Ìjíròrò tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Mojí lọ sí ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ṣẹwà.

“Ẹ MÁA ṢE ÈYÍ NÍ ÌRÁNTÍ MI”

Mojí: Ẹ ǹlẹ́ o. Inú mi dùn pé ẹ wá sí Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe lọ́sẹ̀ tó kọjá. * Kí lèrò yín nípa ìpàdé yẹn?

Ṣẹwà: Inú mi dùn pé mo wà níbẹ̀. Àmọ́ kí n sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n sọ níbẹ̀ ló yé mi. Mo mọ̀ pé àwọn èèyàn máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù nígbà ọdún Kérésì, wọ́n sì tún máa ń ṣe ayẹyẹ àjíǹde rẹ̀ nígbà Ọdún Àjíǹde. Àmọ́, èmi ò gbọ́ ọ rí pé wọ́n ń ṣe ìrántí ikú rẹ̀.

Mojí: Òótọ́ ni, ọ̀pọ̀ ibi láyé làwọn èèyàn ti máa ń ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì àti Ọdún Àjíǹde. Ṣùgbọ́n àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ó ṣe pàtàkì ká máa ṣe ìrántí ikú Jésù. Tẹ́ ẹ bá fún mi ní ìṣẹ́jú díẹ̀, màá fẹ́ ṣàlàyé ìdí tá a fi gbà bẹ́ẹ̀.

Ṣẹwà: Kò burú.

Mojí: Ní pàtàkì, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ìrántí ikú Jésù torí pé òun fúnra rẹ̀ ló pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe é. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú. Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àkànṣe oúnjẹ tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ jọ jẹ lálẹ́ ọjọ́ náà?

Ṣẹwà: Ṣé Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

Mojí: Bẹ́ẹ̀ ni. Òun la máa ń pè ní Ìrántí Ikú Kristi. Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́, Jésù pa àṣẹ kan tó ṣe kedere fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ṣé ẹ lè bá mi ka ohun tó sọ nínú ìwé Lúùkù 22:19?

Ṣẹwà: Ó kà pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’”

Mojí: Ẹ ṣeun. Ẹ wo àṣẹ tí Jésù pa nínú ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Kí Jésù tó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sọ ohun tó yẹ kí wọ́n máa rántí nípa òun. Ó sọ pé òun máa fi ẹ̀mí òun lélẹ̀ nítorí àwọn ọmọlẹ́yìn òun. Jésù sọ ohun kan náà nínú Mátíù 20:28. Ẹsẹ yẹn kà pé: “Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Ní kúkúrú, ìdí nìyẹn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń kóra jọ lọ́dọọdún ní àyájọ́ ọjọ́ tí Jésù kú láti rántí ẹbọ ìràpadà rẹ̀. Ikú rẹ̀ á mú káwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn ní ìyè.

KÍ NÌDÍ TÁ A FI NÍLÒ ÌRÀPADÀ?

Ṣẹwà: Mo máa ń gbọ́ tàwọn èèyàn ń sọ pé Jésù kú fún wa ká lè rí ìgbàlà. Àmọ́ ki n sòótọ́, kò ye mi bí ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe.

Mojí: Kì í ṣe ẹ̀yin nìkan lẹ nírú èrò yìí. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni ọ̀rọ̀ nípa ẹbọ ìràpadà Jésù jẹ́. Àmọ́, ọ̀kan pàtàkì ló jẹ́ lára àwọn òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣé a ṣì lè sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú díẹ̀ sí i?

 Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni, mo ṣì lè fún yín ní ìṣẹ́jú díẹ̀ sí i.

Mojí: Ẹ ṣeun. Mo ṣe àwọn ìwádìí kan nípa ìràpadà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, màá fẹ́ ṣàlàyé fún yín lọ́nà tó máa tètè yé e yín.

Ṣẹwà: Ó dáa.

Mojí: Ká lè lóye ohun tí ìràpadà jẹ́, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ wàhálà tí Ádámù àti Éfà dá sílẹ̀ nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Ká lè mọ ohun tí èyí ní nínú, ẹ jẹ́ ká jọ ka Róòmù 6:23. Ẹ jọ̀ọ́, ṣé ẹ lè kà á?

Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó kà pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”

Mojí: Ẹ ṣeun. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹsẹ yìí sọ yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ wo bó ṣe bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” Ìlànà tó ṣe kedere yìí ni Ọlọ́run fi lélẹ̀ nígbà tó ṣẹ̀dá èèyàn, ìyẹn ni pé owó ọ̀yà tàbí ìyà tó wà fún ẹ̀ṣẹ̀ ni ikú. Lóòótọ́, kò tíì sí ẹ̀ṣẹ̀ nígbà yẹn. Ẹni pípé ni Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, àwọn ọmọ wọn náà ì bá sì jẹ́ pípé. Torí náà, ńṣe ni à bá máa wà láàyè títí lọ. Ádámù àti Éfà àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ní ìrètí láti wà láàyè títí láé, kí wọ́n sì láyọ̀. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bá a ṣe mọ̀, nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí. Àbí ó rí bẹ́ẹ̀?

Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni. Ádámù àti Éfà jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀.

Mojí: Òótọ́ ni. Wọ́n tipa báyìí dẹ́ṣẹ̀, torí pé ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Èyí fi hàn pé fúnra wọn ni wọ́n yàn láti di ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé. Ohun tí wọ́n yàn yẹn máa ní àbájáde búburú lórí Ádámù àti Éfà àti gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ wọn.

Ṣẹwà: Kí lẹ ní lọ́kàn?

Mojí: Kí ohun tí mò ń sọ lè yé yín, màá lo àpèjúwe kan. Ẹ jẹ́ kí n bi yín ní ìbéèrè kan, ṣé ẹ mọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe búrẹ́dì?

Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni! Mo mọ̀ ọ́n.

Mojí: Ká sọ pé ẹ ní agolo tuntun kan tó dáa, tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì. Àmọ́ kẹ́ ẹ tó fi ṣe búrẹ́dì, agolo náà jábọ́ sílẹ̀, ó sì tẹ̀ gan-an. Ní báyìí tí agolo náà ti tẹ̀, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí búrẹ́dì tẹ́ ẹ bá fi ṣe? Ṣé kò ní lámì lára?

Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni, á lámì lára.

Mojí: Lọ́nà kan náà, nígbà tí Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé mú kí wọ́n ní “àmì” tàbí àléébù lára. Torí pé wọ́n ti di ẹlẹ́ṣẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, gbogbo ọmọ tí wọ́n bá bí ló máa ní “àmì” náà lára. Inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n máa bí gbogbo ọmọ wọn sí. Nínú Bíbélì, “ẹ̀ṣẹ̀” máa ń túmọ̀ sí ohun tí kò dáa tẹ́nì kan ṣe, ó sì tún máa ń tọ́ka sí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa kọ́ la dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ò sì tíì bí wa nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́sẹ̀. Àbájáde ọ̀rọ̀ náà ni pé, wọ́n mú kí àwa àtọmọdọ́mọ wọn di aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ èyí tó máa yọrí sí ikú. Bá a ṣe kà á nínú ìwé Róòmù 6:23, ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣẹwà: Àmọ́, ìyẹn ò dáa o! Kí nìdí tí àwa èèyàn á fi wá máa jìyà títí láé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà?

Mojí: Òótọ́ ni, ó lè dà bí i pé kò fi bẹ́ẹ̀ dáa. Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà kọjá pé ó dáa tàbí kò dáa. Torí pé Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ó rí i pé ó yẹ kí Ádámù àti Éfà kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n, ìrètí ṣì wà fún àwa tá a jẹ́ àtọmọdọ́mọ wọn. Ọlọ́run ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa ká lè bọ́ nínú ìṣòro náà. Ìdí tá a fi nílò ẹbọ ìràpadà Jésù gan-an nìyẹn. Ẹ jẹ́ ká tún pa dà wo ìwé Róòmù 6:23. Lẹ́yìn tí ẹsẹ yẹn sọ pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” ó tún wá sọ pé: “Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” Torí náà, ikú Jésù ló ṣe ọ̀nà àbáyọ tá á jẹ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. *

 ÌRÀPADÀ—Ẹ̀BÙN IYEBÍYE TÍ ỌLỌ́RUN FÚN WA

Mojí: Kókó míì tún wà nínú ẹsẹ yìí tí màá fẹ́ kí ẹ fi sọ́kàn.

Ṣẹwà: Kókó wo nìyẹn?

Mojí: Ẹ kíyè sí i pé ẹsẹ náà sọ pé: “Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa.” Ó dáa, tó bá jẹ́ pé Jésù ni ẹni tó jìyà, tó sì kú nítorí wa, kí nìdí tí ẹsẹ yẹn fi sọ nípa ìràpadà pé ó jẹ́ “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni,” tí kò sọ pé “ẹ̀bùn tí Jésù ń fi fúnni”? *

Ṣẹwà: Ẹ̀n-ẹ́n. Kò yé mi dáadáa.

Mojí: Ó dáa, ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí. Ọlọ́run ló dá Ádámù àti Éfà, òun sì ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí nígbà tí wọ́n ṣàìgbọràn nínú ọgbà Édẹ́nì. Kò sí àní-àní pé ó máa dùn ún gan-an nígbà tí àwọn ẹ̀dá èèyàn méjì àkọ́kọ́ yìí ṣọ̀tẹ̀ sí i. Àmọ́, ojú ẹsẹ̀ ni Jèhófà sọ ohun tó máa jẹ́ ojútùú sí ìṣòro náà. * Ó sọ pé ọ̀kan lára àwọn ańgẹ́lì tó dá máa wá sí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà. Torí náà, ìràpadà jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ohun míì tún wà tó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìràpadà jẹ́. Ǹjẹ́ ẹ ti ronú nípa bó ṣe máa rí lára Ọlọ́run nígbà tí wọ́n pa Jésù?

Ṣẹwà: Rárá, mi ò tíì ronú nípa ẹ̀ rí.

Mojí: Mo rí àwọn nǹkan ìṣeré ọmọdé níwájú ilé yín. Ìyẹn fi hàn pé àwọn ọmọdé wà nínú ilé yìí.

Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni, mo ní àwọn ọmọ méjì. Ọkùnrin àti obìnrin.

Mojí: Ẹ rò ó wò ná, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ, báwo lẹ ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá Jésù ní ọjọ́ tí Jésù kú. Ohun tí mo ní lọ́kàn ni pé, báwo ló ṣe máa rí lára Ọlọ́run bó ṣe ń wo Ọmọ rẹ̀ látọ̀run tí wọ́n fàṣẹ ọba mú un, tí wọ́n ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, tí wọ́n sì ń gbá a ní ẹ̀ṣẹ́? Báwo lẹ ṣe rò pé ó máa rí lára Bàbá Jésù bó ṣe ń rí i tí wọ́n ń kan Ọmọ rẹ̀ mọ́gi, tí wọ́n sì fi í sílẹ̀ níbẹ̀ kó máa jẹ ìrora títí tó fi kú ikú oró?

Ṣẹwà: Ó máa dùn ún gan-an. Mi ò rò ó báyìí rí o!

Mojí: Lóòótọ́, a ò lè mọ bó ṣe máa rí gan-an lára Ọlọ́run lọ́jọ́ náà. Síbẹ̀, a mọ̀ pé ó mọ̀ ọ́n lára, a sì mọ ìdí tó fi fàyè gba gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá a mọ̀ dáadáa tó sọ ìdí náà fún wa ni Jòhánù 3:16. Ẹ jọ̀wọ́, ṣé ẹ lè bá wa kà á?

Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó ní: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Mojí: Ẹ ṣeun. Ẹ tún wo ìbẹ̀rẹ̀ ẹsẹ yẹn. Ó ní: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé.” Ìfẹ́ ló mú kí Ọlọrun fàyè gba ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé kó bàa lè kú nítorí wa. Ká sòótọ́, ìràpadà ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ hàn sí wa. Ìyẹn sì ni ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kóra jọ láti ṣe ìrántí rẹ̀ lọ́dọọdún ní àyájọ́ ọjọ́ tí Jésù kú. Ṣé ó ti wá yé yín báyìí?

Ṣẹwà: Bẹ́ẹ̀ ni, ó ti yé mi. Ẹ ṣeun gan-an fún bẹ́ ẹ ṣe ṣàlàyé kókó yìí fún mi.

Ṣé àwọn ẹ̀kọ Bíbélì kan máa ń ṣe ìwọ náà ní kàyéfì? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ àti bí ìjọsìn wa ṣe rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́tìkọ̀ láti bi ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa rẹ̀. Inú onítọ̀hún á dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.

^ ìpínrọ̀ 5 Ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kóra jọ ní àyájọ́ ọjọ́ tí Jésù kú láti rántí ikú ìrúbọ rẹ̀. Ọjọ́ Friday, April 3, ló bọ́ sí lọ́dún yìí.

^ ìpínrọ̀ 32 Nínú àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀ nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ lórí bí ẹbọ ìràpadà Jésù ṣe lè mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè jàǹfààní nínú ìràpadà náà.

^ ìpínrọ̀ 36 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run àti Jésù. Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo orí 4 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

Ìràpadà ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ hàn sí wa