wé kan àtàwọn òṣìṣẹ́ mìíràn.

Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló gbà pé àwọn tá a mẹ́nu kàn yìí wà lóòótọ́. Èyí sì jẹ́ kó dá wa lójú pé lóòótọ́ ni wọ́n gbáyé. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí díẹ̀ nínú àwọn tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì tọ́ka sí, àwọn bíi Hẹ́rọ́dù, Pọ́ńtíù Pílátù, Tìbéríù, Káyáfà àti Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì.

Ìgbà wo ni àwọn kìnnìún kú tán ní àwọn agbègbè Ísírẹ́lì?

Àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára bíríkì dídán ní ìlú bábílónì àtijọ́

Nǹkan bí àádọ́jọ [150] ìgbà ni ọ̀rọ̀ náà kìnnìún fara hàn nínú Bíbélì, èyí fi hàn pé ẹranko yìí kò ṣàjèjì sáwọn tó kọ Bíbélì. Àmọ́ lóde òní, kò sí kìnnìún mọ́ ní àwọn agbègbè tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Lọ́pọ̀ ìgbà, àpèjúwe ni Bíbélì máa ń fi kìnnìún ṣe, àmọ́ ó tún sọ nípa àwọn tó bá kìnnìún jà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Sámúsìnì, Dáfídì àti Bẹnáyà pa kìnnìún. (Àwọn Onídàájọ́ 14:5, 6; 1 Sámúẹ́lì 17:34, 35; 2 Sámúẹ́lì 23:20) Bákan náà, ó tún sọ nípa àwọn mí ì tí Kìnnìún pa.1 Àwọn Ọba 13:24; 2 Àwọn Ọba 17:25.

Láyé àtijọ́, àwọn kìnnìún ilẹ̀ Éṣíà (Panthera leo persica) wà ní àwọn agbègbè Éṣíà kékeré dé Gíríìsì títí lọ dé Palẹ́sìnì, Síríà, Mesopotámíà àti ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ India. Torí ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún kìnnìún tó jẹ́ àkòtagìrì ẹran, wọ́n sábà máa ń wà nínú àwọn àwòrán tí wọ́n yà ní àwọn agbègbè tó yí Ísírẹ́lì ká. Wọ́n tún gbẹ́ àwòrán kìnnìún sára bíríkì dídán tí wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí Òpópónà Àwọn Aláyẹyẹ tó wà ní Bábílónì àtijọ́.

Ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kejìlá Sànmánì Kristẹni, àwọn tó ń jagun ìsìn kiri bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn kìnnìún nílẹ̀ Palẹ́sínì. Ó sì dàbí pé kété lẹ́yìn ọdún 1300 ni àwọn kìnnìún kú tán ní agbègbè náà. Síbẹ̀, àwọn kan ṣì rí àwọn kìnnìún ní Mesopotámíà àti Síríà títí di ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún Sànmánì Kristẹni. Bákan náà, wọ́n wà nílẹ̀ Ìráànì àti Ìráàkì lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn 1901.