Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Ibeere Meta Lo Yi Igbesi Aye Mi Pa Da

Ibeere Meta Lo Yi Igbesi Aye Mi Pa Da
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1949

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: AMẸ́RÍKÀ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO FẸ́ MỌ ÌDÍ TÁ A FI WÀ LÁYÉ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Ancram ní àríwá New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni mo dàgbà sí. Oko tí wọ́n ti ń fún wàrà màlúù ló pọ̀ jù nílùú yẹn. Kódà, màlúù pọ̀ nílùú yẹn ju àwọn èèyàn lọ.

Ṣọ́ọ̀ṣì kan ṣoṣo tó wà nílùú yẹn làwọn ìdílé mi ń lọ. Bàbá mi àgbà máa ń bá mi kun bàtà mi láràárọ̀ ọjọ́ Sunday. Lẹ́yìn náà, màá wá lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi, mo sì máa ń mú Bíbélì funfun kékeré tí màmá mi àgbà fún mi dání. Wọ́n kọ́ èmi àtàwọn àbúrò mi láti máa ṣiṣẹ́ kára, ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aládùúgbò wa, ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì tún máa dúpẹ́ fún àwọn ìbùkún tá à ń rí gbà.

Mo kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí mi lẹ́yìn tí mo ti tójúúbọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ olùkọ́. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa Ọlọ́run àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé máa ń jẹ mí lọ́kàn. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan mọ̀wé dáadáa. Àwọn míì ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé àmọ́ wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára, àwọn kan jẹ́ aláàbọ̀ ara, ara àwọn míì sì dá ṣáṣá. Mo ronú pé kò yẹ kí nǹkan rí bẹ́ẹ̀. Lára ohun táwọn òbí àwọn ọmọ tó kù-díẹ̀-káàtó fún yìí máa ń sọ ni pé, “Bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ káyé ọmọ mi rí nìyẹn.” Èyí máa ń mú kí n ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run fi ń jẹ́ kí wọ́n bí àwọn ọmọ kan ní aláàbọ̀ ara. Ó ṣe tán, àwọn ọmọ yìí ò tíì lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn.

Mo máa ń ronú pé, ‘Nǹkan gidi wo ni mo lè fi ayé mi ṣe?’ Mo ronú pé mo ti ń dàgbà lọ. Inú ìdílé tí wọ́n ti rí já jẹ ni mo dàgbà sí, mo lọ sílé ẹ̀kọ́, iṣẹ́ tí mo nífẹ̀ẹ́ sí ni mò ń ṣe nígbà yẹn. Ṣùgbọ́n ó dà bíi pé kò sí ohun tí mo tún máa fi ayé mi ṣe. Gbogbo ohun tí mo lè ṣe ò ju pé, kí n ṣègbéyàwó, kí n ní ilé tó dáa, kí n bímọ, kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ títí màá fi fẹ̀yìn tì, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn kí n lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Mò ń ronú pé kò sí nǹkan míì tí mo tún lè fi ayé mi ṣe.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Nígbà kan, èmi àtàwọn olùkọ́ ẹlẹgbẹ́ mi rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù. A lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Westminster Abbey, Notre-Dame de Paris àti sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì kéékèèké míì. Mo máa ń béèrè àwọn ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn níbikíbi tí mo bá lọ.  Lẹ́yìn tí mo pa dà sílé nílùú Sloatsburg, ní ìpínlẹ̀ New York, mo tún lọ sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tó dáhùn ìbéèrè mi lọ́nà tó tẹ́ mi lọ́rùn.

Lọ́jọ́ kan, akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún méjìlá kan wá bá mi, ó sì bi láwọn ìbéèrè mẹ́ta kan. Àkọ́kọ́, ó béèrè pé ṣé mo mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Mo ní bẹ́ẹ̀ ni. Ìkejì, ó béèrè pé ṣé màá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo tún dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni. Ìkẹ́ta, ó béèrè ibi tí mò ń gbé. Nígbà tí mo sọ àdírẹ́sì ilé mi fún un, àwa méjèèjì wá rí i pé ilé wa ò jìnnà síra. Mi ò mọ̀ pé ìbéèrè mẹ́ta tí ọmọdébìnrin yìí bi mí ló máa yí ìgbésí ayé mi pa dà pátápátá.

Láìpẹ́ sígbà yẹn, ó gun kẹ̀kẹ́ wá sílé mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo béèrè àwọn ìbéèrè tí mo ti ń béèrè lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tiẹ̀ yàtọ̀ sí tiwọn, torí pé ó fi àwọn ìdáhùn tó ṣe kedere tó sì tẹ́ mi lọ́rùn hàn mí láti inú Bíbélì mi, àwọn ìdáhùn tí èmi fúnra mi ò mọ̀ pé ó wà nínú Bíbélì!

Ohun tí mo kọ́ látinú Bíbélì jẹ́ kí n ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Ẹnu yà mí nígbà tí mo ka 1 Jòhánù 5:19 tó sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Ìtùnú ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo wá mọ̀ pé Sátánì ló ń fa gbogbo ìbànújẹ́ tó ń bá aráyé fínra, pé kì í ṣe Ọlọ́run àti pé Ọlọ́run máa yanjú gbogbo ìṣòro wa pátá. (Ìṣípayá 21:3, 4) Mo wá rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì bọ́gbọ́n mu, tí wọ́n bá ṣàlàyé rẹ̀ dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún méjìlá péré ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, mo gbà pé láìka irú ẹni tó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, òtítọ́ ni òtítọ́ á máa jẹ́.

Síbẹ̀, mo ṣì fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọmọdébìnrin yìí máa ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ní àwọn ìwà bíi sùúrù àti inúure. (Gálátíà 5:22, 23) Mo fẹ́ mọ̀ bóyá òun fúnra rẹ̀ ní àwọn ìwà yìí. Lọ́jọ́ kan, mo mọ̀ọ́mọ̀ pẹ́ kí n tó wá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ mi. Mò ń rò ó pé: ‘Ṣé yóò ṣì máa dúró dè mí? Tó bá tiẹ̀ ṣì dúró, ṣé kò ti ní máa bínú pé mo pẹ́?’ Bí mo ṣe ń wa mọ́tò wọlé, mo rí i tó dúró lórí àtẹ̀gùn iwájú ilé mi. Ó sáré wá bá mi nínú mọ́tò, ó sì sọ pé: “Mo ti fẹ́ pa dà sílé kí n lè lọ sọ fún ìyá mi pé kí á pe ilé ìwòsàn, ká sì pe àwọn ọlọ́pàá, ká lè mọ̀ bóyá àlàáfíà lẹ wà torí ẹ kì í pẹ́ dé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yín. Mo ti ń dààmú nípa yín gan-an!”

Lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo bi í ní ìbéèrè tí mo rò pé ọmọ ọdún méjìlá kò lè dáhùn. Mo fẹ́ mọ̀ bóyá á kàn dáhùn bákàn. Nígbà tí mo bi í ní ìbéèrè yẹn, ó wò mí pẹ̀lú kàyéfì, ó sì sọ pé: “Ìbéèrè yìí le o. Àmọ́ màá kọ ọ́ sílẹ̀, màá sì bi àwọn òbí mi.” Lóòótọ́, nígbà tí a tún máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, ó mú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó dáhùn àwọn ìbéèrè mi dání. Èyí ló jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé àwọn ìtẹ̀jáde wọn máa ń jẹ́ kí n mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí àwọn ìbéèrè mi. Mo gbà kí ọmọbìnrin yìí máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, lẹ́yìn ọdún kan mo ṣèrìbọmi, mo sì di ọkàn lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. *

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo rí ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn sáwọn ìbéèrè mi, èmi náà sì fẹ́ ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 12:35) Ìdílé mi kọ́kọ́ ta kò mí nítorí ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́ yìí. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yí ìwà pa dà. Ìyá mi náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó tó kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ṣèrìbọmi tí wọ́n fi kú, ó dá mi lójú pé wọ́n ti pinnu láti sin Jèhófà.

Mo fẹ́ Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Elias Kazan ní ọdún 1978. Nígbà tó di ọdún 1981, wọ́n pe èmi àti Elias láti wá di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. * Ó bà mí nínú jẹ́ pé, lẹ́yìn tí a ti sìn fún nǹkan bí ọdún mẹ́rin níbẹ̀, Elias ọkọ mi kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti di opó, mo ṣì ń bá iṣẹ́ ìsìn mi lọ ní Bẹ́tẹ́lì, èyí jẹ́ kí n lè pọkàn pọ̀, ó sì ń tù mí nínú.

Ní ọdún 2006, mo ṣègbéyàwó pẹ̀lú Richard Eldred tí òun náà jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Èmi àti Richard túbọ̀ ń gbádùn àǹfààní tá a ní láti máa ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Mo mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, ó dá mi lójú pé kì í ṣe àwọn ìdáhùn tí mò ń wá nìkan ni mo rí, ṣùgbọ́n mo tún mọ ìdí téèyàn fi wà láyé. Kí ẹ sì máa wò ó, ìbéèrè mẹ́ta tí ọmọdébìnrin kan bi mí ló yí ìgbésí ayé mi pa dà.

^ ìpínrọ̀ 16 Lápapọ̀, ọmọbìnrin yìí àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kọ́ márùn ún lára àwọn olùkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì di olùjọ́sìn Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 18 “Bẹ́tẹ́lì” túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.” Orúkọ yìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pe àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn kárí ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 28:17, 19) Àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń ṣe onírúurú iṣẹ́ láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe.