Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?

Eto Eko Bibeli fun Gbogbo Eeyan

Eto Eko Bibeli fun Gbogbo Eeyan

Àwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa nítorí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé a tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé?

Lọ́dún 2014, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè òjìlérúgba [240] tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Iye àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [9,500,000]. * Ká sòótọ́, iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ju iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogóje [140]!

Kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí, a máa ń tẹ Bíbélì, àwọn ìwé, àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje (700) èdè! Iṣẹ́ ìtẹ̀wé tí kò lẹ́gbẹ́ yìí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè tí wọ́n bá fẹ́.

ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ NÍPA ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ TÁ À Ń ṢE

 Báwo lẹ ṣe máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?

A máa ń yan onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì, a sì máa ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó bá àwọn ẹ̀kọ́ náà mu. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè, bíi: Ta ni Ọlọ́run? Irú ẹni wo ni Ọlọ́run jẹ́? Ṣé ó ní orúkọ? Ibo ló ń gbé? Ǹjẹ́ a lè sún mọ́ ọn? Ohun tó máa ń jẹ́ ìṣòro ni béèyàn ṣe máa rí ìdáhùn nínú Bíbélì.

Kó lè ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti rí ìdáhùn, a máa ń lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tó ní ojú ìwé igbà ó lé mẹ́rìnlélógún [224]. * Ńṣe la dìídì ṣe ìwé yìí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì. Ìwé náà ní àwọn ẹ̀kọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, Jésù Kristi, ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, àjíǹde, àdúrà àtàwọn ẹ̀kọ́ míì.

 Ìgbà wo ni èèyàn lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ibo ló sì ti máa ṣe é?

Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè wáyé ní àkókò tó bá rọrùn fún ẹ àti ní ibi tó bá wù ẹ́.

Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa gùn tó?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo nǹkan bíi wákátì kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò pọn dandan kó gùn tó bẹ́ẹ̀. A máa ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó máa bá ipò rẹ mu. Àwọn kan kì í lò ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Èló lẹ máa ń gbà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà?

Ọ̀fẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Èyí sì bá ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mu pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.

Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa pẹ́ tó?

Ìwọ fúnra rẹ lo máa pinnu bó ṣe máa pẹ́ tó. Ẹ̀kọ́ mọ́kàndínlógún [19] ló wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O lè ka èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀kọ́ náà, o sì lè ka gbogbo rẹ̀ bí àkókó bá ṣe wà fún ẹ tó.

Ṣé ó pọn dandan kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Rárá. A gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó máa gbà gbọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó bá ti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ló máa ń fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe.

 Ibo ni mo ti lè rí ìsọfúnni síwájú sí i?

Wàá rí ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ìkànnì jw.org/yo.

Báwo ni mo ṣe lè béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

^ ìpínrọ̀ 4 A sábà máa ń kọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí àwùjọ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

^ ìpínrọ̀ 9 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. A sì ti tẹ ẹ̀dá tó lé ní mílíọ̀nù igba ó lé ọgbọ̀n [230,000,000] jáde ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgọ́ta [260] èdè.