Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  May 2015

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ÒPIN TI SÚN MỌ́LÉ

Opo Eeyan Maa La Opin Ja—Iwọ Naa Le Laaja

Opo Eeyan Maa La Opin Ja—Iwọ Naa Le Laaja

Bíbélì sọ pé òpin tó ń bọ̀ máa mú ìparun wá, ó sọ pé: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí . . . láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là.” (Mátíù 24:21, 22) Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò làájá, ó sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ . . . , ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.

Bó o bá fẹ́ la ayé tó ń kọjá lọ yìí já, tó o sì fẹ́ wà láàyè títí láé, kí ló yẹ kó o ṣe? Àbí, ṣé ohun tó kàn ni pé kó o máa kó àwọn nǹkan ìní jọ pelemọ tàbí kó o máa gbara dì lójú méjèèjì? Rárá. Bíbélì sọ ohun tó fẹ́ ká fi sí ipò àkọ́kọ́. Ó ní: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà.” (2 Pétérù 3:10-12) Àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé àwọn alákòóso inú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí àti gbogbo àwọn tó fara mọ́ ìṣàkóso èèyàn dípò Ọlọ́run ló dúró fún “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” tí yóò di yíyọ́. Ká sòótọ́, tó bá jẹ́ àwọn nǹkan ìní tara là ń tọ́jú pamọ́, ìyẹn kò ní lè dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìparun tó ń bọ̀.

Tá a bá fẹ́ là á já, a ní láti fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà Ọlọ́run, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ ká lè mọ àwọn ìwà àti ìṣe tó máa dùn mọ́ ọn nínú. (Sefanáyà 2:3) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a ‘fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,’ a ní láti yẹra fún ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ ká sì fọkàn sí àwọn àmì tó fi hàn pé àkókò tí kò lẹ́gbẹ́ là ń gbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fi ohun tí Bíbélì sọ hàn ẹ́, kó o lè mọ bí wà á ṣe la òpin tó ń bọ̀ já.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú àti ohun tó yẹ kó o ṣe.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kí Ló Yẹ Kí O Ṣe Kó O Lè Lóye Bíbélì?

Láìka irú èèyàn tó o jẹ́ tàbí ibi tí o ti wá sí, o lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́.